MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀—Má Ṣe Máa Fọ́nnu
Ìgbéraga ló máa ń mú kéèyàn fọ́nnu, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kì í sì í gbé àwọn míì ró. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹlòmíì ni kó yìn ọ́, kì í ṣe ẹnu tìrẹ.”—Owe 27:2.
WO FÍDÍÒ NÁÀ DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ—JẸ́ ONÍRẸ̀LẸ̀, LẸ́YÌN NÁÀ KÓ O DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí làwọn nǹkan tó máa ń mú káwọn èèyàn máa fọ́nnu?
Kí ló mú kí Kọ́lá máa fọ́nnu sí ọ̀rẹ́ rẹ̀?
Báwo ni Bàbá Kọ́lá ṣe jẹ́ kó mọ̀ pé kò dáa kéèyàn máa fọ́nnu?
Báwo ni 1 Pétérù 5:5 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?