Àbá Nípa Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà Lọni
◼ Gbé Bíbélì rẹ dání kí o sì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ ni yóò fẹ́ láti sún mọ́ ọn. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń pè wá pé ká sún mọ́ òun? [Ka Jákọ́bù 4:8.] A ṣe ìwé yìí lọ́nà tí yóò fi lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tipa kíka Bíbélì wọn sún mọ́ Ọlọ́run.” Ka ìpínrọ̀ kìíní ní ojú ìwé 16.
◼ Gbé Bíbélì rẹ dání kí o sì sọ pé: “Lónìí ìwà ìrẹ́jẹ gbòde kan. Bí wọ́n ṣe ṣàlàyé rẹ̀ níbí yìí gan-an lórí. [Ka Oníwàásù 8:9b.] Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé bóyá tiẹ̀ ni Ọlọ́run bìkítà nípa ọ̀rọ̀ náà. [Ka gbólóhùn méjì àkọ́kọ́ ní ìpínrọ̀ kẹrin ní ojú ìwé 119.] Orí yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run ṣì fi ń fàyè gba ìwà ìrẹ́jẹ títí di ìgbà kan ná.”