ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Hẹsikáyà di ọba Júdà (1-8)

      • Bí wọ́n ṣe ṣẹ́gun Ísírẹ́lì (9-12)

      • Senakérúbù wá gbéjà ko Júdà (13-18)

      • Rábúṣákè pẹ̀gàn Jèhófà (19-37)

2 Àwọn Ọba 18:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 15:30; 17:1
  • +2Kr 28:27; Mt 1:9
  • +2Ọb 16:2, 20

2 Àwọn Ọba 18:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìkékúrú orúkọ Ábíjà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 29:1, 2

2 Àwọn Ọba 18:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:3; 2Kr 31:20, 21; Sm 119:128
  • +1Ọb 15:5

2 Àwọn Ọba 18:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “Néhúṣítánì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:52; 1Ọb 3:2; 2Ọb 14:1, 4
  • +Di 7:5; 12:3; 2Kr 31:1
  • +Nọ 21:8, 9

2 Àwọn Ọba 18:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:15; 2Kr 32:7, 8

2 Àwọn Ọba 18:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:20; Joṣ 23:8

2 Àwọn Ọba 18:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 16:7

2 Àwọn Ọba 18:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ní ibi gbogbo, ì báà jẹ́ ibi tí èèyàn kéréje ń gbé tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 28:18, 19; Ais 14:28, 29

2 Àwọn Ọba 18:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:1
  • +2Ọb 17:3-6

2 Àwọn Ọba 18:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 13:16; Emọ 3:11; Mik 1:6

2 Àwọn Ọba 18:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:4; Emọ 6:1, 7
  • +2Ọb 17:6; 1Kr 5:26

2 Àwọn Ọba 18:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:20; 1Ọb 14:15

2 Àwọn Ọba 18:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 10:5
  • +2Kr 32:1; Ais 36:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 14-15

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1993, ojú ìwé 5-6

2 Àwọn Ọba 18:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tálẹ́ńtì kan jẹ́ kìlógíráàmù 34.2. Wo Àfikún B14.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 383-385

    Ìwé fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 14-15

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1993, ojú ìwé 5-6

2 Àwọn Ọba 18:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 12:18; 16:8; 2Kr 16:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1993, ojú ìwé 6

2 Àwọn Ọba 18:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 6:33-35
  • +2Kr 29:1, 3

2 Àwọn Ọba 18:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “olórí ọmọ ogun.”

  • *

    Tàbí “olórí àwọn òṣìṣẹ́ láàfin.”

  • *

    Tàbí “olórí agbọ́tí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:20, 39; 2Kr 11:5, 9
  • +2Kr 32:9
  • +Ais 36:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 386

2 Àwọn Ọba 18:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:2; Ais 22:20-24
  • +Ais 22:15-19

2 Àwọn Ọba 18:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:10; Ais 36:4-10

2 Àwọn Ọba 18:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:7

2 Àwọn Ọba 18:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, koríko etí omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2010, ojú ìwé 12-13

    8/1/2005, ojú ìwé 11

2 Àwọn Ọba 18:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:8
  • +2Kr 31:1
  • +Di 12:11, 13; 2Kr 32:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2010, ojú ìwé 13

2 Àwọn Ọba 18:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 10:12, 13

2 Àwọn Ọba 18:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Síríà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:18
  • +2Ọb 18:17
  • +Ẹsr 4:7; Da 2:4
  • +Ais 36:11, 12

2 Àwọn Ọba 18:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 36:13-20

2 Àwọn Ọba 18:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:15

2 Àwọn Ọba 18:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:32-34

2 Àwọn Ọba 18:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ wá ìbùkún lọ́dọ̀ mi, kí ẹ sì jáde wá bá mi.”

