Àpéjọ Àyíká Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà
Bá a bá fojú báwọn nǹkan ṣe ń lọ nínú ayé yìí wò ó, ṣe ló máa dà bíi pé kò sí mìmì kan tó lè mì ín. Ṣùgbọ́n ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yàtọ̀ sí irú èrò yẹn. (1 Jòh. 2:15-17) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé béèyàn bá ‘ń to ìṣúra jọ pa mọ́ lórí ilẹ̀ ayé’ yìí, òwò tí ò pé ló ń ṣe. Káwa èèyàn Ọlọ́run bàa lè gbára dì, àpéjọ àyíká ti ọdún 2007 máa tú iṣu désàlẹ̀ ìkòkò lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ To Ìṣúra Jọ Pa Mọ́ . . . ní Ọ̀run.”—Mát. 6:19, 20.
Lára ohun tí ìwé Éfésù 2:2 ń tọ́ka sí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa “olùṣàkóso ọlá àṣẹ afẹ́fẹ́, ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí nínú àwọn ọmọ àìgbọ́ràn” ni jíjẹ́ kí ìfẹ́ àtikó ọrọ̀ jọ gba èèyàn lọ́kàn. Bó ṣe jẹ́ pé kò síbi tí afẹ́fẹ́ tá à ń mí sínú ò sí, bákan náà ni “ẹ̀mí ayé” wà káàkiri nínú ètò àwọn nǹkan yìí. (1 Kọ́r. 2:12) Bíbélì sọ pé ẹ̀mí ayé ní “ọlá àṣẹ” nítorí pé ó lágbára láti darí ẹni. Àpéjọ àyíká tó ń bọ̀ lọ́nà yìí á ràn wá lọ́wọ́ láti máa yẹra fún kíkó ọrọ̀ jọ, ká bàa lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù. (Mát. 6:33) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa gbọ́ ní àpéjọ náà á ràn wá lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìfi ti àwọn ìṣòro àti àdánwò tó lè dojú kọ wá pè.
Rí i pé o wà ní àpéjọ náà ní gbogbo ọjọ́ méjèèjì kó o sì ‘fún un ní àfiyèsí tó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.’ (Héb. 2:1) Ṣe àkọsílẹ̀ ṣókí tó o mọ̀ pé ó máa wúlò fún ẹ nígbèésí ayé àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Bó o bá wà ní àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì tó kún fáwọn ìmọ̀ràn tó lè jẹ́ kéèyàn túbọ̀ fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run yìí, ìyànjú àti okun tí wàá rí gbà á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa bá a lọ ní ‘títo ìṣúra jọ pa mọ́ ní ọ̀run’!