ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 13-14
“Ẹ Dúró Gbọn-in, Kí Ẹ sì Rí Bí Jèhófà Ṣe Máa Gbà Yín Là”
Jèhófà máa ń gba tẹni rò tó bá ń gbani là. Báwo ló ṣe gba tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì rò nígbà tó mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì?
Ó tò wọ́n lọ́wọ̀ọ̀wọ́.—Ẹk 13:18
Ó tọ́ wọn sọ́nà, ó sì dáàbò bò wọ́n.—Ẹk 14:19, 20
Ó gba gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀, lọ́mọdé àti lágbà.—Ẹk 14:29, 30
Kí ló dá wa lójú bí ìpọ́njú ńlá ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé?—Ais 30:15