2 Àwọn Ọba 18:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:6

2 Àwọn Ọba 18:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:21
  • +2Ọb 17:24
  • +2Ọb 17:6

2 Àwọn Ọba 18:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 19:17-19; 2Kr 32:15; Ais 37:23

2 Àwọn Ọba 18:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 36:21, 22

2 Àwọn Ọba 18:37

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Àwọn míì

2 Ọba 18:12Ọb 15:30; 17:1
2 Ọba 18:12Kr 28:27; Mt 1:9
2 Ọba 18:12Ọb 16:2, 20
2 Ọba 18:22Kr 29:1, 2
2 Ọba 18:32Ọb 20:3; 2Kr 31:20, 21; Sm 119:128
2 Ọba 18:31Ọb 15:5
2 Ọba 18:4Nọ 33:52; 1Ọb 3:2; 2Ọb 14:1, 4
2 Ọba 18:4Di 7:5; 12:3; 2Kr 31:1
2 Ọba 18:4Nọ 21:8, 9
2 Ọba 18:52Ọb 19:15; 2Kr 32:7, 8
2 Ọba 18:6Di 10:20; Joṣ 23:8
2 Ọba 18:72Ọb 16:7
2 Ọba 18:82Kr 28:18, 19; Ais 14:28, 29
2 Ọba 18:92Ọb 17:1
2 Ọba 18:92Ọb 17:3-6
2 Ọba 18:10Ho 13:16; Emọ 3:11; Mik 1:6
2 Ọba 18:11Ais 8:4; Emọ 6:1, 7
2 Ọba 18:112Ọb 17:6; 1Kr 5:26
2 Ọba 18:12Di 8:20; 1Ọb 14:15
2 Ọba 18:13Ais 10:5
2 Ọba 18:132Kr 32:1; Ais 36:1
2 Ọba 18:152Ọb 12:18; 16:8; 2Kr 16:2, 3
2 Ọba 18:161Ọb 6:33-35
2 Ọba 18:162Kr 29:1, 3
2 Ọba 18:17Joṣ 15:20, 39; 2Kr 11:5, 9
2 Ọba 18:172Kr 32:9
2 Ọba 18:17Ais 36:2, 3
2 Ọba 18:182Ọb 19:2; Ais 22:20-24
2 Ọba 18:18Ais 22:15-19
2 Ọba 18:192Kr 32:10; Ais 36:4-10
2 Ọba 18:202Ọb 18:7
2 Ọba 18:21Ais 30:1, 2
2 Ọba 18:222Kr 32:8
2 Ọba 18:222Kr 31:1
2 Ọba 18:22Di 12:11, 13; 2Kr 32:12
2 Ọba 18:23Ais 10:12, 13
2 Ọba 18:262Ọb 18:18
2 Ọba 18:262Ọb 18:17
2 Ọba 18:26Ẹsr 4:7; Da 2:4
2 Ọba 18:26Ais 36:11, 12
2 Ọba 18:28Ais 36:13-20
2 Ọba 18:292Kr 32:15
2 Ọba 18:302Ọb 19:32-34
2 Ọba 18:322Ọb 17:6
2 Ọba 18:34Nọ 13:21
2 Ọba 18:342Ọb 17:24
2 Ọba 18:342Ọb 17:6
2 Ọba 18:352Ọb 19:17-19; 2Kr 32:15; Ais 37:23
2 Ọba 18:36Ais 36:21, 22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 18:1-37

Àwọn Ọba Kejì

18 Ní ọdún kẹta Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Hẹsikáyà+ ọmọ Áhásì+ ọba Júdà di ọba. 2 Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni nígbà tó jọba, ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Ábì* ọmọ Sekaráyà.+ 3 Ó ń ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà+ bí Dáfídì baba ńlá rẹ̀ ti ṣe.+ 4 Òun ló mú àwọn ibi gíga kúrò,+ tó fọ́ àwọn ọwọ̀n òrìṣà sí wẹ́wẹ́, tó sì gé òpó òrìṣà*+ lulẹ̀. Ó tún fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe;+ torí pé títí di àkókò yẹn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń mú ẹbọ rú èéfín sí i, tí wọ́n sì ń pè é ní òrìṣà ejò bàbà.* 5 Ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì; kò sí ẹnì kankan tó dà bíi rẹ̀ nínú gbogbo àwọn ọba Júdà tó wà ṣáájú rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jẹ lẹ́yìn rẹ̀. 6 Kò fi Jèhófà sílẹ̀.+ Kò yà kúrò lẹ́yìn rẹ̀; ó ń pa àwọn àṣẹ tí Jèhófà fún Mósè mọ́. 7 Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ó ń hùwà ọgbọ́n níbikíbi tó bá lọ. Ó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà, ó sì kọ̀ láti sìn ín.+ 8 Ó tún ṣẹ́gun àwọn Filísínì+ títí dé Gásà àti àwọn ìpínlẹ̀ rẹ̀, láti ilé ìṣọ́ títí dé ìlú olódi.*

