Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Nínú Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni
Ọ̀pọ̀ nínú wa ló máa dùn mọ́ nínú láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá a bá mọ bó ṣe yẹ ká bẹ̀rẹ̀. Ìwé tuntun náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? lè ràn wá lọ́wọ́. Ṣe la dìídì fi ọ̀rọ̀ àkọ́sọ tó wà lójú ìwé 3 sí 7 nínú ìwé yìí kún un láti mú onílé wọnú ìjíròrò Bíbélì. Kódà àwọn tí kò tíì pẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lè rí i pé ó rọrùn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Bó o bá fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí ojú ewé 3 nínú ìwé náà, o lè lo àbá yìí:
Lẹ́yìn tó o bá ti mẹ́nu ba ìròyìn kan tàbí ìṣòro táwọn tó wà ládùúgbò yẹn mọ̀, bi onílé náà ní àwọn ìbéèrè tá a fi àwọ̀ tó dúdú yàtọ̀ kọ lójú ìwé 3, kó o wá ní kó sọ èrò rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 4 àti 5.
◼ O sì lè bẹ̀rẹ̀ nípa ṣíṣàlàyé ohun tó wà lójú ìwé 4 sí 5:
O lè sọ pé, “Ṣó o rò pé kò ní dáa gan-an báwọn ìyípadà tó wà nínú àwòrán yìí bá wáyé?” O sì lè béèrè pé: “Èwo lára àwọn ìlérí tó wà níbí ló wù ọ́ jù pé kó nímùúṣẹ?” Fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tó bá ń fèsì.
Bí onílé náà bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, fi ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó yẹn hàn án nípa jíjíròrò ìpínrọ̀ tó ṣàlàyé rẹ̀ nínú ìwé yẹn pẹ̀lú rẹ̀. (Wo àpótí tó wà nínú àkìbọnú lójú ìwé yìí.) Jíròrò àwọn kókó náà bí ìgbà tó ò ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. O lè fi ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá ṣe é lórí ìdúró níbẹ̀ nígbà tó o bá kọ́kọ́ bá ẹni náà pàdé.
◼ Àbá mìíràn ni lílo ojú ìwé 6 láti mú kí onítọ̀hún sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀:
Fi àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ ojú ìwé náà han onílé, kó o wá bi í pé: “Ǹjẹ́ o ti fìgbà kan rí ronú lórí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè tó wà níbí yìí?” Bí ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè náà bá fà á mọ́ra, ṣí ìwé náà sí ìpínrọ̀ tó dáhùn ìbéèrè ọ̀hún. (Wo àpótí tó wà nínú àkìbọnú ní ojú ìwé yìí.) Gbogbo bẹ́ ẹ ṣe ń jíròrò àwọn àlàyé yẹn, o ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn o.
◼ O lè lo ojú ìwé 7 láti fi bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni náà:
Ka gbólóhùn mẹ́ta àkọ́kọ́ tó wà lójú ìwé yẹn, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe máa ń lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi jíròrò Bíbélì. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé náà sí orí 3, kó o sì fi ìpínrọ̀ 1 sí 3 ṣàṣefihàn bá a ṣe máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ jọ ṣàdéhùn ìgbà tó o máa padà lọ láti jíròrò àwọn ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 3.
◼ Bó o ṣe lè ṣàdéhùn ìgbà tó o máa padà lọ:
Nígbà tó o bá ń kádìí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àkọ́kọ́, ẹ jọ ṣàdéhùn bẹ́ ẹ ó ṣe máa tẹ̀ síwájú lọ́jọ́ míì. O kàn lè ní: “Níwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ yìí la ti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó yìí o. Tí n bá padà wá, a óò jíròrò síwájú sí i lórí [béèrè ìbéèrè kan tó o máa jíròrò tó o bá padà lọ]. Ṣé àkókò yìí náà ni kí n wá lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀?”
Bá a ṣe ń sún mọ́ àkókò tí Jèhófà ti yàn kalẹ̀, kò ṣíwọ́ láti máa mú wa gbára dì fún iṣẹ́ tó wà níkàáwọ́ wa. (Mát. 28:19, 20; 2 Tím. 3:17) Ǹjẹ́ ká lo àgbàyanu irin iṣẹ́ tuntun yìí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìjíròrò Tó Dá Lórí Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Tó Wà Lójú Ìwé 4 sí 5
◻ Ìṣípayá 21:4 (ojú ìwé 27 sí 28, ìpínrọ̀ 1 sí 3)
◻ Aísáyà 33:24; 35:5, 6 (ojú ìwé 36, ìpínrọ̀ 22)
◻ Jòhánù 5:28, 29 (ojú ìwé 72 sí 73, ìpínrọ̀ 17 sí 19)
◻ Sáàmù 72:16 (ojú ìwé 34, ìpínrọ̀ 19)
Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Tó Wà Lójú Ìwé 6
◻ Kí nìdí tá a fi ń jìyà? (ojú ìwé 108 sí 109, ìpínrọ̀ 6 sí 8)
◻ Báwo la ṣe lè borí àníyàn ìgbésí ayé? (ojú ìwé 184 sí 185, ìpínrọ̀ 1 sí 3)
◻ Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ìdílé wa túbọ̀ láyọ̀? (ojú ìwé 143, ìpínrọ̀ 20)
◻ Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá kú? (ojú ìwé 58 sí 59, ìpínrọ̀ 5 sí 6)
◻ Ǹjẹ́ a óò tún padà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú? (ojú ìwé 72 sí 73, ìpínrọ̀ 17 sí 19)
◻ Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò mú àwọn ohun tó ṣèlérí pé òun yóò ṣe ní ọjọ́ ọ̀la ṣẹ? (ojú ìwé 25, ìpínrọ̀ 17)