Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù May
“Kò sí èèyàn kankan tí kì í ṣe àṣìṣe. Àmọ́ ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run lè dárí jì wá tá a bá tiẹ̀ ṣe àṣìṣe tó burú gan-an?” [Jẹ́ kó fèsì.] Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 15 hàn án nínú Ilé Ìṣọ́ May 1, kó o sì jíròrò ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Kí ẹ ka ẹsẹ Bíbélì kan, ó kéré tán. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣàdéhùn ìgbà tí wàá pa dà wá kẹ́ ẹ lè jọ jíròrò ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ May 1
“A fẹ́ mọ ohun tó o rò nípa ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ. [Ka 1 Jòhánù 4:8.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé òótọ́ lohun tí Bíbélì yìí sọ, àmọ́ àwọn míì rò pé òǹrorò ni Ọlọ́run torí pé ó fàyè gbà á kí àjálù ṣẹlẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń sọ pé àmúwá Ọlọ́run ni. Kí ni ìwọ rò? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn ìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká máa dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló ń fa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀.”
Jí! May–June
“Ibi gbogbo kárí ayé ni ìjà ti sábà máa ń wáyé láàárín tọkọtaya. Àwọn kan sọ pé àṣà ìbílẹ̀, bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà àtàwọn ohun tí wọ́n ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n ló fà á. Kí ni ìwọ rò pé ó jẹ́ olórí ohun tó máa ń mú kí àwọn ọkọ lu ìyàwó wọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ bó ṣe yẹ kí àárín tọkọtaya rí. [Ka Éfésù 5:33.] Ìwé yìí sọ bí àwọn tọkọtaya kan ṣe tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì yìí tí àlàáfíà sì wá jọba láàárín wọn.”