9 Ní ọdún kẹrin Ọba Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún keje Hóṣéà+ ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì, Ṣálímánésà ọba Ásíríà wá gbéjà ko Samáríà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dó tì í.+ 10 Wọ́n gbà á+ ní òpin ọdún mẹ́ta; ní ọdún kẹfà Hẹsikáyà, ìyẹn ní ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì, wọ́n gba Samáríà. 11 Lẹ́yìn ìyẹn, ọba Ásíríà kó Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn+ ní Ásíríà, ó sì ní kí wọ́n máa gbé ní Hálà àti ní Hábórì níbi odò Gósánì àti ní àwọn ìlú àwọn ará Mídíà.+ 12 Ohun tó fa èyí ni pé wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn, wọ́n ń da májẹ̀mú rẹ̀, ìyẹn gbogbo ohun tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà pa láṣẹ.+ Wọn ò fetí sílẹ̀, wọn ò sì ṣègbọràn.

13 Ní ọdún kẹrìnlá Ọba Hẹsikáyà, Senakérúbù ọba Ásíríà+ wá gbéjà ko gbogbo ìlú olódi Júdà, ó sì gbà wọ́n.+ 14 Nítorí náà, Hẹsikáyà ọba Júdà ránṣẹ́ sí ọba Ásíríà ní Lákíṣì pé: “Èmi ni mo jẹ̀bi. Má ṣe bá mi jà mọ́, ohunkóhun tí o bá ní kí n san ni màá san.” Ni ọba Ásíríà bá bu ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì* fàdákà àti ọgbọ̀n (30) tálẹ́ńtì wúrà lé Hẹsikáyà ọba Júdà. 15 Torí náà, Hẹsikáyà fi gbogbo fàdákà tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà àti ní àwọn ibi ìṣúra ilé* ọba+ lélẹ̀. 16 Lákòókò yẹn, Hẹsikáyà yọ* àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì+ Jèhófà kúrò àti àwọn òpó ilẹ̀kùn tí Hẹsikáyà ọba Júdà fúnra rẹ̀ fi wúrà bò,+ ó sì kó wọn fún ọba Ásíríà.

17 Ọba Ásíríà wá rán àwọn mẹ́ta tí orúkọ oyè wọn ń jẹ́ Tátánì* àti Rábúsárísì* àti Rábúṣákè* pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun láti Lákíṣì+ sí Ọba Hẹsikáyà ní Jerúsálẹ́mù.+ Wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì dúró síbi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà, èyí tó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀.+ 18 Nígbà tí wọ́n pe ọba pé kó jáde, Élíákímù+ ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà+ akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí jáde wá bá wọn.

19 Torí náà, Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún Hẹsikáyà pé, ‘Ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ nìyí: “Kí lo gbọ́kàn lé?+ 20 Ò ń sọ pé, ‘Mo ní ọgbọ́n àti agbára láti jagun,’ àmọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu lásán nìyẹn. Ta lo gbẹ́kẹ̀ lé, tí o fi gbójúgbóyà ṣọ̀tẹ̀ sí mi?+ 21 Wò ó! Ṣé Íjíbítì+ tó dà bí esùsú* fífọ́ yìí lo gbẹ́kẹ̀ lé, tó jẹ́ pé bí èèyàn bá fara tì í, ṣe ló máa wọ àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, tí á sì gún un yọ? Bí Fáráò ọba Íjíbítì ṣe rí nìyẹn sí gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e. 22 Tí ẹ bá sì sọ fún mi pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run wa ni a gbẹ́kẹ̀ lé,’+ ṣé òun kọ́ ni Hẹsikáyà mú àwọn ibi gíga rẹ̀ àti àwọn pẹpẹ rẹ̀ kúrò,+ tó sì sọ fún Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé, ‘Iwájú pẹpẹ tó wà ní Jerúsálẹ́mù yìí ni kí ẹ ti máa forí balẹ̀’?”’+ 23 Ní báyìí, ẹ wò ó, olúwa mi ọba Ásíríà pè yín níjà: Ẹ jẹ́ kí n fún yín ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin, ká wá wò ó bóyá ẹ máa lè rí àwọn agẹṣin tó máa gùn wọ́n.+ 24 Báwo wá ni ẹ ṣe lè borí gómìnà kan ṣoṣo tó kéré jù lára àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, nígbà tó jẹ́ pé Íjíbítì lẹ gbẹ́kẹ̀ lé pé ó máa fún yín ní àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn agẹṣin? 25 Ṣé láìgba àṣẹ lọ́wọ́ Jèhófà ni mo wá gbéjà ko ibí yìí láti pa á run ni? Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ fún mi pé, ‘Lọ gbéjà ko ilẹ̀ yìí, kí o sì pa á run.’”

