Wíwo Ayé
Pílánẹ́ẹ̀tì Ayé Kò Láfiwé
Gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà ṣe sọ, ńṣe làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣáà ń rí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tuntun bí wọ́n ṣe ń wọn ipa tí ó wọ́ kọ́lọkọ̀lọ—tí agbára òòfà pílánẹ́ẹ̀tì fà—bí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ṣe ń yí ìràwọ̀ tó jìnnà réré po. Nígbà tó fi di ọdún 1999, wọ́n sọ pé méjìdínlọ́gbọ̀n irú pílánẹ́ẹ̀tì yẹn ló wà lẹ́yìn òde oòrùn àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀ tó jẹ́ tiwa. Wọ́n sọ pé àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí tóbi bíi Júpítà tàbí kí wọ́n tilẹ̀ tóbi jù ú lọ. Júpítà tóbi ju Ayé lọ ní nǹkan bí ìgbà ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìdínlógún. Bíi ti Júpítà, wọ́n ronú pé gáàsì helium àti hydrogen ló wà nínú àwọn pílánẹ́ẹ̀tì yẹn. Nítorí bí àlàfo ibi tí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì wọ̀nyẹn ń yí po ṣe rí, wọ́n sọ pé ó dà bíi pé kò ṣeé ṣe rárá ni kí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n tóbi bí ayé tún wà pẹ̀lú wọn. Ní àfikún sí i, láìdà bí Ayé yìí tó máa ń yípo gba ibi tó rí róbótó, tó jẹ́ àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù kìlómítà ní fífẹ̀, ṣe làwọn máa ń yí ìràwọ̀ wọn po gba ibi tí ìrísí rẹ̀ rí bíi ti ẹyin. Ní gidi, ipa ọ̀nà kan jìnnà sí ìràwọ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti nǹkan bí ọgọ́ta ó dín méjì mílíọ̀nù kìlómítà sí ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́rìnlélógójì [344] mílíọ̀nù kìlómítà. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan wí pé: “Ó bẹ̀rẹ̀ sì hàn gbangba pé àwọn ipa ọ̀nà róbótó, tí wọ́n wà ní ipò tó ṣe rẹ́gí, irú bó ṣe wà nínú ìgbékalẹ̀ oòrùn àti àwọn ọ̀wọ́ rẹ̀ tó jẹ́ tiwa kò wọ́pọ̀ rárá.”
Fífi Òfé Báni Sọ̀rọ̀
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Times ti London ṣe sọ, wọ́n ti sọ pé kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n jẹ́ ará Sípéènì, tí wọ́n wà ní erékùṣù Gomera, tó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Erékùṣù Canary, máa kọ́ bí wọ́n ṣe ń fi òfé sọ̀rọ̀, èyí tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ń gbé ládùúgbò náà ti lò fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ láti máa fi sọ̀rọ̀ ní àwọn àfonífojì àwọn ilẹ̀ olókè ńlá, silbo, èdè Gomera, tàbí òfé, ń dún bí àwọn sílébù ọ̀rọ̀. Àwọn tó ń súfèé yìí yóò kí ọmọ-ìka wọn bọ ẹnu láti mú kí ìró ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jáde, wọ́n á sì tún tẹ ọwọ́ wọn kòtò bo ẹnu kí ìró yẹn bàa lè lọ dé nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ta. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èdè silbo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa rẹ́ ní ọdún 1960 sí ọdún 1969, ó ti tún gbajúmọ̀ báyìí, wọ́n sì máa ń ṣe àyájọ́ ìsúfèé lọ́dọọdún ní erékùṣù náà nísinsìnyí. Àmọ́, èdè náà ní ààlà. Juan Evaristo, tó jẹ́ olùdarí ètò ẹ̀kọ́ kan ní àdúgbò náà wí pé: “Ẹ lè fi bá ara yín sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ohun tí ẹ lè sọ kò ní pọ̀.”
