Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù March
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù, àmọ́ ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣèrántí ikú rẹ̀?” Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, fún onílé ní Ilé Ìṣọ́ March 1, ẹ jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16, kẹ́ ẹ sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ kẹ́ ẹ lè jọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
March 1
“Onírúurú ẹ̀kọ́ àti àṣà ni ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ẹ̀sìn lóríṣiríṣi ń gbé lárugẹ. Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo àwọn tó ń pe ara wọn ní Kristẹni náà ni Kristẹni lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo àmì kan tí Jésù sọ pé a lè fi dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. [Ka Jòhánù 13:34, 35.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn gbólóhùn márùn-ún tí Jésù sọ tó jẹ́ ká mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tòótọ́.”
January–March
“Láyé tá a wà yìí, àwọn èèyàn kò fojú pàtàkì wo ìgbéyàwó mọ́. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó fà á? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 2 Tímótì 3:1-5.] Bí àwọn tọkọtaya bá jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú tí wọ́n sì ń ṣìkẹ́ ara wọn, ìgbéyàwó wọn máa yọrí sí rere. Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò àwọn ohun márùn-ún tó lè mú kí ìgbéyàwó wà pẹ́ títí.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 20 hàn án.