ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Jèhófà Máa Ń Bù Kún Ìsapá Tá A Bá Fi Gbogbo Ọ̀kan Ṣe
Èlíṣà sọ fún Ọba Jèhóáṣì pé kó ṣe ohun kan tó ṣàpẹẹrẹ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa ṣẹ́gun àwọn ará Síríà (2Ọb 13:15-18)
Torí pé Jèhóáṣì ò fi gbogbo ọ̀kan ẹ̀ sí ohun tí Èlíṣà ní kó ṣe, àṣeyọrí tó ṣe ò tó nǹkan (2Ọb 13:19; w10 4/15 26 ¶11)
Jèhófà máa ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń wá a tọkàntọkàn (Heb 11:6; w13 11/1 11 ¶5-6)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ó hàn pé tọkàntọkàn ni mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó bá dọ̀rọ̀ ọwọ́ tí mo fi mú àwọn nńkan bí iṣẹ́ ìwàásù, Bíbélì kíkà àti wíwá sípàdé?’