Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
Tí ẹnì kan bá gbà wá láyè láti wàásù ìhìn rere fún òun, ọ̀nà tó dára láti lo àǹfààní yìí ni pé kí á ka Ìwé Mímọ́ tààràtà láti inú Bíbélì, èyí á jẹ́ kí onítọ̀hún rí agbára tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A pàfíyèsí wa sí kókó yìí ní àpéjọ àkànṣe wa ti ọdún tó kọjá. Alábòójútó àyíká sọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ṣe Lágbára Tó Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Ǹjẹ́ o rántí àwọn kókó pàtàkì inú àsọyé yẹn?
Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ Jèhófà fi lágbára ju ọ̀rọ̀ ti wa lọ?—2 Tím. 3:16, 17.
Báwo ni Bíbélì ṣe ń mú ká ní ìmọ̀lára tó yẹ? Báwo ló ṣe ń mú ká máa ronú lọ́nà tó tọ́? Báwo ló sì ṣe ń tún èrò inú àti ìwà wa ṣe?—Wo Ilé Ìṣọ́, June 15, 2012, ojú ìwé 27, ìpínrọ̀ 7.
Tá bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún ẹnì kan lóde ẹ̀rí, báwo la ṣe lè pàfíyèsí rẹ̀ sí ohun tá a kà lọ́nà tó máa jẹ́ kí onítọ̀hún ní ọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 148, ìpínrọ̀ 3 sí 4 àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2013 ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 8.
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ ká sì fèrò wérò lórí ohun tá a kà, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?—Ìṣe 17:2, 3; wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 154, ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 156, ìpínrọ̀ 4.