ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Gbára Lé Jèhófà fún Ìrànlọ́wọ́
Jèhófà máa ń gbọ́ igbe wa fún ìrànlọ́wọ́ (2Sa 22:7)
Jèhófà lágbára ju ọ̀tá èyíkéyìí lọ (2Sa 22:14-18; cl 19 ¶11)
Torí pé Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa gbé ìgbésẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ (2Sa 22:26; w10 6/1 26 ¶4-6)
Jèhófà lágbára láti mú àwọn ìṣòro wa kúrò. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹgbẹ́ ará láti fún wa lókun ká lè fara dà á. (Sm 55:22) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe kí Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́?