Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún March
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 4
Orin 1
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
10 min: “Fi Ìbùkún fún Jehofa ‘ní Gbogbo Ọjọ́.’” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 2 sí 5 bí àkókò bá ti yọ̀ǹda sí. Fúnni ní ìṣírí tí ń gbéni ró láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ àti aṣáájú ọ̀nà déédéé.
15 min: “Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ń tani jí láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, tí a gbé karí ìpínrọ̀ 1 sí 12 nínú àkìbọnú.
15 min: “Ìmọ̀ Ọlọrun Tòótọ́ Ń Sinni Lọ sí Ìyè.” Gbé àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn yẹ̀ wò. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì.
Orin 78 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 11
Orin 164
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ó yẹ kí àwọn tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ẹni tuntun, tí ń tẹ̀ síwájú dáradára nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọn, níṣìírí láti lépa góńgó dídi akéde tí kò tí ì ṣe ìrìbọmi. Àwọn òbí pẹ̀lú lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti di akéde. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà tí a là lẹ́sẹẹsẹ nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 97 sí 100.
15 min: “Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ.” Jíròrò ìpínrọ̀ 13 sí 16 nínú àkìbọnú pẹ̀lú àwùjọ. Tẹnu mọ́ ṣíṣe àkànṣe ìsapá láti pín Ilé-Ìṣọ́nà àti Ji! kiri ní April àti May. Níwọ̀n bí a ti ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn náà jáde ní oríṣiríṣi èdè, a ní láti sọ fún àwọn tí ń sọ èdè àjèjì pé a lè máa mú ìwé ìròyìn wá fún wọn déédéé lédè àbínibí wọn. Ní ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́, pípín ìwé ìròyìn wá lè jẹ́ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ jù lọ láti mú ọkàn-ìfẹ́ dàgbà, níwọ̀n bí wọ́n ti ń pèsè àkọ̀tun ìsọfúnni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Níbi tí a bá ti fi ìfẹ́ hàn nígbà ìpadàbẹ̀wò, fi àsansílẹ̀-owó lọni. Jẹ́ kí agbo ìdílé kan ṣàṣefihàn ìfidánrawò kan, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe ní ìpínrọ̀ 13. Pẹ̀lúpẹ̀lú, sọ àwọn àbá gbígbéṣẹ́ mélòó kan fún mímú kí fífìwé sóde pọ̀ sí i.
15 min: “Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 3.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Fún gbogbo àwọn tí ó bá lè forúkọ sílẹ̀ níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀, kí wọ́n sì fí ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ àyànfúnni wọn.
10 min: “Ìwé Ìròyìn Lédè Hausa.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn.
Orin 211 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 18
Orin 6
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “Ìpè Tí Ń Runi Sókè Dún Jáde ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè!—Ẹ Fi Ìdùnnú-Ayọ̀ Yin Jehofa Láti Ọjọ́ dé Ọjọ́!” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
20 min: “Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Jèrè Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè.” Ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò. Fi àṣefihàn kan tàbí méjì kún un. Tẹnu mọ́ góńgó bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.
Orin 130 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní March 25
Orin 5
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò “Ìránnilétí Ìṣe Ìrántí.” Ṣàlàyé ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti wà níbẹ̀. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1985, ojú ìwé 16 sí 18.) Ṣàyẹ̀wò ìwéwèé láti ran àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àti àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti wà níbẹ̀. Jíròrò ètò tí ẹ ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá tí a mú gbòòrò sí i láàárín ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ yìí. Síwájú sí i, ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ibi Tí A Ti Ń Fi Ẹ̀mí Ìgbàlejò Hàn Sí Àwọn Àjèjì,” nínú Ji!, October 8, 1995, ojú ìwé 15.
15 min: “Ìwé Tuntun Tẹnu Mọ́ Ìmọ̀ Ọlọrun.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti dojúlùmọ̀ pátápátá pẹ̀lú àwọn ohun tí ó wà nínú ìwé náà kí wọ́n baà lè lò ó lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú pápá.
10 min: Ẹ Máa Ṣe Nǹkan Pọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé. Bàbá ń bá ìdílé rẹ́ sọ̀rọ̀ láìjẹ́bí àṣà nípa àìní náà fún jíjọ wà pọ̀, tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, September 1, 1993, ojú ìwé 16 sí 19. Kó àfiyèsí jọ sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti iṣẹ́ ajíhìnrere. Mẹ́nu kan bí àwọn ìdílé òde òní ṣe ń fọ́ sí wẹ́wẹ́ nítorí pé àkókò díẹ̀ ni wọ́n ń lo pa pọ̀, wọn kò sì ní ìlépa kan náà. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti ṣíṣàjọpín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pa pọ̀ jẹ́ ìbùkún fún ìdílé Kristian. Tẹnu mọ́ àìní fún bàbá láti ṣètò àwọn ohun wọ̀nyí dáradára àti fún ìyá láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ ní ọkàn-ìfẹ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, ní ṣíṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn. Ìdílé yóò wà ní ìṣọ̀kan, a óò sì fún wọn lókun láti kojú àwọn ìkìmọ́lẹ̀ tí ń pọ̀ sí i síhà jíjẹ́ ẹlẹ́mìí ayé.
10 min: “Ìmúrasílẹ̀—Kọ́kọ́rọ́ Àṣeyọrí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Mẹ́nu kàn án pé a óò fí àsansílẹ̀-owó fún Ilé-Ìṣọ́nà lọni ní April àti May. Ẹ ṣètò nísinsìnyí nípa bíbéèrè fún àfikún ẹ̀dà, gbígba fọ́ọ̀mù tí a fi ń ṣe àsansílẹ̀-owó, àti ṣíṣe ìwéwèé láti ti ètò tí ìjọ ṣe fún ìgbòkègbodò Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn lẹ́yìn.
Orin 7 àti àdúrà ìparí.