Ìwé Ìròyìn Lédè Hausa
1 Ẹ ha ní àwọn ènìyàn tí ń sọ Hausa ní ìpínlẹ̀ yín bí? Kò sí iyè méjì pé gbogbo ìjọ tí ó wà ní Àríwá yóò dáhùn pé Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ní Gúúsù ńkọ́? Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń sọ Hausa wà ní ọ̀pọ̀ jù lọ ìlú ńlá ní Gúúsù pẹ̀lú. Kódà wọ́n wà ní àwọn ìlú kéékèèké àti àwọn ìgbèríko lórílẹ̀-èdè yìí. Ìjọ yín ha ní ìṣètò ìgbàwé pípẹ́ títí fún ìwé ìròyìn lédè Hausa bí?
2 A ń rọ àwọn ìjọ tí wọ́n ní àwọn ènìyàn tí ń sọ Hausa ní ìpínlẹ̀ wọn láti kọ̀wé fún ìṣètò ìgbàwé pípẹ́ títí fún, ó kéré tán, ìwé ìròyìn mélòó kan lédè Hausa lóṣooṣù. A dábàá pé kí àwọn ìjọ ńlá béèrè fún ó kéré tán, Ilé-Ìṣọ́nà márùn-ún lédè Hausa lóṣù. Ẹ rántí pé, ẹ̀ẹ̀kan péré ni a ń tẹ̀ ẹ́ jáde lóṣù. Àwọn ìjọ kéékèèké lè béèrè fún ìwé ìròyìn méjì tàbí mẹ́ta. Ó yẹ kí aṣáájú ọ̀nà kọ̀ọ̀kan béèrè fún ó kéré tán, ẹyọ kan lóṣù, bí wọ́n bá ní àwọn tí ń sọ Hausa ní ìpínlẹ̀ wọn. Dájúdájú, àwọn tí ó wà ní àgbègbè tí a tí ń sọ Hausa yóò fẹ́ láti béèrè fún púpọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ rí i dájú pé, ẹ béèrè ohun tí àwọn ará yóò máa gbà déédéé.
3 Àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti ní ìwé ìròyìn mélòó kan lédè Hausa lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá ń lọ fún iṣẹ́ ìwàásù, tàbí nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí ọjà. Wá àwọn tí ń ka Hausa rí, kí o sì fi ìwé ìròyìn náà lọ̀ wọ́n. Bí àwọn kan bá gbádùn kíka ìwé ìròyìn náà, sọ wọ́n di ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ, kí o lè máa mú ìtẹ̀jáde tuntun Ilé-Ìṣọ́nà lédè Hausa tọ̀ wọ́n lọ lóṣooṣù, bí ó bá ti jáde.
4 Rántí ohun tí Jesu sọ nípa ọjọ́ wa nínú Marku 13:10 pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, a níláti kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere naa ní gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” Ìyẹn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń sọ èdè Hausa—nǹkan bí 40 mílíọ̀nù. A tí ń tẹ Ilé-Ìṣọ́nà lédè Hausa jáde ní àwọ̀ mèremère nísinsìnyí, gan-an bí i tí àwọn èdè yòókù. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wá lo irin iṣẹ́ àtàtà yìí ní kíkún láti ràn wá lọ́wọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere náà fún gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìpínlẹ̀ tí a yàn fún wa.