ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/10 ojú ìwé 8
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 8/10 ojú ìwé 8

Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ilé Ìṣọ́ August 1

“Kí lo rò pé ó máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Mátíù 5:3.] Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa béèyàn ṣe lè láyọ̀ la ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí. Àpilẹ̀kọ yìí sọ àwọn ohun tá a kọ́ lọ́dọ̀ Jésù nípa béèyàn ṣe lè ní ojúlówó ayọ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 16 hàn án.

Ji! July–September

Ka Òwe 17:17. Lẹ́yìn náà, béèrè pé: “Tó o bá jẹ́ irú ọ̀rẹ́ tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, báwo lo ṣe máa ṣèrànwọ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ tó ń mu sìgá kó lè jáwọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun pàtàkì mẹ́rin tá a lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tó bá ń mu sìgá kó bàa lè jáwọ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 9 hàn án.

Ilé Ìṣọ́ September 1

Mẹ́nu ba ìròyìn kan tó ń jẹ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn ládùúgbò yín. Kó o wá sọ pé: “Ǹjẹ́ o máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí irú ìwà burúkú bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. [Ka 2 Pétérù 3:13.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ibi, ó sì tún sọ bí Ọlọ́run ṣe máa fòpin sí gbogbo ìwà ibi.”

Ji! July–September

“Ọ̀pọ̀ nǹkan ribiribi làwọn èèyàn ti fowó ṣe, àmọ́ ǹjẹ́ o mọ̀ pé nǹkan kan wà tí owó kò lè ṣe? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 7:12.] Òótọ́ ni pé owó lè dáàbò boni dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ ọgbọ́n Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì nìkan ló lè pèsè ojúlówó ààbò fún wa nígbà gbogbo.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́