ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 59
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì mú kí wọ́n jìnnà sí Ọlọ́run (1-8)

      • Wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ (9-15a)

      • Jèhófà dá sí i torí àwọn tó ronú pìwà dà (15b-21)

Àìsáyà 59:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wúwo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:23; Ais 50:2
  • +Sm 116:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 290-291

Àìsáyà 59:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:25
  • +Di 31:16, 17; 32:20; Ais 57:17; Isk 39:23; Mik 3:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 290-291

Àìsáyà 59:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:15; Jer 2:34; Isk 7:23
  • +Jer 7:9, 10; Isk 13:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 291

Àìsáyà 59:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Òfìfo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:1; Isk 22:30; Mik 7:2
  • +Ais 30:12, 13
  • +Mik 2:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 291-292

Àìsáyà 59:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 8:13, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 292-293

Àìsáyà 59:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 57:12
  • +Jer 6:7; Mik 6:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 293

Àìsáyà 59:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 22:17; Isk 9:9; Mt 23:35
  • +Ro 3:15-17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 293-294

Àìsáyà 59:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:7; 59:15; Jer 5:1; Emọ 6:12; Hab 1:4
  • +Jer 8:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 293-294

Àìsáyà 59:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 294-295

Àìsáyà 59:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15, 29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 294-295

Àìsáyà 59:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 294-295

Àìsáyà 59:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:5; Isk 5:5, 6
  • +Jer 14:7; Ho 5:5
  • +Ẹsr 9:13; Ne 9:33; Da 9:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 295

Àìsáyà 59:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 31:6; 32:6; Jer 17:13
  • +Jer 5:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 295

Àìsáyà 59:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìṣòtítọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 82:2; Hab 1:4
  • +Ais 5:22, 23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 296-297

Àìsáyà 59:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ìṣòtítọ́.”

  • *

    Ní Héb., “ó sì burú ní ojú rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:1
  • +Mik 3:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 296-298

Àìsáyà 59:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú kó ṣẹ́gun.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 297-298

Àìsáyà 59:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìṣẹ́gun.”

  • *

    Tàbí “aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 6:17; 1Tẹ 5:8
  • +Di 32:35; Sm 94:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 297-299

Àìsáyà 59:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 34:11; Sm 62:12; Jer 17:10
  • +Ais 1:24; Ida 4:11; Isk 5:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 298-299

Àìsáyà 59:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 299

Àìsáyà 59:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:17
  • +Ais 62:11
  • +Di 30:1-3; Ro 11:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 299-300

Àìsáyà 59:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Ní Héb., “èso àwọn èso rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 11:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 299-302

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    7/1/1995, ojú ìwé 15

Àwọn míì

Àìsá. 59:1Nọ 11:23; Ais 50:2
Àìsá. 59:1Sm 116:1
Àìsá. 59:2Jer 5:25
Àìsá. 59:2Di 31:16, 17; 32:20; Ais 57:17; Isk 39:23; Mik 3:4
Àìsá. 59:3Ais 1:15; Jer 2:34; Isk 7:23
Àìsá. 59:3Jer 7:9, 10; Isk 13:8
Àìsá. 59:4Jer 5:1; Isk 22:30; Mik 7:2
Àìsá. 59:4Ais 30:12, 13
Àìsá. 59:4Mik 2:1
Àìsá. 59:5Job 8:13, 14
Àìsá. 59:6Ais 57:12
Àìsá. 59:6Jer 6:7; Mik 6:12
Àìsá. 59:7Jer 22:17; Isk 9:9; Mt 23:35
Àìsá. 59:7Ro 3:15-17
Àìsá. 59:8Ais 5:7; 59:15; Jer 5:1; Emọ 6:12; Hab 1:4
Àìsá. 59:8Jer 8:15
Àìsá. 59:9Ais 5:30
Àìsá. 59:10Di 28:15, 29
Àìsá. 59:12Ais 1:5; Isk 5:5, 6
Àìsá. 59:12Jer 14:7; Ho 5:5
Àìsá. 59:12Ẹsr 9:13; Ne 9:33; Da 9:5
Àìsá. 59:13Ais 31:6; 32:6; Jer 17:13
Àìsá. 59:13Jer 5:23
Àìsá. 59:14Sm 82:2; Hab 1:4
Àìsá. 59:14Ais 5:22, 23
Àìsá. 59:15Ais 48:1
Àìsá. 59:15Mik 3:2
Àìsá. 59:17Ef 6:17; 1Tẹ 5:8
Àìsá. 59:17Di 32:35; Sm 94:1
Àìsá. 59:18Job 34:11; Sm 62:12; Jer 17:10
Àìsá. 59:18Ais 1:24; Ida 4:11; Isk 5:13
Àìsá. 59:20Ais 48:17
Àìsá. 59:20Ais 62:11
Àìsá. 59:20Di 30:1-3; Ro 11:26
Àìsá. 59:21Ro 11:27
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 59:1-21

Àìsáyà

59 Wò ó! Ọwọ́ Jèhófà kò kúrú jù láti gbani là,+

Bẹ́ẹ̀ ni etí rẹ̀ kò di* tí kò fi lè gbọ́.+

 2 Rárá, àwọn àṣìṣe yín ti pín ẹ̀yin àti Ọlọ́run yín níyà.+

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín ti mú kó fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún yín,

Ó sì kọ̀ láti gbọ́ yín.+

 3 Torí ẹ̀jẹ̀ ti sọ àtẹ́lẹwọ́ yín di eléèérí,+

Ẹ̀ṣẹ̀ sì ti sọ ìka yín di eléèérí.

Ètè yín ń parọ́,+ ahọ́n yín sì ń sọ àìṣòdodo kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́.

