“Màá Gba Ìwé Yín Tí Ìwọ Náà Bá Gba Ìwé Wa”
Ohun táwọn kan máa ń sọ nìyí tá a bá fún wọn ní àwọn ìwé wa. A mọ̀ pé a kì í fi àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pààrọ̀ àwọn ìwé ẹ̀sìn tó ń tan ẹ̀kọ́ èké kálẹ̀, báwo la wá ṣe lè fọgbọ́n fèsì? (Róòmù 1:25) A lè sọ pé: “Ẹ ṣeun gan-an ni. Kí ni ìwé yín sọ nípa ojútùú sí àwọn ìṣòro aráyé? [Jẹ́ kó fèsì. Tó bá sọ pé kó o ka ìwé tóun fi lọ̀ ẹ́ kó o lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè tó o bi í, o lè rán an létí pé kó o tó fi ìwé tìẹ lọ̀ ọ́, o kọ́kọ́ sọ ohun tó wà nínú rẹ̀ fún un. Lẹ́yìn náà, o lè ka Mátíù 6:9, 10 tàbí kó o sọ ohun tó wà níbẹ̀ fún un.] Jésù sọ pé Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ láyé. Nítorí náà, Ìjọba Ọlọ́run ni ìwé ẹ̀sìn kan ṣoṣo tí mo máa ń kà dá lé. Ṣé mo lè fi àwọn ohun pàtó tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe hàn ẹ́ nínú Bíbélì?”