Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Fún Àwọn Èèyàn Ní Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi
“À ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni síbi ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan. Ní April 14, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló máa pàdé láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n sì máa gbọ́ ìjíròrò Bíbélì kan lọ́fẹ̀ẹ́ tó dá lórí bí ikú Jésù Kristi ṣe ṣe wá láǹfààní. Ìwé ìkésíni yìí máa jẹ́ kó o mọ ibi tá a ti máa ṣe é ládùúgbò wa àti àkókò tá a máa ṣe é.”
Ilé Ìṣọ́ April 1
“Ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ yín ni pé a fẹ́ ká jọ sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa nǹkan kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe. Ẹ̀sìn yòówù ká máa ṣe, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo èèyàn ló máa ń gbàdúrà. Ṣé o rò pé Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà, àbí a kàn máa fi ń tu ara wa nínú nígbà tá a bá níṣòro ni? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa àdúrà. [Ka 1 Jòhánù 5:14.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí àdúrà ṣe lè ṣe wá láǹfààní.”
Ji! March–April
“À ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tí wọ́n lè ṣe sí ìṣòro kan tó ti ń wọ́pọ̀ báyìí. Àwọn èèyàn tó ń bẹ̀rù òkú máa ń gbìyànjú láti bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè tù wọ́n lójú tàbí kí wọ́n bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n ran àwọn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn òkú lè ṣe nǹkan kan fún àwọn tó wà láàyè? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ó jẹ́ ká mọ ipò tí àwọn òkú wà gangan. [Ka Oníwàásù 9:5.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká yẹra fún ìbẹ́mìílò, ká má sì gbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 12 hàn án.