ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 20-21
“Ẹnì Yòówù Tí Ó Bá Fẹ́ Di Ẹni Ńlá Láàárín Yín Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́ Yín”
Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí onígbèéraga fẹ́ràn ìwà ṣekárími àti káwọn èèyàn máa kí wọn níbi ọjà
Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí onígbèéraga máa ń pe àfiyèsí síra wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ wà ní ipò ọlá. (Mt 23:5-7) Jésù yàtọ̀ sí wọn. “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́.” (Mt 20:28) Ṣé apá táwọn èèyàn á ti mọ̀ wá, tí wọ́n á sì ti máa yìn wá la máa ń fẹ́ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run? Tá a bá fẹ́ jẹ́ ẹni ńlá lójú Jèhófà, àfi ká máa sapá láti dà bíi Jésù, ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwọn èèyàn lè má kíyè sí ohun tá a ṣe, àmọ́ Jèhófà rí i. (Mt 6:1-4) Òjíṣẹ́ tó nírẹ̀lẹ̀ á máa . . .
kópa nínú iṣẹ́ ìmọ́tótó àti àtúnṣe Gbọ̀ngàn Ìjọba
lo ìdánúṣe láti ran àwọn àgbàlagbà àtàwọn míì lọ́wọ́
fowó ṣe ìtìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run