Jóòbù
17 “Ìbànújẹ́ ti bá ẹ̀mí mi, àwọn ọjọ́ mi ti dópin;
Itẹ́ òkú ń retí mi.+
3 Jọ̀ọ́, gba ohun tí mo fi ṣe ìdúró, kí o sì tọ́jú rẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ.
Ta ló tún máa bọ̀ mí lọ́wọ́, tó sì máa dúró fún mi?+
4 Torí o ò jẹ́ kí ọkàn wọn ní òye;+
Ìdí nìyẹn tí o kò fi gbé wọn ga.
5 Ó lè fẹ́ kí òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pín in,
Síbẹ̀, ojú àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣú.
7 Ìrora ti sọ ojú mi di bàìbàì,+
Òjìji sì ni gbogbo apá àti ẹsẹ̀ mi.
8 Àwọn olóòótọ́ ń wo èyí tìyanutìyanu,
Ọkàn aláìṣẹ̀ ò sì balẹ̀ torí ẹni tí kò mọ Ọlọ́run.*
10 Àmọ́ gbogbo yín tún lè wá máa ro ẹjọ́ yín,
Torí mi ò rí ọlọ́gbọ́n kankan nínú yín.+
12 Wọ́n ń sọ òru di ọ̀sán,
Wọ́n ń sọ pé, ‘Ó ní láti jẹ́ pé ìmọ́lẹ̀ wà nítòsí torí òkùnkùn ṣú.’
14 Màá ké pe ihò*+ pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi!’
Àti ìdin pé, ‘Ìyá mi àti arábìnrin mi!’
15 Ibo wá ni ìrètí mi+ wà?
Ta ló lè bá mi rí ìrètí?