ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Wòlíì Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀dá máa wà (1)

      • Àwọn ẹyẹ ìwò bọ́ Èlíjà (2-7)

      • Èlíjà dé sọ́dọ̀ opó kan ní Sáréfátì (8-16)

      • Ọmọ opó náà kú, ó sì jíǹde (17-24)

1 Àwọn Ọba 17:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ọlọ́run Mi.”

  • *

    Ní Héb., “tí mo dúró síwájú rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 17:15, 16, 22, 24; 18:36, 38, 46; 2Ọb 2:8, 11; Lk 1:17; Jo 1:19, 21
  • +Joṣ 22:9
  • +Di 28:15, 23; Jer 14:22; Lk 4:25; Jem 5:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/1/1992, ojú ìwé 17

1 Àwọn Ọba 17:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/1/1992, ojú ìwé 18

1 Àwọn Ọba 17:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:25; Mt 6:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/1/1992, ojú ìwé 18

1 Àwọn Ọba 17:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 11:23; Ond 15:19

1 Àwọn Ọba 17:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:5

1 Àwọn Ọba 17:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 4:25, 26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 13-14

    4/1/1992, ojú ìwé 18-19

1 Àwọn Ọba 17:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:32, 37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 13

1 Àwọn Ọba 17:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 13

1 Àwọn Ọba 17:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 4:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 14

1 Àwọn Ọba 17:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 14

1 Àwọn Ọba 17:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:10; 37:17, 19; Flp 4:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 14

1 Àwọn Ọba 17:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 10:41, 42; Lk 4:25, 26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 14-15

1 Àwọn Ọba 17:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 14-15

1 Àwọn Ọba 17:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 4:19, 20

1 Àwọn Ọba 17:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Kí ló pa èmi àti ìwọ pọ̀, . . .?”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 13:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 15

1 Àwọn Ọba 17:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 4:21, 32

1 Àwọn Ọba 17:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 99:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2014, ojú ìwé 15

1 Àwọn Ọba 17:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

1 Àwọn Ọba 17:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jem 5:16
  • +Di 32:39; 1Sa 2:6; 2Ọb 4:32, 34; 13:21; Lk 7:15; 8:54, 55; Jo 5:28, 29; 11:44; Iṣe 9:40, 41; 20:9, 10; Ro 14:9; Heb 11:17, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2007, ojú ìwé 5

    4/1/1999, ojú ìwé 16

    Nígbà Tí A Bá Kú, ojú ìwé 23

1 Àwọn Ọba 17:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:35

1 Àwọn Ọba 17:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:2

Àwọn míì

1 Ọba 17:11Ọb 17:15, 16, 22, 24; 18:36, 38, 46; 2Ọb 2:8, 11; Lk 1:17; Jo 1:19, 21
1 Ọba 17:1Joṣ 22:9
1 Ọba 17:1Di 28:15, 23; Jer 14:22; Lk 4:25; Jem 5:17
1 Ọba 17:4Sm 37:25; Mt 6:11
1 Ọba 17:6Nọ 11:23; Ond 15:19
1 Ọba 17:71Ọb 18:5
1 Ọba 17:9Lk 4:25, 26
1 Ọba 17:10Heb 11:32, 37
1 Ọba 17:122Ọb 4:2
1 Ọba 17:14Sm 34:10; 37:17, 19; Flp 4:19
1 Ọba 17:15Mt 10:41, 42; Lk 4:25, 26
1 Ọba 17:172Ọb 4:19, 20
1 Ọba 17:18Job 13:26
1 Ọba 17:192Ọb 4:21, 32
1 Ọba 17:20Sm 99:6
1 Ọba 17:22Jem 5:16
1 Ọba 17:22Di 32:39; 1Sa 2:6; 2Ọb 4:32, 34; 13:21; Lk 7:15; 8:54, 55; Jo 5:28, 29; 11:44; Iṣe 9:40, 41; 20:9, 10; Ro 14:9; Heb 11:17, 19
1 Ọba 17:23Heb 11:35
1 Ọba 17:24Jo 3:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 17:1-24

Àwọn Ọba Kìíní

17 Nígbà náà, Èlíjà*+ ará Tíṣíbè, tó ń gbé ní Gílíádì+ sọ fún Áhábù pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí mò ń sìn* ti wà láàyè, kò ní sí òjò tàbí ìrì ní àwọn ọdún tó ń bọ̀, àfi nípa ọ̀rọ̀ mi!”+

2 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 3 “Kúrò ní ibí yìí, kí o forí lé ìlà oòrùn, kí o sì fara pa mọ́ sí Àfonífojì Kérítì, tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì. 4 Kí o máa mu omi láti inú odò tó wà níbẹ̀, màá sì pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò pé kí wọ́n máa gbé oúnjẹ wá fún ọ níbẹ̀.”+ 5 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Jèhófà sọ; ó lọ sí Àfonífojì Kérítì tó wà ní ìlà oòrùn Jọ́dánì, ó sì dúró síbẹ̀. 6 Àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní àárọ̀, wọ́n tún ń gbé búrẹ́dì àti ẹran wá fún un ní ìrọ̀lẹ́, ó sì ń mu omi láti inú odò náà.+ 7 Àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, odò náà gbẹ+ torí pé òjò ò rọ̀ ní ilẹ̀ náà.

