Ṣé Wàá Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Oṣù October?
1. Àwọn ìwé wo la máa lò lóde ẹ̀rí ní oṣù October?
1 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò lóde ẹ̀rí ní oṣù October. Láti lè mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a rọ̀ wá pé ká fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, ká sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Báwo la ṣe lè ṣe èyí nígbà ìpadàbẹ̀wò?
2. Báwo la ṣe lè fi ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a bá ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó gba ìwé ìròyìn wa?
2 Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Náà: O lè sọ pé: “Ìwé ìròyìn tí mo fún ẹ yẹn rọ gbogbo èèyàn pé kí wọ́n ṣàyẹ̀wò Bíbélì láìka ibi tí wọ́n ti wá tàbí ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe sí. [Fún onílé ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́, kó o sì fi àwọn ìbéèrè tó wà ní ojú ìwé àkọ́kọ́ hàn án.] Wo àwọn ìbéèrè tó fani lọ́kàn mọ́ra tí Bíbélì dáhùn lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn. Ǹjẹ́ o ti béèrè èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí rí?” Lẹ́yìn tí onílé bá ti fèsì, kí ẹ jọ jíròrò ìdáhùn sí ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó bá yàn, kí ẹ sì ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Kó o wá ṣàlàyé fún un pé èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, kó o sì fún un ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Lẹ́yìn náà, o lè jíròrò àwọn ìpínrọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ orí tí ẹni náà bá yàn látinú àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé náà. O sì lè yàn láti ṣí ìwé náà sí ibi tí ìsọfúnni púpọ̀ sí i wà nípa kókó ọ̀rọ̀ tá a jíròrò nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Àwọn ibi tó o lè ṣí ìwé náà sí rèé:
● Ṣé lóòótọ́ ni Ọlọ́run bìkítà nípa wa? (ojú ìwé 10 sí 11, ìpínrọ̀ 6 sí 10)
● Ṣé ogun àti ìjìyà máa dópin? (ojú ìwé 12, ìpínrọ̀ 12 sí 13)
● Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tá a bá kú? (ojú ìwé 59 sí 60, ìpínrọ̀ 7 sí 8)
● Ṣé ìrètí kankan tiẹ̀ wà fáwọn tó ti kú? (ojú ìwé 71, ìpínrọ̀ 13 sí 15)
● Báwo ni mo ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á sì gbọ́ àdúrà mi? (ojú ìwé 166 sí 167, ìpínrọ̀ 5 sí 8)
● Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ aláyọ̀? (ojú iwé 9, ìpínrọ̀ 4 sí 5)
3. Àwọn ìyípadà wo la lè ṣe láti mú kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa bá ipò tí onílé wà mu.
3 Bí kò bá ṣeé ṣe láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nígbà àkọ́kọ́ tá a bá ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹnì kan, a lè ṣètò láti pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni náà, ká lè máa bá ìjíròrò náà lọ. A tiẹ̀ lè yàn láti jíròrò ju ìbéèrè kan lọ nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà nígbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a bá pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò, ká tó wá fún un ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, èyí sinmi lórí bí onílé náà bá ṣe nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa tó. Ẹ jẹ́ ká lo ìwé àṣàrò kúkúrú tó wúlò yìí dáadáa láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní oṣù October, ká sì ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́, kí wọ́n lè “mọ òtítọ́.”—Jòh. 8:31, 32.