ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN
Ọgbọ́n Táwọn Alátakò Máa Ń Dá Kí Wọ́n Lè Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Wa
Àwọn alátakò máa ń parọ́ mọ́ àwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò Ọlọ́run kí wọ́n lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa (2Ọb 18:19-21; w05 8/1 11 ¶5)
Wọ́n máa ń sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa Jèhófà àti ètò rẹ̀ kí wọ́n lè ṣì wá lọ́nà (2Ọb 18:22, 25; w10 7/15 13 ¶3)
Wọ́n lè ṣèlérí tí wọn ò ní lọ́kàn láti mú ṣẹ kí wọ́n lè fi tàn wá kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà (2Ọb 18:31, 32; w13 11/15 19 ¶14; yb74 177 ¶1)
BÍ ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan wo ló yẹ kí n ṣe báyìí kí ìgbàgbọ́ mi lè lágbára, kí n má bàa bọ́hùn tí inúnibíni bá dé?’