8 Jèhófà bá a sọ̀rọ̀, ó ní: 9 “Dìde, lọ sí Sáréfátì, ti Sídónì, kí o sì máa gbé ibẹ̀. Wò ó! Màá pàṣẹ fún opó kan níbẹ̀, pé kí ó máa gbé oúnjẹ wá fún ọ.”+ 10 Torí náà, ó dìde, ó sì lọ sí Sáréfátì. Nígbà tó dé ẹnu ọ̀nà ìlú náà, opó kan wà níbẹ̀ tó ń ṣa igi jọ. Torí náà, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi fi ife bu omi díẹ̀ wá kí n mu.”+ 11 Bí ó ṣe ń lọ bù ú wá, ó pè é, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, bá mi mú búrẹ́dì díẹ̀ bọ̀.” 12 Obìnrin náà wá sọ pé: “Bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti wà láàyè, mi ò ní búrẹ́dì kankan, àfi ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú ìṣà kékeré.+ Ńṣe ni mò ń ṣa igi díẹ̀ jọ, kí n lè wọlé lọ ṣe nǹkan díẹ̀ fún èmi àti ọmọ mi. Lẹ́yìn tí a bá ti jẹ ẹ́ tán, a ò ní nǹkan míì, ikú ló kàn.”

13 Ni Èlíjà bá sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù. Wọlé lọ, kí o sì ṣe bí o ṣe sọ. Àmọ́ kọ́kọ́ bá mi fi ohun tó wà nílẹ̀ ṣe búrẹ́dì ribiti kékeré kan, kí o sì gbé e wá fún mi. Lẹ́yìn náà, o lè wá ṣe nǹkan kan fún ìwọ àti ọmọ rẹ. 14 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ìyẹ̀fun kò ní tán nínú ìkòkò náà, òróró ò sì ní gbẹ nínú ìṣà kékeré náà títí di ọjọ́ tí Jèhófà yóò rọ òjò sórí ilẹ̀.’”+ 15 Nítorí náà, ó lọ, ó sì ṣe ohun tí Èlíjà sọ, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni obìnrin náà àti agbo ilé rẹ̀ pẹ̀lú Èlíjà fi rí oúnjẹ jẹ.+ 16 Ìyẹ̀fun kò tán nínú ìkòkò náà, òróró kò sì gbẹ nínú ìṣà kékeré náà, bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Èlíjà sọ.

17 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọmọ obìnrin tí ó ni ilé náà ṣàìsàn, àìsàn tó ṣe é sì le débi pé kò lè mí mọ́.+ 18 Ni ó bá sọ fún Èlíjà pé: “Kí ni mo ṣe fún ọ,* ìwọ èèyàn Ọlọ́run tòótọ́? Ṣé o wá rán mi létí ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá, kí o sì pa mí lọ́mọ ni?”+ 19 Àmọ́, ó sọ fún un pé: “Gbé ọmọ rẹ fún mi.” Nígbà náà, ó gbà á lọ́wọ́ rẹ̀, ó gbé e lọ sí yàrá orí òrùlé, níbi tó ń gbé, ó sì tẹ́ ẹ sórí ibùsùn rẹ̀.+ 20 Ó ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi,+ ṣé wàá tún mú àjálù bá opó tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni, tí o fi jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ kú?” 21 Lẹ́yìn náà, ó nà sórí ọmọ náà ní ìgbà mẹ́ta, ó sì ké pe Jèhófà pé: “Jèhófà Ọlọ́run mi, jọ̀wọ́, mú kí ẹ̀mí* ọmọ yìí sọ jí.” 22 Jèhófà gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Èlíjà,+ ẹ̀mí* ọmọ náà sọ jí, ó sì yè.+ 23 Èlíjà gbé ọmọ náà, ó gbé e sọ̀ kalẹ̀ láti yàrá orí òrùlé wá sínú ilé, ó sì gbé e fún ìyá rẹ̀; Èlíjà wá sọ pé: “Wò ó, ọmọ rẹ yè.”+ 24 Obìnrin náà wá sọ fún Èlíjà pé: “Mo ti wá mọ̀ báyìí pé èèyàn Ọlọ́run+ ni ọ́ lóòótọ́ àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà lẹ́nu rẹ jẹ́ òótọ́.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́