ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/12 ojú ìwé 2-3
  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Èmi Kò Lè Dákẹ́”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Kí O sì Sọ Ọ̀rọ̀ Yìí Fún Wọn”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Ọkàn tí Àárẹ̀ Mú Ni Èmi Yóò Tẹ́ Lọ́rùn ní Kíkún”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 5/12 ojú ìwé 2-3

Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà

1. Ìwé wo ni ètò Ọlọ́run mú jáde ní àpéjọ àgbègbè ọdún 2010 sí 2011, báwo la sì ṣe máa lò ó?

1 Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó nígbà tí wọ́n mú ìwé tórúkọ rẹ̀ wá lókè yìí jáde ní Àpéjọ Àgbègbè “Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà!” tá a ṣe lọ́dún 2010 sí 2011! Àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè fi ṣàríkọ́gbọ́n nínú ìgbé ayé wa ojoojúmọ́ látinú ìwé Jeremáyà àti Ìdárò ló wà nínú ìwé yìí. (Róòmù 15:4) Ńṣe la dìídì ṣe é ká lè máa lò ó ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, a sì máa bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó láti ọ̀sẹ̀ November 5, 2012.

2. Kí nìdí táa fi máa jàǹfààní tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìwé Bíbélì náà, Jeremáyà àti Ìdárò?

2 Ó Ṣàǹfààní Lónìí: Àkókò tí nǹkan kò rọgbọ ní ilẹ̀ Júdà ni Ọlọ́run mí sí Jeremáyà láti kọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, kò gbà pé òun tóótun láti ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún yìí. (Jer. 1:6) Àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ pàápàá ṣe inúnibíni sí i, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ táwọn náà jẹ́ ọmọ ìlú Ánátótì bíi tiẹ̀ kẹ̀yìn sí i. (Jer. 11:21, 22) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé ìrẹ̀wẹ̀sì bá Jeremáyà láwọn ìgbà kan. (Jer. 20:14) Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa pé ká “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,” a sábà máa ń dojú kọ àwọn ìṣòro, a sì máa ń ní irú ìmọ̀lára tí Jeremáyà ní. (Mát. 28:19) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn àkọ́sílẹ̀ rẹ̀, ó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa fi ìgboyà àti ìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.

3. Báwo la ṣe máa lo àwọn apá pàtàkì kan nínú ìwé, Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà?

3 Àwọn Apá Pàtàkì: A kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe pàtàkì wínníwínní, ó sì yẹ kí ẹ kà wọ́n. Ní ìparí apá tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, a kọ ìbéèrè kan sí méjì tó kún fún ẹ̀kọ́, lọ́nà tó dúdú yàtọ̀, láti tẹnu mọ́ kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ ọ̀sẹ̀ náà. Ẹni tó bá darí ìpàdé máa lo àwọn ìbéèrè yìí láti ṣàtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú àwùjọ. Àwọn àwòrán mèremère wà jálẹ̀ inú ìwé náà tẹ́ ẹ máa fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí.

4. Báwo la ṣe lè jàǹfààní ní kíkún látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà?

4 Tó o bá fẹ́ jàǹfààní ní kíkún, rí i pé ò ń múra ẹ̀kọ́ tó o rí kọ́ sílẹ̀. Wá àwọn kókó tó lè wúlò fún ọ nígbèésí ayé rẹ̀ àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ. Rí i pé ò ń dáhùn dáadáa nígbà tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìwé yìí. Lọ́lá ìtìlẹ́yìn Jèhófà, Jeremáyà ṣe iṣẹ́ náà yanjú, ó sì ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. (Jer. 15:16) Ǹjẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa ṣe nínú ìwé tuntun yìí mú kí àwa náà lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wa, ká sì rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́