Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù March
“Ìdí tá a fi wá sọ́dọ̀ yín ni pé, ohun kan máa ṣẹlẹ̀ ní April 14. Ọjọ́ yẹn ni àyájọ́ ikú Jésù. Ìdí táwọn kan fi máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ni pé wọ́n gbà pé ó ṣe pàtàkì. Àmọ́ àwọn míì ò tiẹ̀ mọ bí ikú Jésù ti ṣe pàtàkì tó. Ǹjẹ́ o rò pé ikú Jésù ṣe ìwọ àti èmi láǹfààní?” Jẹ́ kó fèsì. Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ March 1 hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ọ̀rọ̀ tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ níbẹ̀ àti ó kéré tán ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kí o sì ṣètò láti pa dà wá dáhùn ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ March 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run kò fi fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjìyà tó wà láyé. Ṣé o rò pé Ọlọ́run ò bìkítà ni àbí torí pé ó fẹ́ káwa èèyàn máa jìyà? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Jòhánù 3:16.] Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló máa ń sọ ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ tí wọ́n bá fẹ́ fi hàn pé Ọlọ́run bìkítà, kò dá wọn lójú pé ikú ọmọ Ọlọ́run lè ṣe wọ́n láǹfààní. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí ikú Jésù ṣe máa mú kí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìjìyà dópin láyé.”
Ji! March–April
“Ǹjẹ́ ẹ gbà pé ọ̀pọ̀ ìṣòro ló ń dojú kọ ìdílé lónìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Òwe Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ ohun táwọn ìdílé gbọ́dọ̀ ní kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí, kí wọ́n sì ṣe ara wọn lọ́kan. [Ka Òwe 24:3.] Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé ọgbọ́n tó ṣeé gbára lé wà nínú Bíbélì. Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa ìkànnì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀, tó ní àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì tó lè ran ìdílé lọ́wọ́.”