ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 August ojú ìwé 8
  • Ìgbà Wo Ni Mo Tún Lè Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Wo Ni Mo Tún Lè Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Láyọ̀ Ó sì Nírètí Bí Kò Tiẹ̀ Lówó Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ohun Pàtàkì Tó Yẹ Ká Fojú Sùn Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀ Yìí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • A Ń Fẹ́—30,000 Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • A Ní Àǹfààní Púpọ̀ Sí I Láti Yin Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 August ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ìgbà Wo Ni Mo Tún Lè Ṣe Olùrànlọ́wọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà?

Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí fi hàn pé àwọn èèyàn Jèhófà á máa fi tinútinú lo ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè máa rú ẹbọ ìyìn sí Jèhófà?​—⁠Heb 13:​15, 16.

Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn oṣù kan wà nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn 2018 tó ní Sátidé àti Sunday márùn-ún. Àǹfààní ni èyí sì jẹ́ fún àwọn tó jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń jáde òde ẹ̀rí nítorí iṣẹ́ wọn. Ohun míì ni pé àwọn akéde lè yàn láti lo ọgbọ̀n [30] tàbí àádọ́ta [50] wákàtí ní oṣù March àti April àti nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká.

Àmọ́ kí la lè ṣe tí a ò bá lè ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà báyìí? A lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sunwọ̀n sí i, ká sì gbìyànjú láti fi kún àkókò tá à ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ipò yòówù ká wà, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà mú kí á fi ohun tó níye lórí bọlá fún un, pàápàá lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2018!​—⁠Ho 14:⁠2.

Sabina Hernández fi ẹnu mú báírò dání láti fi buwọ́ lu fọ́ọ̀mù olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà

Báwo ni mo ṣe lè ní ìtara bíi ti Sabina Hernández?

WO FÍDÍÒ NÁÀ, LỌ́LÁ JÈHÓFÀ, KÒ SÓHUN TÍ MI Ò LÈ ṢE, LẸ́YÌN NÁÀ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Kí ló mú kí Sabina pinnu láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

  • Kí lo rí kọ́ lára Sabina?

  • Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2018, oṣù wo lo máa fẹ́ ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́