ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

      • Jésù fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ (1-20)

      • Jésù fi hàn pé Júdásì ló máa da òun (21-30)

      • Àṣẹ tuntun (31-35)

        • “Tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín” (35)

      • Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun (36-38)

Jòhánù 13:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:2; Jo 12:23; 17:1
  • +Jo 16:28; 17:11
  • +Jo 15:9; Ef 5:2; 1Jo 3:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 161-162

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1992, ojú ìwé 17

Jòhánù 13:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 22:3, 4; Jo 13:27
  • +Mt 26:14-16, 24; Mk 14:10, 11

Jòhánù 13:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 16:28

Jòhánù 13:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “di ara rẹ̀ lámùrè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 2:5-7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 30-31

Jòhánù 13:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó fi di ara rẹ̀ lámùrè.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 268

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2009, ojú ìwé 19

    3/1/1999, ojú ìwé 30-31

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 32, 33-34

    Olùkọ́, ojú ìwé 38-39

Jòhánù 13:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 6:11; Ef 5:25, 26; Tit 3:5; Heb 10:22

Jòhánù 13:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 6:64

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 8/2016,

Jòhánù 13:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”

Jòhánù 13:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 23:8

Jòhánù 13:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó di dandan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 22:27
  • +Mt 20:26, 27; Lk 9:48; 22:26; Ro 12:10; 1Pe 5:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 268-269

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2003, ojú ìwé 4-5

    2/1/2002, ojú ìwé 15

    3/1/1999, ojú ìwé 30-31

    Olùkọ́, ojú ìwé 38-39

Jòhánù 13:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 2:5; 1Pe 2:21; 1Jo 2:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2005, ojú ìwé 7

    3/1/1999, ojú ìwé 30-31

    9/15/1994, ojú ìwé 15-16

Jòhánù 13:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 7:24, 25; Lk 11:28; Jem 1:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2018, ojú ìwé 4

Jòhánù 13:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ti yíjú pa dà sí mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 17:12
  • +Sm 41:9; Mt 26:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 270

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2011, ojú ìwé 13

Jòhánù 13:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:29; 16:4

Jòhánù 13:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 25:40
  • +Mt 10:40

Jòhánù 13:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:21; Mk 14:18; Lk 22:21; Jo 6:70

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 270

Jòhánù 13:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:22; Lk 22:23

Jòhánù 13:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “rọ̀gbọ̀kú.”

  • *

    Ní Grk., “ní oókan àyà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:26; 20:2

Jòhánù 13:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 21:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2015, ojú ìwé 15

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 270

Jòhánù 13:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:23

Jòhánù 13:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 22:3, 4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 270

Jòhánù 13:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 12:4-6

Jòhánù 13:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:20

Jòhánù 13:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 12:23

Jòhánù 13:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 17:1

Jòhánù 13:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:34; 8:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2003, ojú ìwé 13

Jòhánù 13:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 15:9
  • +Le 19:18; Jo 15:12; 1Tẹ 4:9; Jem 2:8; 1Pe 1:22; 1Jo 3:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 18

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 301

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2013, ojú ìwé 10-11

    3/1/2012, ojú ìwé 6

    11/15/2009, ojú ìwé 20

    10/1/2007, ojú ìwé 5-6

    3/1/2006, ojú ìwé 5

    3/15/2003, ojú ìwé 5-6

    2/1/2002, ojú ìwé 15-16

    3/15/1996, ojú ìwé 8-9

    3/1/1992, ojú ìwé 17-18

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 176-177

Jòhánù 13:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 13:8; 1Kọ 13:8, 13; 1Jo 4:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 18

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 301

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2009, ojú ìwé 20

    6/1/2009, ojú ìwé 14

    3/1/2006, ojú ìwé 5

    3/15/2003, ojú ìwé 5-6

    2/1/2003, ojú ìwé 13-14

    2/15/1999, ojú ìwé 22

    8/1/1997, ojú ìwé 16

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 176-177

    Yiyan, ojú ìwé 8-9

Jòhánù 13:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:3

Jòhánù 13:37

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:33; Mk 14:29; Lk 22:33

Jòhánù 13:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:34; Mk 14:30; Lk 22:34; Jo 18:27

