Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 3
1 Aposteli Paulu fẹ́ kí àwọn arákùnrin rẹ̀ gbàdúrà nítorí rẹ̀, kí ó baà lè ní agbára àtisọ ìhìn rere náà láìṣojo. (Efe. 6:18-20) Ó wù wá láti mú irú agbára yẹn dàgbà. Láti lè ṣe bẹ́ẹ̀, a mọrírì ìrànwọ́ tí à ń rígbà láti inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun, nínú èyí tí a rọ àwọn tí ń wá sí ìpàdé, tí wọ́n tóótun, láti forúkọ sílẹ̀.
2 Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́, a ń gba ìmọ̀ràn tí ó kàn wá gbọ̀ngbọ̀n, tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú agbára ìsọ̀rọ̀ àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i. (Owe 9:9) A tún lè jàǹfààní láti inú fífetí sílẹ̀ sí ìmọ̀ràn tí a fí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn, ní mímú ohun tí a kọ́ bá ara wa mu. Nígbà tí a bá ń múra iṣẹ́ àyànfúnni sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a tí mú iṣẹ́ náà jáde dáradára, láti rí i dájú pé àlàyé wa nípa rẹ̀ péye. Àwọn kókò pàtàkì àti àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a óò lò gbọ́dọ̀ bá ìgbékalẹ̀ ẹṣin ọ̀rọ̀ náà mu. Bí iṣẹ́ àyànfúnni náà bá ní ẹlòmíràn nínú, a gbọ́dọ̀ fi dánra wò dáradára ṣáájú gbígbé e kalẹ̀ nínú ilé ẹ̀kọ́. Bí a ti ń tẹ̀ síwájú, a ní láti sapa láti lè sọ̀rọ̀ ní ọ̀rọ̀ ara ẹni, ní lílo àkọsílẹ̀ ṣókí dípò kíka ìwé.
3 Gbogbo àwọn tí ó ní iṣẹ́ àyànfúnni ní ilé ẹ̀kọ́ gbọ́dọ̀ tètè dé, kí wọ́n fún alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ní ìwé Imọran Ọrọ Sisọ wọn, kí wọ́n sì jókòó sí ọwọ́ iwájú nínú gbọ̀ngàn. Àwọn arábìnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ ṣáájú, bí ìgbékalẹ̀ wọn yóò ṣe rí àti bóyá wọn yóò dúró tàbí jókòó nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ wọn. Fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní ọ̀nà yìí ń mú kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ lọ déédéé, ó sì ń ran àwọn tí ń bójú tó pèpéle lọ́wọ́ láti pèsè gbogbo ohun tí a nílò sílẹ̀ ṣáájú àkókò.
4 Mímúra Iṣẹ́ Àyànfúnni No. 2 Sílẹ̀: Ète kan fún Bibeli kíkà jẹ́ láti ran akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mú agbára ìkàwé rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Báwo ni a ṣe lè ṣe èyí lọ́nà tí ó dára jù lọ? Kíka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ náà sókè ní àkàtúnkà ni ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti mọ̀ ọ́n dáradára. Fún pípe ọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́ ní àfiyèsí dáradára. Bí ọ̀rọ̀ méjì tí ó ní ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ní sípẹ́lì kan náà, dídi ojúlùmọ̀ pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tí ó wà yóò ran ẹni tí ń kà á lọ́wọ́ láti pe ọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́.
5 Ọ̀nà míràn tí o lè gbà mú bí o ti ń pe ọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i jẹ́ nípa kíkàwé fún ẹlòmíràn, ẹnì kan tí ń pe ọ̀rọ̀ dáradára, kí o sì sọ fún un pé kí ó dá ọ dúró nígbàkígbà tí o bá ti ṣi ọ̀rọ̀ kan pè, kí ó sì kọ́ ọ bí wọ́n ti ń pè é. Síwájú sí i, fetí sílẹ̀ dáradára sí àwọn tí ó mọ̀wé kà dáradára, kí o sì máa fọkàn bá a lọ bí wọ́n ti ń kàwé; kíyè sí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n pè yàtọ̀ sí bí ìwọ́ tí ń pè e. Kọ wọ́n sílẹ̀, kí o sì fi wọ́n dánra wò. Láìpẹ́ láìjìnnà, ìwọ pẹ̀lú yóò bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn ọ̀rọ̀ lọ́nà títọ́.
6 Àwọn òbí lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ wọn kéékèèké láti múra iṣẹ́ àyànfúnni ìwé kíkà wọn sílẹ̀. Èyí lè kan fífetí sílẹ̀ nígbà tí ọmọ náà bá ń ṣe ìfidánrawò, kí wọ́n sì fún un ní àwọn àbá wíwúlò láti sunwọ̀n sí i. Àkókò tí a yàn fúnni fàyè sílẹ̀ fún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí àti ìparí ọ̀rọ̀ bíbá a mu wẹ́kú, tí ó ṣe ìfisílò àwọn kókó pàtàkì. Akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò tipa báyìí mú agbára àtisọ̀rọ̀ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ dàgbà.
7 Onipsalmu náà bẹ̀bẹ̀ tàdúràtàdúrà pé: “Oluwa, ìwọ́ ṣí mi ní ètè; ẹnu mi yóò sì máa fi ìyìn rẹ hàn.” (Orin Da. 51:15) Ǹjẹ́ kí ipa tí a ń kó nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ́ ìfẹ́ ọkàn kan náà yìí lọ́rùn.