ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÁMÓSÌ 1-9
“Wá Jèhófà, Kí O sì Máa Wà Láàyè Nìṣó”
Kí ló túmọ̀ sí láti wá Jèhófà?
Ó túmọ̀ sí pé ká túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọn kò wá Jèhófà mọ́?
Wọ́n dẹni tí kò ‘kórìíra ohun búburú mọ́, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere’
Bí wọ́n á ṣe tẹ́ ara wọn lọ́rùn ni wọ́n ń lé
Wọn kò tẹ̀ lé ìtọ́ni Jèhófà
Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà ti pèsè fún wa tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa wá a?