MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ẹ Dúró Gbọn-in Bí Òpin Ṣe Ń Sún Mọ́lé
ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Láìpẹ́, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbankọgbì máa dán wa wò, ìyẹn á sì fi hàn bóyá a nígboyà àti ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ìparun ìsìn èké ló máa bẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá. (Mt 24:21; Ifi 17:16, 17) Lákòókò tí nǹkan máa lé ganan yẹn, ó ṣeé ṣe ká máa kéde ọ̀rọ̀ ìdájọ́ tó dà bí òkúta yìnyín. (Ifi 16:21) Lẹ́yìn náà, Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù máa gbéjà kò wá. (Isk 38:10-12, 14-16) Ìyẹn ló máa mú kí Jèhófà gbégbèésẹ̀, kí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè” sì bẹ̀rẹ̀. (Ifi 16:14, 16) Tá a bá ń fìgboyà kojú àwọn ohun tó lè dán ìgbàgbọ́ wa wò ní báyìí, àá túbọ̀ nígboyà láti kojú àwọn ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
BÓ O ṢE LÈ ṢE É:
Fìgboyà dúró lórí àwọn ìlànà Jèhófà nípa ìwà rere.—Ais 5:20
Máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará.—Heb 10:24, 25
Máa tẹ̀ lé ìlànà èyíkéyìí tí ètò Ọlọ́run bá fún wa láìjáfara.—Heb 13:17
Máa ronú lórí bí Jèhófà ṣe gba àwọn èèyàn rẹ̀ là nígbà àtijọ́.—2Pe 2:9
Máa gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì gbẹ́kẹ̀ lé e.—Sm 112:7, 8
WO FÍDÍÒ NÁÀ ÀWỌN OHUN TÓ MÁA ṢẸLẸ̀ LỌ́JỌ́ IWÁJÚ TÓ GBA PÉ KÁ NÍ ÌGBOYÀ—ÀYỌLÒ, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àdánwò wo làwọn àkéde kan kojú nígbà tí ìjọ wọn pín sí méjì?
Tá a bá ń ṣègbọràn, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà?
Kí nìdí tá a fi máa nílò ìgboyà nígbà tí Amágẹ́dọ́nì bá dé?
Múra sílẹ̀ ní báyìí bó o ṣe ń retí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú tó máa gba pé ká nígboyà
Ìtàn Bíbélì wo ló lè mú kó túbọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà máa gbà wá là?—2Kr 20:1-24