ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/03 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Rántí Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Ìrántí Ikú Kristi
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àwọn Ohun Tí Kò Yẹ Ká Gbàgbé Nípa Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àwọn Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 3/03 ojú ìwé 7

Àwọn Ìránnilétí Nípa Ìṣe Ìrántí

Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí bọ́ sí Wednesday, April 16. Kí àwọn alàgbà fiyè sí àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí:

◼ Tí ẹ bá ń ṣètò àkókò tẹ́ ẹ máa fi ìpàdé yìí sí, ẹ rí i dájú pé a kì yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà kiri àyàfi lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀.

◼ Kí a jẹ́ kí gbogbo èèyàn, títí kan olùbánisọ̀rọ̀ náà, mọ àkókò pàtó tí a óò ṣe ayẹyẹ náà àti ibi tí a óò ti ṣe é.

◼ A gbọ́dọ̀ wá irú búrẹ́dì àti wáìnì tó yẹ, kí wọ́n sì ti wà ní sẹpẹ́.—Wo Ile-Iṣọ Naa, February 1, 1985, ojú ìwé 17.

◼ Kí a gbé àwọn àwo, ife, tábìlì àti aṣọ orí tábìlì tó bójú mu wá sí gbọ̀ngàn ìpàdé náà kí a sì tò wọ́n ṣáájú àkókò.

◼ Kí a tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí ibòmíràn tí a óò lò ṣe, kí ó sì wà ní mímọ́ tónítóní ṣáájú àkókò.

◼ Kí a yan àwọn olùtọ́jú èrò àtàwọn tí yóò gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ, kí a sì ti fún wọn nítọ̀ọ́ni ṣáájú àkókò nípa ojúṣe wọn, bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe é, àti ìjẹ́pàtàkì mímúra lọ́nà tó bójú mu.

◼ Kí a ṣètò láti gbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ lọ fún ẹni àmì òróró èyíkéyìí tó jẹ́ aláìlera tí kò ṣeé ṣe fún láti wá.

◼ Tí a bá ṣètò pé kí ìjọ tó ju ẹyọ kan lọ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, kí àwọn ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa, kí ẹnu ọ̀nà, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ tí gbogbo èèyàn ń gbà àti ibi ìgbọ́kọ̀sí má bàa kún jù fún èrò. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ó dára kí a fi ìṣẹ́jú márùnlélógójì sílẹ̀ lẹ́yìn tí ìjọ kan bá ti parí ayẹyẹ tirẹ̀ kí òmíràn tó bẹ̀rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́