ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 6:23-27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Bí ẹ ó ṣe máa súre+ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyí. Kí ẹ sọ fún wọn pé:

      24 “Kí Jèhófà bù kún ọ,+ kó sì pa ọ́ mọ́.

      25 Kí Jèhófà mú kí ojú rẹ̀ tàn sí ọ+ lára, kó sì ṣojúure sí ọ.

      26 Kí Jèhófà bojú wò ọ́, kó sì fún ọ ní àlàáfíà.”’+

      27 Kí wọ́n sì fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí n lè bù kún wọn.”+

  • Diutarónómì 10:8
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 “Ìgbà yẹn ni Jèhófà ya ẹ̀yà Léfì sọ́tọ̀+ kí wọ́n lè máa gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà,+ kí wọ́n sì máa dúró níwájú Jèhófà, kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre,+ bí wọ́n ṣe ń ṣe títí dòní.

  • Diutarónómì 21:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 “Kí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì sì wá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun,+ kí wọ́n sì máa súre ní orúkọ Jèhófà.+ Wọ́n á sọ bí wọ́n á ṣe máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìwà ipá.+

  • 1 Kíróníkà 23:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Àwọn ọmọ Ámúrámù ni Áárónì+ àti Mósè.+ Àmọ́ a ya Áárónì sọ́tọ̀+ láti máa sìn ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ títí lọ, kí òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa rú ẹbọ níwájú Jèhófà, kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún un, kí wọ́n sì máa fi orúkọ rẹ̀ súre fún àwọn èèyàn nígbà gbogbo.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́