Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Fún Àwọn Èèyàn Ní Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi
Lẹ́yìn tá a bá ti kí onílé dáadáa, a lè sọ pé: “A ní ká wá fún ìdílé yín ní ìwé ìkésíni yìí. A fẹ́ fi pè yín wá síbi ìrántí pàtàkì kan tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún. Ìyẹn Ìrántí Ikú Kristi. Ọjọ́ Tuesday March 26, la máa ṣe é kárí ayé lọ́dún yìí. A máa gbọ́ ìwàásù látinú Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. Èyí tó máa jẹ́ ká mọ àǹfààní tí ikú Jésù ṣe fún wa. Àdírẹ́sì ibi tá a ti máa ṣe ìrántí náà àti aago tá a máa ṣe é wà nínú ìwé ìkésíni yìí.”
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Àwọn èèyàn kan máa ń béèrè pé ‘Kí ló jẹ́ kó dá wa lójú pé lóòótọ́ ni Jésù jíǹde?’ Àbí ìwọ náà ti béèrè irú ìbéèrè yẹn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ ká wo ìdí tó fi yẹ ká mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. [Ka 1 Kọ́ríńtì 15:14.] Ìwé yìí ṣàlàyé ohun tó jẹ́ ká gbà pé òótọ́ ni Jésù jíǹde.”
Jí! March–April
“Lásìkò tá a wà yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń ṣí láti ìlú kan lọ sí ibòmíì kí wọ́n lè rí ibi tí nǹkan ti máa ṣẹnuure fún wọn. Ǹjẹ́ o rò pé wọ́n máa ń rí ohun tí wọ́n ń wá lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti máa ń ṣí láti ìlú kan lọ sí ibòmíì. Wo àpẹẹrẹ kan nínú ìwé àkọ́kọ́ tó wà nínú Bíbélì. [Ka Jẹ́nẹ́sísì 46:5, 6.] Ìwé yìí dáhùn àwọn ìbéèrè kan nípa ohun tí à ń sọ yìí.” Fi àwọn ìbéèrè tó wà ní ìparí àpilẹ̀kọ kìíní lójú ìwé 6 hàn án.