ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Káwa Kristẹni Máa Sapá Láti Tẹ̀ Síwájú?
Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa ń sapá kí ọwọ́ wọn lè tẹ àwọn àfojúsùn kan nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ń sapá kí wọ́n lè di aṣáájú-ọ̀nà, àwọn míì fẹ́ ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tàbí kí wọ́n bá àwọn tó ń kọ́ ilé ètò Ọlọ́run ṣiṣẹ́. Bákan náà, àwọn arákùnrin kan ń sapá kí wọ́n lè di alábòójútó nínú ìjọ. (1Ti 3:1) Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó yẹ káwa Kristẹni máa lépa àtiwà nípò ńlá?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ MÁA SAPÁ LÁTI TẸ̀ SÍWÁJÚ? (1TI 3:1), KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká rí ìdí mẹ́ta tó fi yẹ ká sapá láti tẹ̀ síwájú?