ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JEREMÁYÀ 25-28
Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà
Jeremáyà kìlọ̀ pé Jerúsálẹ́mù máa dahoro bí ìlú Ṣílò
Ìgbà kan wà tí wọ́n tọ́jú àpótí ẹ̀rí tó ṣàpẹẹrẹ pé Jèhófà wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ sí ìlú Ṣílò
Jèhófà gbà kí àwọn Filísínì gbé Àpótí náà, bó ṣe di pé kò pa dà sí Ṣílò mọ́ nìyẹn
Àwọn àlùfáà, wòlíì àtàwọn èèyan náà lérí pé àwọn máa pa Jeremáyà
Àwọn èèyàn náà gbá Jeremáyà mú torí pé ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ máa pa run
Jeremáyà kò pa iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé e lọ́wọ́ tì, kó wá sá lọ
Jèhófà dáàbò bo Jeremáyà
Jeremáyà jẹ́ onígboyà, Jèhófà kò sì fi í sílẹ̀
Jèhófà lo ọkùnrin onígboyà náà, Áhíkámù láti dáàbò bo Jeremáyà
Torí pé Jèhófà ti Jeremáyà lẹ́yìn tó sì fún un níṣìírí, ogójì [40] ọdún gbáko ló fi wàásù ohun táwọn èèyàn ò nífẹ̀ẹ́ sí