ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 4:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 “Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ti bo ibi mímọ́+ náà tán àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ náà nígbà tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra. Kí àwọn ọmọ Kóhátì wá wọlé wá gbé e,+ àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ fara kan ibi mímọ́ kí wọ́n má bàa kú.+ Ojúṣe* àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé nìyí.

  • Nọ́ńbà 4:24-26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 24 Iṣẹ́ tí ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì á máa ṣe àtàwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ nìyí: 25 Kí wọ́n máa gbé aṣọ àgọ́+ ti àgọ́ ìjọsìn, àgọ́ ìpàdé, ìbòrí rẹ̀ àti ìbòrí tí wọ́n fi awọ séálì ṣe tó wà lókè rẹ̀,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé,+ 26 àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá,+ aṣọ* tí wọ́n ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá+ tó yí àgọ́ ìjọsìn àti pẹpẹ ká, àwọn okùn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun èlò wọn pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe nìyí.

  • Nọ́ńbà 4:31-33
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 31 Àwọn ohun tí wọ́n á máa gbé+ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ wọn nínú àgọ́ ìpàdé nìyí: àwọn férémù+ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọ̀pá ìdábùú+ rẹ̀, àwọn òpó+ rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + rẹ̀; 32 àwọn òpó+ àgbàlá tó yí i ká, àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò + wọn, àwọn èèkàn+ àgọ́ wọn àti àwọn okùn àgọ́ wọn pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọn àti gbogbo iṣẹ́ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí. Kí ẹ fi orúkọ yan ohun tí kálúku wọn á máa gbé. 33 Bí ìdílé àwọn ọmọ Mérárì+ á ṣe máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé nìyí, kí Ítámárì ọmọ àlùfáà Áárónì+ máa darí wọn.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́