ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jèhófà Ṣe Ohun Tó Dà Bíi Pé Kò Ṣeé Ṣe
Lásìkò tí iyàn mú gan-an, Jèhófà sọ pé oúnjẹ máa pọ̀ rẹpẹtẹ lọ́jọ́ kejì (2Ọb 7:1; it-1 716-717)
Ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin sọ pé ohun tí Jèhófà sọ ò ṣeé ṣe (2Ọb 7:2)
Jèhófà ṣe ohun tó dà bíi pé kò ṣeé ṣe (2Ọb 7:6, 7, 16-18)
Jèhófà sọ pé ayé búburú yìí máa pa run lójijì, lásìkò tẹ́nikẹ́ni ò retí. (1Tẹ 5:2, 3) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gba ohun tí Jèhófà bá sọ gbọ́?