ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 March ojú ìwé 3
  • Àwọn Wo Ni Mo Lè Pè?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Wo Ni Mo Lè Pè?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 17
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Jèhófà Máa Ń Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣe Ìrántí Ikú Kristi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 March ojú ìwé 3
Arákùnrin kan ń fún mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìwé ìkésíni sí ìrántí Kristi nígbà tí wọ́n jọ ń jẹun. Àwọn ìyàwó wọn sì ń sọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe ń dáná lẹ́yìn wọn.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Àwọn Wo Ni Mo Lè Pè?

Lọ́dọọdún, a máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti pe àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa síbi Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tá à ń pè la ò mọ̀ rí. Àmọ́ ó tún yẹ ká gbìyànjú láti pe àwọn tá a mọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń yá àwọn èèyàn lára láti wá tó bá jẹ́ pé ẹni tí wọ́n mọ̀ ló fún wọn ní ìwé ìkésíni. (km 2/09 1 ¶3; w13 1/15 32) Àwọn wo la lè pè wá?

  • Àwọn mọ̀lẹ́bí wa

  • Àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọ ilé ìwé wa

  • Àwọn aládùúgbò wa

  • Àwọn ìpadàbẹ̀wò àtàwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, yálà èyí tá à ń ṣe lọ́wọ́ tàbí èyí tá a ti pa tì

Bákan náà, àwọn alàgbà máa pe àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́. Kí lo lè ṣe tí ẹni tó o fẹ́ pè ò bá gbé ládùúgbò yín? O lè wá àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi níbi tẹ́ni náà ń gbé. Wàá rí i lórí ìkànnì jw.org/⁠yo, ní abala tá a pè ní NÍPA WA, lọ sábẹ́ “Ìrántí.” Bó o ṣe ń múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, ronú nípa àwọn tó o lè pè kó o sì gbìyànjú láti fún wọn ní ìwé ìkésíni.

Àwòrán: 1. Arákùnrin kan ń wàásù fún ọkùnrin kan nígbà ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. 2. Arákùnrin kan ń fi fídíò han òṣìṣẹ́ ilé oúnjẹ kan.
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́