Àwọn Ọmọdé àti Oorun
Ìwé ìròyìn Parents sọ pé: “Kì í ṣe kìkì pé àwọn òbí gbọ́dọ̀ fi ààlà sí bí àwọn ọmọ tí ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ṣe gbọ́dọ̀ pẹ́ tó kí wọ́n tó lọ sùn lálẹ́ nìkan ni, wọ́n tún gbọ́dọ̀ pinnu ohun tí àwọn ọmọ náà lè ṣe kí wọ́n tó lọ sún. Wíwo tẹlifíṣọ̀n, ṣíṣe eré orí kọ̀ǹpútà àti ti fídíò, àti wíwá ìsọfúnni orí Íńtánẹ́ẹ̀tì kiri jẹ́ ìgbòkègbodò tí ń runi sókè tí kì í jẹ́ kí ọkàn àwọn ọmọdé lélẹ̀ lákòókò. Bí ohun tí àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ilé ẹ̀kọ́ dé bá ti pọ̀ jù, kò ní jẹ́ kí wọ́n parí iṣẹ́ àṣetiléwá wọn lákòókò.” Ìwádìí fi hàn pé bí àwọn ọmọ kéékèèké kò bá sun oorun tí ó tó, ó sábà máa ń ní ipa tó yàtọ̀ lórí wọn—ara wọn kò ní balẹ̀, wọn kò sì ní ṣeé ṣàkóso, nígbà tó sì jẹ́ pé ṣe ni àwọn àgbàlagbà yóò sùn wọra, tí wọ́n á sì ṣe wọ̀ọ̀. Nítorí èyí, bí àwọn ọmọ tí kò sun oorun tí ó tó bá dé ilé ẹ̀kọ́, wọn kì í lè pọkàn pọ̀, wọn kì í fetí sílẹ̀, wọn kì í rántí ohun tí wọ́n bá kọ́, wọn kì í sì lè mọ ojútùú sí ìdánwò ráńpẹ́ tí wọ́n bá gbé fún wọn. Àwọn ògbógi sọ pé ó yẹ kí àwọn òbí sọ àkókò tí àwọn ọmọ wọn yóò máa lọ sùn, kí wọ́n sì rí i pé wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀—kì í ṣe pé kó jẹ́ pé nígbà tí ó bá ti rẹ̀ wọ́n tàbí tí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe bá ti tán ni wọ́n á tó lọ sùn.
Àrùn Éèdì Ti Gbayé Kan
Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti Kánádà sọ nípa ìròyìn kan tó ti ọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè jáde pe jákèjádò ayé, “o ju àádọ́ta mílíọ̀nù èèyàn tí wọ́n ti ní fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn éèdì—tó jẹ́ iye kan náà pẹ̀lú iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì—mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ló sì ti kú. Ìwádìí ní àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-án ní Áfíríkà fi hàn pé ní báyìí, àwọn obìnrin tó ti kó àrùn náà ti fi ìpín ogun nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju àwọn ọkùnrin lọ” àti pé “ó túbọ̀ ṣeé ṣe fún ìlọ́po márùn-ún àwọn ọmọdébìnrin tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba láti kó fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn éèdì ju àwọn ọmọdékùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́langba lọ.” Peter Piot, tó jẹ́ olùdarí àgbà fún Àjọ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Àrùn Éèdì ní Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, ṣàpèjúwe bí ọ̀ràn náà ṣe rí ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù pé “ńṣe ló ń yára gbèèràn.” Ìròyìn náà sọ pé, “bí àwọn èèyàn ṣe ń kó fáírọ́ọ̀sì HIV ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀ rí ti ju ìlọ́po méjì lọ lẹ́nu ọdún méjì sẹ́yìn, òun ló tètè ń gbèèràn jù lọ láyé yìí.” Àwọn ògbógi sọ pé ṣe ló ń fi hàn pé àwọn tó ń fi abẹ́rẹ́ fa oògùn sínú ara wọn ní àgbègbè yẹn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Yíká ayé, èyí tó ju ìdajì lọ lára àwọn tó kó fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn éèdì “ló kó àrùn náà nígbà tí wọ́n jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, wọ́n sì sábà máa ń kú kí wọ́n tó di ẹni ọdún márùndínlógójì.”