 4 Kò sí ẹni tó ń wá òdodo,+

Kò sí ẹni tó ń fi òótọ́ inú lọ sí ilé ẹjọ́.

Ohun tí kò sí rárá* ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé,+ wọ́n sì ń sọ ohun tí kò ní láárí.

Wọ́n lóyún wàhálà, wọ́n sì bí ohun tó ń pani lára.+

 5 Wọ́n pa ẹyin ejò olóró,

Wọ́n sì hun òwú aláǹtakùn.+

Ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹyin wọn máa kú,

Ẹyin tí wọ́n sì tẹ̀ fọ́ mú ejò paramọ́lẹ̀ jáde.

 6 Òwú aláǹtakùn wọn ò ní dà bí aṣọ,

Wọn ò sì ní fi ohun tí wọ́n ṣe bo ara wọn.+

Iṣẹ́ wọn léwu,

Ìwà ipá ló sì kún ọwọ́ wọn.+

 7 Ẹsẹ̀ wọn ń sáré láti hùwà burúkú,

Wọ́n sì ń yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.+

Ohun burúkú ni wọ́n ń rò;

Ìparun àti ìyà wà ní àwọn ọ̀nà wọn.+

 8 Wọn ò mọ ọ̀nà àlàáfíà,

Kò sí ìdájọ́ òdodo ní àwọn ipa ọ̀nà wọn.+

Wọ́n mú kí àwọn ọ̀nà wọn wọ́;

Ìkankan nínú àwọn tó ń rìn níbẹ̀ kò ní mọ àlàáfíà.+

 9 Ìdí nìyẹn tí ìdájọ́ òdodo fi jìnnà sí wa,

Tí òdodo kò sì lé wa bá.

À ń retí ìmọ́lẹ̀ ṣáá, àmọ́ wò ó! òkùnkùn ló ṣú;

À ń retí ìmọ́lẹ̀ tó tàn yòò, àmọ́ a ò yéé rìn nínú ìṣúdùdù.+

10 À ń táràrà níbi ògiri bí afọ́jú;

À ń táràrà bí àwọn tí kò ní ojú.+

A kọsẹ̀ ní ọ̀sán gangan bíi pé a wà nínú òkùnkùn alẹ́;

Ṣe la dà bí òkú láàárín àwọn alágbára.

11 Gbogbo wa ń kùn ṣáá bíi bíárì,

A sì ń ṣọ̀fọ̀, à ń ké kúùkúù bí àdàbà.

À ń retí ìdájọ́ òdodo, àmọ́ kò sí;

À ń retí ìgbàlà, àmọ́ ó jìnnà gan-an sí wa.

12 Torí ọ̀tẹ̀ wa pọ̀ níwájú rẹ;+

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ń ta kò wá níkọ̀ọ̀kan.+

Torí àwọn ọ̀tẹ̀ wa wà pẹ̀lú wa;

A mọ àwọn àṣìṣe wa dáadáa.+

13 A ti ṣẹ̀, a sì ti sẹ́ Jèhófà;

A ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run wa,

A ti sọ̀rọ̀ nípa ìnilára àti ọ̀tẹ̀;+

A ti lóyún irọ́, a sì ti sọ̀rọ̀ èké kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ látinú ọkàn.+

14 Wọ́n ti rọ́ ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,+

Òdodo sì dúró sí ọ̀nà jíjìn;+

Nítorí pé òtítọ́* ti kọsẹ̀ ní ojúde ìlú,

Ohun tó tọ́ kò sì rí ọ̀nà wọlé.

15 Òtítọ́* ti pòórá,+

Ẹnikẹ́ni tó bá sì yí pa dà kúrò nínú ohun tó burú ni wọ́n ń kó lẹ́rù.

Jèhófà rí i, inú rẹ̀ ò sì dùn*

Torí kò sí ìdájọ́ òdodo.+

16 Ó rí i pé kò sí èèyàn kankan,

Ó sì yà á lẹ́nu pé ẹnì kankan ò bá wọn bẹ̀bẹ̀,

Torí náà, apá rẹ̀ mú ìgbàlà wá,*

Òdodo rẹ̀ sì tì í lẹ́yìn.

17 Ó wá gbé òdodo wọ̀ bí ẹ̀wù irin,

Ó sì dé akoto ìgbàlà* sí orí rẹ̀.+

Ó wọ ẹ̀wù ẹ̀san bí aṣọ,+

Ó sì fi ìtara bo ara rẹ̀ bí aṣọ àwọ̀lékè.*

18 Ó máa san wọ́n lẹ́san ohun tí wọ́n ṣe:+

Ó máa bínú sí àwọn elénìní rẹ̀, ó máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn ọ̀tá rẹ̀.+

Ó sì máa san ohun tó yẹ àwọn erékùṣù fún wọn.

19 Wọ́n máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà láti ìwọ̀ oòrùn

Àti ògo rẹ̀ láti ìlà oòrùn,

Torí ó máa wọlé wá bí odò tó ń yára ṣàn,

Tí ẹ̀mí Jèhófà ń gbé lọ.

20 “Olùtúnrà+ máa wá sí Síónì,+

Sọ́dọ̀ àwọn ti Jékọ́bù, àwọn tó yí pa dà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀,”+ ni Jèhófà wí.

21 “Ní tèmi, májẹ̀mú tí mo bá wọn dá nìyí,”+ ni Jèhófà wí. “Ẹ̀mí mi tó wà lára rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ kò ní kúrò ní ẹnu rẹ, ní ẹnu àwọn ọmọ* rẹ tàbí ní ẹnu àwọn ọmọ ọmọ rẹ,”* ni Jèhófà wí, “láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́