ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kọ́ríńtì 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Kọ́ríńtì

      • Ẹ̀bùn ti ẹ̀mí (1-11)

      • Ara kan, ẹ̀yà ara púpọ̀ (12-31)

1 Kọ́ríńtì 12:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 14:1

1 Kọ́ríńtì 12:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, aláìgbàgbọ́.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 115:5; Hab 2:18; 1Kọ 8:4; Ga 4:8; 1Tẹ 1:9

1 Kọ́ríńtì 12:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 4:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2007, ojú ìwé 21

1 Kọ́ríńtì 12:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 23

1 Kọ́ríńtì 12:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 23

1 Kọ́ríńtì 12:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀nà ìṣiṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Pe 4:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2011, ojú ìwé 24-25

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 23

1 Kọ́ríńtì 12:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 14:26

1 Kọ́ríńtì 12:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “A fi iṣẹ́ ọgbọ́n rán ẹnì kan.”

1 Kọ́ríńtì 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 13:2
  • +Iṣe 3:5-8; 28:8, 9

1 Kọ́ríńtì 12:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ahọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 2:3, 4
  • +1Jo 4:1
  • +Iṣe 10:45, 46; 1Kọ 14:18
  • +1Kọ 14:26

1 Kọ́ríńtì 12:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 12:4, 5

1 Kọ́ríńtì 12:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “mu.”

1 Kọ́ríńtì 12:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:16

1 Kọ́ríńtì 12:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    8/2020, ojú ìwé 23-24

1 Kọ́ríńtì 12:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    8/2020, ojú ìwé 23-24

1 Kọ́ríńtì 12:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/15/1996, ojú ìwé 20

1 Kọ́ríńtì 12:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2014, ojú ìwé 24

    10/15/1997, ojú ìwé 14-15

1 Kọ́ríńtì 12:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:7, 21

1 Kọ́ríńtì 12:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/1999, ojú ìwé 20

1 Kọ́ríńtì 12:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 12:10; Ga 6:2; Ef 4:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 19

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2007, ojú ìwé 20

    5/15/2004, ojú ìwé 19

1 Kọ́ríńtì 12:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 13:3
  • +Ro 12:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 19

1 Kọ́ríńtì 12:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 1:22, 23
  • +Ro 12:4, 5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/1/1995, ojú ìwé 11

1 Kọ́ríńtì 12:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ahọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 2:20
  • +Iṣe 13:1
  • +Ef 4:11
  • +Ga 3:5
  • +Iṣe 5:16
  • +Heb 13:17
  • +Iṣe 2:6, 7

1 Kọ́ríńtì 12:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “atúmọ̀ èdè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 14:4
  • +1Kọ 14:5

1 Kọ́ríńtì 12:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi ìtara wá ẹ̀bùn tó tóbi jù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 14:1
  • +1Kọ 13:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2009, ojú ìwé 26-27

    2/15/1999, ojú ìwé 22-23

Àwọn míì

1 Kọ́r. 12:11Kọ 14:1
1 Kọ́r. 12:2Sm 115:5; Hab 2:18; 1Kọ 8:4; Ga 4:8; 1Tẹ 1:9
1 Kọ́r. 12:31Jo 4:2, 3
1 Kọ́r. 12:4Ef 4:4
1 Kọ́r. 12:5Ef 4:11
1 Kọ́r. 12:61Pe 4:11
1 Kọ́r. 12:71Kọ 14:26
1 Kọ́r. 12:91Kọ 13:2
1 Kọ́r. 12:9Iṣe 3:5-8; 28:8, 9
1 Kọ́r. 12:10Heb 2:3, 4
1 Kọ́r. 12:101Jo 4:1
1 Kọ́r. 12:10Iṣe 10:45, 46; 1Kọ 14:18
1 Kọ́r. 12:101Kọ 14:26
1 Kọ́r. 12:12Ro 12:4, 5
1 Kọ́r. 12:14Ef 4:16
1 Kọ́r. 12:23Jẹ 3:7, 21
1 Kọ́r. 12:25Ro 12:10; Ga 6:2; Ef 4:25
1 Kọ́r. 12:26Heb 13:3
1 Kọ́r. 12:26Ro 12:15
1 Kọ́r. 12:27Ef 1:22, 23
1 Kọ́r. 12:27Ro 12:4, 5
1 Kọ́r. 12:28Ef 2:20
1 Kọ́r. 12:28Iṣe 13:1
1 Kọ́r. 12:28Ef 4:11
1 Kọ́r. 12:28Ga 3:5
1 Kọ́r. 12:28Iṣe 5:16
1 Kọ́r. 12:28Heb 13:17
1 Kọ́r. 12:28Iṣe 2:6, 7
1 Kọ́r. 12:301Kọ 14:4
1 Kọ́r. 12:301Kọ 14:5
1 Kọ́r. 12:311Kọ 14:1
1 Kọ́r. 12:311Kọ 13:8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Kọ́ríńtì 12:1-31

Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

12 Ní ti àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí,+ ẹ̀yin ará, mi ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ̀ nípa rẹ̀. 2 Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ ṣì jẹ́ èèyàn orílẹ̀-èdè,* wọ́n ń nípa lórí yín, wọ́n ń kó yín ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn òrìṣà tí kò lè sọ̀rọ̀,+ ẹ sì ń ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́. 3 Ní báyìí, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé kò sí ẹni tó bá ń fi ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tó máa sọ pé: “Ẹni ègún ni Jésù!” kò sì sí ẹni tó lè sọ pé: “Jésù ni Olúwa!” àfi nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+