Àwọn míì

Jòh. 13:1Mt 26:2; Jo 12:23; 17:1
Jòh. 13:1Jo 16:28; 17:11
Jòh. 13:1Jo 15:9; Ef 5:2; 1Jo 3:16
Jòh. 13:2Lk 22:3, 4; Jo 13:27
Jòh. 13:2Mt 26:14-16, 24; Mk 14:10, 11
Jòh. 13:3Jo 16:28
Jòh. 13:4Flp 2:5-7
Jòh. 13:81Kọ 6:11; Ef 5:25, 26; Tit 3:5; Heb 10:22
Jòh. 13:11Jo 6:64
Jòh. 13:13Mt 23:8
Jòh. 13:14Lk 22:27
Jòh. 13:14Mt 20:26, 27; Lk 9:48; 22:26; Ro 12:10; 1Pe 5:5
Jòh. 13:15Flp 2:5; 1Pe 2:21; 1Jo 2:6
Jòh. 13:17Mt 7:24, 25; Lk 11:28; Jem 1:25
Jòh. 13:18Jo 17:12
Jòh. 13:18Sm 41:9; Mt 26:23
Jòh. 13:19Jo 14:29; 16:4
Jòh. 13:20Mt 25:40
Jòh. 13:20Mt 10:40
Jòh. 13:21Mt 26:21; Mk 14:18; Lk 22:21; Jo 6:70
Jòh. 13:22Mt 26:22; Lk 22:23
Jòh. 13:23Jo 19:26; 20:2
Jòh. 13:25Jo 21:20
Jòh. 13:26Mt 26:23
Jòh. 13:27Lk 22:3, 4
Jòh. 13:29Jo 12:4-6
Jòh. 13:30Mt 26:20
Jòh. 13:31Jo 12:23
Jòh. 13:32Jo 17:1
Jòh. 13:33Jo 7:34; 8:21
Jòh. 13:34Jo 15:9
Jòh. 13:34Le 19:18; Jo 15:12; 1Tẹ 4:9; Jem 2:8; 1Pe 1:22; 1Jo 3:14
Jòh. 13:35Ro 13:8; 1Kọ 13:8, 13; 1Jo 4:20
Jòh. 13:36Jo 14:3
Jòh. 13:37Mt 26:33; Mk 14:29; Lk 22:33
Jòh. 13:38Mt 26:34; Mk 14:30; Lk 22:34; Jo 18:27
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù 13:1-38

Àkọsílẹ̀ Jòhánù

13 Torí pé Jésù ti mọ̀ ṣáájú àjọyọ̀ Ìrékọjá pé wákàtí òun ti tó+ láti kúrò ní ayé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba,+ ó nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tó wà ní ayé, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.+ 2 Wọ́n ń jẹ oúnjẹ alẹ́ lọ́wọ́, Èṣù sì ti fi sínú ọkàn Júdásì Ìsìkáríọ́tù,+ ọmọ Símónì, pé kó dà á.+ 3 Jésù mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́ àti pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òun sì ń lọ,+ 4 torí náà, ó dìde nídìí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Ó wá mú aṣọ ìnura, ó sì so ó mọ́ ìbàdí.*+ 5 Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú bàsíà kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì ń fi aṣọ ìnura tó so mọ́ ìbàdí* nù ún gbẹ. 6 Ó wá dé ọ̀dọ̀ Símónì Pétérù. Ó bi í pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi ni?” 7 Jésù dá a lóhùn pé: “Ohun tí mò ń ṣe ò tíì yé ọ báyìí, àmọ́ lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, ó máa yé ọ.” 8 Pétérù sọ fún un pé: “O ò ní fọ ẹsẹ̀ mi láéláé.” Jésù dá a lóhùn pé: “Láìjẹ́ pé mo fọ ẹsẹ̀ rẹ,+ o ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ mi.” 9 Símónì Pétérù bá sọ fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan lo máa fọ̀, tún fọ ọwọ́ mi àti orí mi.” 10 Jésù sọ fún un pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti wẹ̀, kò nílò ju ká fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, torí ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin mọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo yín.” 11 Torí ó mọ ẹni tó máa da òun.+ Ìdí nìyí tó fi sọ pé: “Kì í ṣe gbogbo yín lẹ mọ́.”

