Jóṣúà
19 Kèké kejì+ wá mú Síméónì, ẹ̀yà Síméónì+ ní ìdílé-ìdílé. Ogún wọn sì wà láàárín ogún Júdà.+ 2 Ogún wọn ni Bíá-ṣébà,+ pẹ̀lú Ṣébà, Móládà,+ 3 Hasari-ṣúálì,+ Bálà, Ésémù,+ 4 Élítóládì,+ Bẹ́túlì, Hóómà, 5 Síkílágì,+ Bẹti-mákábótì, Hasari-súsà, 6 Bẹti-lébáótì+ àti Ṣárúhénì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́tàlá (13), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn; 7 Áyínì, Rímónì, Étérì àti Áṣánì,+ ó jẹ́ ìlú mẹ́rin pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn; 8 àti gbogbo ìgbèríko tó yí àwọn ìlú yìí ká títí dé Baalati-bíà, ìyẹn Rámà tó wà ní gúúsù. Èyí ni ogún ẹ̀yà Síméónì ní ìdílé-ìdílé. 9 Inú ìpín Júdà ni wọ́n ti mú ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì, torí pé ìpín Júdà ti pọ̀ jù fún wọn. Torí náà, àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì gba ohun ìní tiwọn láàárín ogún wọn.+
10 Lẹ́yìn náà, kèké kẹta+ mú àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì+ ní ìdílé-ìdílé, ààlà ogún wọn sì lọ títí dé Sárídì. 11 Ààlà wọn lọ sápá òkè ní ìwọ̀ oòrùn sí Márálà, ó dé Dábéṣétì, ó sì lọ sí àfonífojì tó wà níwájú Jókínéámù. 12 Ó lọ láti Sárídì sápá ìlà oòrùn níbi tí oòrùn ti ń yọ dé ààlà Kisiloti-tábórì, ó dé Dábérátì,+ ó sì tún dé Jáfíà. 13 Ó lọ látibẹ̀ sápá ìlà oòrùn níbi tí oòrùn ti ń yọ dé Gati-héférì,+ ó dé Ẹti-kásínì, ó sì tún dé Rímónì, títí lọ dé Néà. 14 Ààlà náà yí i ká ní àríwá, ó dé Hánátónì, ó sì parí sí Àfonífojì Ifita-élì, 15 àti Kátátì, Náhálálì, Ṣímúrónì,+ Ídálà àti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú méjìlá (12), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 16 Èyí ni ogún àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì ní ìdílé-ìdílé.+ Èyí sì ni àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
17 Kèké kẹrin+ mú Ísákà,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà ní ìdílé-ìdílé. 18 Ààlà wọn dé Jésírẹ́lì,+ Kẹ́súlótì, Ṣúnémù,+ 19 Háfáráímù, Ṣíónì, Ánáhárátì, 20 Rábítì, Kíṣíónì, Ébésì, 21 Rémétì, Ẹ́ń-gánímù,+ Ẹ́ń-hádà àti Bẹti-pásésì. 22 Ààlà náà sì dé Tábórì,+ Ṣáhásúmà àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì, ààlà wọn wá parí sí Jọ́dánì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún (16) pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 23 Èyí ni ogún ẹ̀yà Ísákà ní ìdílé-ìdílé,+ àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