4 Oríṣiríṣi ẹ̀bùn ló wà, àmọ́ ẹ̀mí kan ló wà;+ 5 oríṣiríṣi iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló wà,+ síbẹ̀ Olúwa kan náà ló wà; 6 oríṣiríṣi iṣẹ́* ló wà, síbẹ̀ Ọlọ́run kan náà ló ń ṣe gbogbo iṣẹ́ náà nínú gbogbo èèyàn.+ 7 Àmọ́, à ń fi ẹ̀mí hàn nípasẹ̀ kálukú kí á lè ṣe àwọn míì láǹfààní.+ 8 A fún ẹnì kan ní ọ̀rọ̀ ọgbọ́n* nípasẹ̀ ẹ̀mí, a fún ẹlòmíì ní ọ̀rọ̀ ìmọ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, 9 a fún òmíì ní ìgbàgbọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, a fún òmíì ní àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn+ nípasẹ̀ ẹ̀mí kan náà, 10 síbẹ̀, a fún òmíì ní ẹ̀bùn láti máa ṣe àwọn iṣẹ́ agbára,+ a fún òmíì ní ìsọtẹ́lẹ̀, a fún òmíì ní òye àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí,+ a fún òmíì ní ẹ̀bùn oríṣiríṣi èdè,*+ a sì fún òmíì ní ìtúmọ̀ àwọn èdè.+ 11 Àmọ́ gbogbo iṣẹ́ yìí ni ẹ̀mí kan náà yìí ń ṣe, ó ń pín ẹ̀bùn fún kálukú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́.

12 Nítorí bí ara ṣe jẹ́ ọ̀kan àmọ́ tó ní ẹ̀yà púpọ̀, tí gbogbo ẹ̀yà ara yẹn sì jẹ́ ara kan+ bí wọ́n tilẹ̀ pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Kristi. 13 Nítorí ipasẹ̀ ẹ̀mí kan ni a batisí gbogbo wa sínú ara kan, ì báà jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì, ẹrú tàbí òmìnira, a sì mú kí gbogbo wa gba* ẹ̀mí kan.

14 Ní tòótọ́, kì í ṣe ẹ̀yà ara kan ṣoṣo ló dá di ara, ẹ̀yà ara púpọ̀ ni.+ 15 Tí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. 16 Tí etí bá sì sọ pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” ìyẹn ò sọ pé kì í ṣe apá kan ara. 17 Tí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, ibo ni agbára ìgbọ́ràn máa wà? Tí gbogbo rẹ̀ bá jẹ́ ìgbọ́ràn, ibo ni agbára ìgbóòórùn máa wà? 18 Àmọ́ ní báyìí, Ọlọ́run ti to ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bí ó ṣe fẹ́ sínú ara.

19 Tí gbogbo wọn bá jẹ́ ẹ̀yà ara kan náà, ibo ni ara máa wà? 20 Àmọ́ ní báyìí bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà ara púpọ̀, ara kan ṣoṣo ni wọ́n. 21 Ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Mi ò nílò rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Mi ò nílò rẹ.” 22 Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀yà ara tó dà bíi pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ṣe pàtàkì, 23 àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá ni à ń bọlá fún jù,+ nípa bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara wa tí kò jọni lójú ni à ń yẹ́ sí jù lọ, 24 nígbà tó jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà ara wa tó fani mọ́ra kò nílò ohunkóhun. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣètò ara, ó fún àwọn ẹ̀yà ara tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára ní ọlá tó pọ̀ jù, 25 kó má bàa sí ìpínyà kankan nínú ara, àmọ́ kí àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣìkẹ́ ara wọn.+ 26 Tí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo ẹ̀yà ara tó kù á bá a jìyà;+ tí a bá sì ṣe ẹ̀yà ara kan lógo, gbogbo ẹ̀yà ara yòókù á bá a yọ̀.+

27 Ní báyìí, ẹ̀yin jẹ́ ara Kristi,+ kálukú yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara.+ 28 Ọlọ́run ti yan ẹnì kọ̀ọ̀kan sínú ìjọ: èkíní, àwọn àpọ́sítélì;+ èkejì, àwọn wòlíì;+ ẹ̀kẹta, àwọn olùkọ́;+ lẹ́yìn náà, àwọn iṣẹ́ agbára;+ lẹ́yìn náà, àwọn ẹ̀bùn ìwòsàn;+ àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́; àwọn agbára láti máa darí+ àti oríṣiríṣi èdè.*+ 29 Kì í ṣe gbogbo wọn ni àpọ́sítélì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni wòlíì, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ni olùkọ́, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ló ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára, àbí gbogbo wọn ni? 30 Kì í ṣe gbogbo wọn ló ní ẹ̀bùn ìwonisàn, àbí gbogbo wọn ni? Kì í ṣe gbogbo wọn ló ń fi èdè fọ̀, àbí gbogbo wọn ni?+ Kì í ṣe gbogbo wọn ló jẹ́ olùtúmọ̀,* àbí gbogbo wọn ni?+ 31 Àmọ́ ẹ máa wá ẹ̀bùn tó tóbi jù.*+ Síbẹ̀, màá fi ọ̀nà tó ta yọ hàn yín.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́