ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 25-26
Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Àgọ́ Ìjọsìn
Àpótí májẹ̀mú ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú ibùdó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé Ọlọ́run wà láàárín àwọn nígbà tí wọ́n bá rí ìkùukùu tó wà lórí ìbòrí àpótí náà láàárín àwọn kérúbù méjèèjì. Ní Ọjọ́ Ètùtù, àlùfáà àgbà máa ń wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ, á sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ síwájú ìbòrí kó lè ṣètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Le 16:14, 15) Ohun tí wọ́n ń ṣe yẹn jẹ́ ká rí bí Jésù tó jẹ́ àlùfáà àgbà tó tóbi jù lọ ṣe wọlé síwájú Jèhófà kó lè gbé ìtóye ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó fi rà wá pa dà fún Jèhófà.—Heb 9:24-26.
Ohun mẹ́ta tí ikú Jésù ṣe fún wa ló wà nísàlẹ̀ yìí, fàlà sí ẹsẹ Bíbélì tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mu:
BÍBÉLÌ
OHUN TÍ IKÚ JÉSÙ ṢE FÚN WA
ó jẹ́ ká ní ìrètí láti wà láàyè títí láé
ó jẹ́ ká rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa
ó jẹ́ ká ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́
Kí ló yẹ ká ṣe ká lè gbádùn àwọn ìbùkún yìí?