12 Lẹ́yìn tó fọ ẹsẹ̀ wọn tán, tó sì wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, ó pa dà jókòó* sídìí tábìlì, ó sì sọ fún wọn pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? 13 Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn.+ 14 Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín,+ ó yẹ* kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín.+ 15 Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe.+ 16 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, ẹni tí a rán jáde kò sì tóbi ju ẹni tó rán an. 17 Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.+ 18 Gbogbo yín kọ́ ni mò ń bá wí; mo mọ àwọn tí mo ti yàn. Àmọ́ èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ+ pé: ‘Ẹni tí a jọ ń jẹun ti jìn mí lẹ́sẹ̀.’*+ 19 Láti ìsinsìnyí lọ, mò ń sọ fún yín kó tó ṣẹlẹ̀, kó lè jẹ́ pé tó bá ṣẹlẹ̀, ẹ máa lè gbà gbọ́ pé èmi ni ẹni náà.+ 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tó bá gba ẹni yòówù tí mo rán gba èmi náà,+ ẹnikẹ́ni tó bá sì gbà mí gba Ẹni tó rán mi pẹ̀lú.”+

21 Lẹ́yìn tí Jésù sọ àwọn nǹkan yìí, ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ẹ̀mí, ó sì jẹ́rìí, ó sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ọ̀kan nínú yín máa dà mí.”+ 22 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá bẹ̀rẹ̀ sí í wo ara wọn, torí ọ̀rọ̀ náà rú wọn lójú, wọn ò mọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.+ 23 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ẹni tí Jésù nífẹ̀ẹ́,+ jókòó* sí tòsí* Jésù. 24 Torí náà, Símónì Pétérù mi orí sí ẹni yìí, ó sì sọ fún un pé: “Sọ ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ fún wa.” 25 Ẹni yẹn wá fẹ̀yìn ti àyà Jésù, ó sì bi í pé: “Olúwa, ta ni?”+ 26 Jésù dáhùn pé: “Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì tí mo kì bọ inú abọ́ ni.”+ Torí náà, lẹ́yìn tó ki búrẹ́dì bọ inú abọ́, ó mú un fún Júdásì, ọmọ Símónì Ìsìkáríọ́tù. 27 Lẹ́yìn tí Júdásì gba búrẹ́dì náà, Sátánì wọ inú Júdásì.+ Torí náà, Jésù sọ fún un pé: “Tètè ṣe ohun tí ò ń ṣe kíákíá.” 28 Àmọ́ ìkankan nínú àwọn tó jókòó sídìí tábìlì ò mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀ fún un. 29 Àwọn kan tiẹ̀ ń rò pé torí pé ọwọ́ Júdásì ni àpótí owó wà,+ ṣe ni Jésù ń sọ fún un pé, “Ra àwọn nǹkan tí a máa fi ṣe àjọyọ̀ náà” tàbí pé kó fún àwọn aláìní ní nǹkan. 30 Torí náà, lẹ́yìn tó gba búrẹ́dì náà, ó jáde lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ilẹ̀ sì ti ṣú.+

31 Torí náà, lẹ́yìn tó jáde, Jésù sọ pé: “Ní báyìí, a ṣe Ọmọ èèyàn lógo,+ a sì tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe Ọlọ́run lógo. 32 Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa ṣe é lógo,+ ó sì máa ṣe é lógo lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 33 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ìgbà díẹ̀ sí i ni màá fi wà pẹ̀lú yín. Ẹ máa wá mi; bí mo sì ṣe sọ fún àwọn Júù pé, ‘Ẹ ò lè wá sí ibi tí mò ń lọ,’+ mò ń sọ fún ẹ̀yin náà báyìí. 34 Mò ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín; bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín,+ kí ẹ̀yin náà nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 35 Èyí ni gbogbo èèyàn máa fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, tí ìfẹ́ bá wà láàárín yín.”+

36 Símónì Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, ibo lò ń lọ?” Jésù dáhùn pé: “O ò lè tẹ̀ lé mi lọ síbi tí mò ń lọ báyìí, àmọ́ o máa tẹ̀ lé mi tó bá yá.”+ 37 Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, kí ló dé tí mi ò lè tẹ̀ lé ọ báyìí? Màá fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí rẹ.”+ 38 Jésù dáhùn pé: “Ṣé o máa fi ẹ̀mí* rẹ lélẹ̀ nítorí mi? Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ, ó dájú pé àkùkọ ò ní kọ tí wàá fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́