Akéde kan ń fi ìwé àṣàrò kúkúrú Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? ní èdè Tuvalu lọ ẹnì kan
Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
JÍ!
Béèrè ìbéèrè: Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa múra sílẹ̀ de àjálù?
Ka Bíbélì: Owe 27:12
Fi ìwé lọni: Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe kí àjálù tó wáyé, nígbà àjálù àti lẹ́yìn tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀.
MÁA FI ÒTÍTỌ́ KỌ́NI
Béèrè ìbéèrè: Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?
Ka Bíbélì: 1Jo 5:3
Òtítọ́: Tá a bá ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
ǸJẸ́ ÀWỌN ÒKÚ LÈ JÍǸDE? (T-35)
Béèrè ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé máa ń ṣe àjọyọ̀ ọdọọdún láti ṣàyẹ́sí àwọn òkú. Ǹjẹ́ ẹ rò pé a tún lè rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?
Ka Bíbélì: Iṣe 24:15
Fi ìwé lọni: Ìwé yìí sọ àǹfààní tí ìrètí àjíǹde máa ṣe fún wa. [Tó bá ṣeé ṣe, jẹ́ kó wo fídíò náà Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?]
KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ
Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.