24 Lẹ́yìn náà, kèké karùn-ún+ mú ẹ̀yà Áṣérì+ ní ìdílé-ìdílé. 25 Ààlà wọn sì ni Hélíkátì,+ Hálì, Béténì, Ákíṣáfù, 26 Alamélékì, Ámádì àti Míṣálì. Ó dé apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Kámẹ́lì,+ ó tún dé Ṣihori-líbínátì, 27 ó wá pa dà sápá ìlà oòrùn lọ sí Bẹti-dágónì, ó dé Sébúlúnì àti Àfonífojì Ifita-élì lápá àríwá, ó dé Bẹti-émékì àti Néélì, ó sì dé Kábúlù ní apá òsì, 28 ó dé Ébúrónì, Réhóbù, Hámónì àti Kánà títí lọ dé Sídónì Ńlá.+ 29 Ààlà náà sì pa dà sí Rámà títí dé Tírè+ tó jẹ́ ìlú olódi. Ó wá pa dà sí Hósà, ó sì parí sí òkun, ní agbègbè Ákísíbù, 30 Úmà, Áfékì+ àti Réhóbù,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú méjìlélógún (22), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 31 Èyí ni ogún ẹ̀yà Áṣérì ní ìdílé-ìdílé.+ Èyí sì ni àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
32 Kèké kẹfà+ mú àwọn àtọmọdọ́mọ Náfútálì, àwọn àtọmọdọ́mọ Náfútálì ní ìdílé-ìdílé. 33 Ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ láti Héléfì, láti ibi igi ńlá ní Sáánánímù+ àti Adami-nékébù pẹ̀lú Jábínéélì títí dé Lákúmì; ó sì parí sí Jọ́dánì. 34 Ààlà náà wá pa dà sápá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Asinoti-tábórì, ó lọ látibẹ̀ sí Húkókù, ó sì dé Sébúlúnì ní gúúsù, ó tún dé Áṣérì ní ìwọ̀ oòrùn àti Júdà ní Jọ́dánì lápá ìlà oòrùn. 35 Àwọn ìlú olódi náà ni Sídíímù, Sérì, Hémátì,+ Rákátì, Kínérétì, 36 Ádámà, Rámà, Hásórì,+ 37 Kédéṣì,+ Édíréì, Ẹ́ń-hásórì, 38 Yírónì, Migidali-élì, Hórémù, Bẹti-ánátì àti Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kàndínlógún (19), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn. 39 Èyí ni ogún ẹ̀yà Náfútálì ní ìdílé-ìdílé,+ àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
40 Kèké keje+ mú ẹ̀yà Dánì+ ní ìdílé-ìdílé. 41 Ààlà ogún wọn sì ni Sórà,+ Éṣítáólì, Iri-ṣéméṣì, 42 Ṣáálábínì,+ Áíjálónì,+ Ítílà, 43 Élónì, Tímúnà,+ Ẹ́kírónì,+ 44 Élétékè, Gíbétónì,+ Báálátì, 45 Jéhúdù, Bẹne-bérákì, Gati-rímónì,+ 46 Me-jákónì àti Rákónì, ààlà náà sì dojú kọ Jópà.+ 47 Àmọ́ ilẹ̀ Dánì ti kéré jù fún wọn.+ Torí náà, wọ́n lọ bá Léṣémù + jà, wọ́n gbà á, wọ́n sì fi idà ṣá wọn balẹ̀. Ó di tiwọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọ́n wá yí orúkọ Léṣémù pa dà sí Dánì, ìyẹn Dánì tó jẹ́ orúkọ baba ńlá wọn.+ 48 Èyí ni ogún ẹ̀yà Dánì ní ìdílé-ìdílé. Èyí sì ni àwọn ìlú náà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.
49 Bí wọ́n ṣe pín àwọn ilẹ̀ tí wọ́n jogún náà tán nìyí gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlú tó wà níbẹ̀. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá fún Jóṣúà ọmọ Núnì ní ogún láàárín wọn. 50 Bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ, wọ́n fún un ní ìlú tó béèrè, ìyẹn Timunati-sírà,+ ní agbègbè olókè Éfúrémù, ó kọ́ ìlú náà, ó sì ń gbé inú rẹ̀.
51 Èyí ni àwọn ogún tí àlùfáà Élíásárì, Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé bàbá nínú ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi kèké pín+ ní Ṣílò+ níwájú Jèhófà, ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ Bí wọ́n ṣe pín àwọn ilẹ̀ náà tán nìyẹn.