26 Ni Élíákímù ọmọ Hilikáyà àti Ṣẹ́bínà+ pẹ̀lú Jóà bá sọ fún Rábúṣákè+ pé: “Jọ̀ọ́, bá àwa ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Árámáíkì*+ torí a gbọ́ èdè náà; má fi èdè àwọn Júù bá wa sọ̀rọ̀ lójú àwọn èèyàn tó wà lórí ògiri.”+ 27 Ṣùgbọ́n Rábúṣákè sọ fún wọn pé: “Ṣé ẹ̀yin àti olúwa yín nìkan ni olúwa mi ní kí n sọ ọ̀rọ̀ yìí fún ni? Ṣé kò tún rán mi sí àwọn ọkùnrin tó ń jókòó lórí ògiri, àwọn tó máa jẹ ìgbẹ́ ara wọn, tí wọ́n sì máa mu ìtọ̀ ara wọn pẹ̀lú yín?”

28 Rábúṣákè bá dìde, ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì fi èdè àwọn Júù sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásíríà.+ 29 Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Ẹ má ṣe jẹ́ kí Hẹsikáyà tàn yín jẹ, nítorí kò lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi.+ 30 Ẹ má sì jẹ́ kí Hẹsikáyà mú kí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bó ṣe ń sọ pé: “Ó dájú pé Jèhófà máa gbà wá, a ò sì ní fi ìlú yìí lé ọba Ásíríà lọ́wọ́.”+ 31 Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, torí ohun tí ọba Ásíríà sọ nìyí: “Ẹ bá mi ṣe àdéhùn àlàáfíà, kí ẹ sì túúbá,* kálukú yín á máa jẹ látinú àjàrà rẹ̀ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, á sì máa mu omi látinú kòtò omi rẹ̀, 32 títí màá fi wá kó yín lọ sí ilẹ̀ tó dà bí ilẹ̀ yín,+ ilẹ̀ ọkà àti ti wáìnì tuntun, ilẹ̀ oúnjẹ àti ti àwọn ọgbà àjàrà, ilẹ̀ àwọn igi ólífì àti ti oyin. Kí ẹ lè máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ má sì kú. Ẹ má fetí sí Hẹsikáyà, nítorí ṣe ló ń ṣì yín lọ́nà bó ṣe ń sọ pé, ‘Jèhófà máa gbà wá.’ 33 Ǹjẹ́ ìkankan lára ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ ọba Ásíríà? 34 Ibo ni àwọn ọlọ́run Hámátì+ àti ti Áápádì wà? Ibo ni àwọn ọlọ́run Séfáfáímù,+ Hénà àti ti Ífà wà? Ǹjẹ́ wọ́n gba Samáríà kúrò lọ́wọ́ mi?+ 35 Èwo nínú gbogbo ọlọ́run àwọn ilẹ̀ náà ló ti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi, tí Jèhófà yóò fi gba Jerúsálẹ́mù kúrò lọ́wọ́ mi?”’”+

36 Àmọ́ àwọn èèyàn náà dákẹ́, wọn ò fún un lésì kankan, nítorí àṣẹ ọba ni pé, “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dá a lóhùn.”+ 37 Ṣùgbọ́n Élíákímù ọmọ Hilikáyà, ẹni tó ń bójú tó agbo ilé* àti Ṣẹ́bínà akọ̀wé pẹ̀lú Jóà ọmọ Ásáfù akọ̀wé ìrántí wá sọ́dọ̀ Hẹsikáyà, pẹ̀lú ẹ̀wù yíya lọ́rùn wọn, wọ́n sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ Rábúṣákè fún un.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́