ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Orin Sólómọ́nì 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Orin Sólómọ́nì

    • Ọ̀DỌ́BÌNRIN ṢÚLÁMÁÍTÌ WÀ NÍNÚ ÀGỌ́ ỌBA SÓLÓMỌ́NÌ (1:1–3:5)

        • Orin tó ju orin lọ (1)

        • Ọ̀dọ́bìnrin (2-7)

        • Àwọn ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù (8)

        • Ọba (9-11)

          • “A máa fi wúrà ṣe ohun ọ̀ṣọ́ fún ọ” (11)

        • Ọ̀dọ́bìnrin (12-14)

          • “Olólùfẹ́ mi dà bí àpò òjíá tó ń ta sánsán” (13)

        • Olùṣọ́ àgùntàn (15)

          • “O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi”

        • Ọ̀dọ́bìnrin(16, 17)

          • “O rẹwà púpọ̀, olólùfẹ́ mi” (16)

Orin Sólómọ́nì 1:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Orin tó dùn jù lọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:29, 32

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 17

Orin Sólómọ́nì 1:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 4:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2015, ojú ìwé 30-31

    11/15/2006, ojú ìwé 18

Orin Sólómọ́nì 1:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 27:9; Onw 9:8; Sol 5:5
  • +Onw 7:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2015, ojú ìwé 30-31

    11/15/2006, ojú ìwé 18

Orin Sólómọ́nì 1:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Fà mí lọ́wọ́.”

  • *

    Tàbí “sọ.”

  • *

    Ìyẹn, àwọn ọ̀dọ́bìnrin.

Orin Sólómọ́nì 1:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 120:5; Isk 27:21
  • +Ẹk 36:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 18

Orin Sólómọ́nì 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2015, ojú ìwé 32

Orin Sólómọ́nì 1:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ọkàn mi fẹ́.”

  • *

    Tàbí “tó lo aṣọ ọ̀fọ̀ tí wọ́n fi ń bojú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 6:3

Orin Sólómọ́nì 1:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “abo ẹṣin mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:28; 2Kr 1:16, 17; Sol 6:4

Orin Sólómọ́nì 1:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Irun tí o dì.”

Orin Sólómọ́nì 1:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun ọ̀ṣọ́ tó rí roboto.”

Orin Sólómọ́nì 1:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Sípíkénádì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 4:13, 14

Orin Sólómọ́nì 1:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:23, 25; Ẹst 2:12; Sm 45:8; Sol 4:6; 5:13

Orin Sólómọ́nì 1:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 4:13
  • +Joṣ 15:20, 62; 1Sa 23:29; 2Kr 20:2

Orin Sólómọ́nì 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 4:1; 5:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 18

Orin Sólómọ́nì 1:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “O dára lọ́mọkùnrin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sol 5:10

Orin Sólómọ́nì 1:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ilé ńlá.”

Àwọn míì

Orin Sól. 1:11Ọb 4:29, 32
Orin Sól. 1:2Sol 4:10
Orin Sól. 1:3Owe 27:9; Onw 9:8; Sol 5:5
Orin Sól. 1:3Onw 7:1
Orin Sól. 1:5Sm 120:5; Isk 27:21
Orin Sól. 1:5Ẹk 36:14
Orin Sól. 1:7Sol 6:3
Orin Sól. 1:91Ọb 10:28; 2Kr 1:16, 17; Sol 6:4
Orin Sól. 1:12Sol 4:13, 14
Orin Sól. 1:13Ẹk 30:23, 25; Ẹst 2:12; Sm 45:8; Sol 4:6; 5:13
Orin Sól. 1:14Sol 4:13
Orin Sól. 1:14Joṣ 15:20, 62; 1Sa 23:29; 2Kr 20:2
Orin Sól. 1:15Sol 4:1; 5:2
Orin Sól. 1:16Sol 5:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Orin Sólómọ́nì 1:1-17

Orin Sólómọ́nì

1 Orin tó ju orin lọ,* tí Sólómọ́nì+ kọ:

 2 “Wá fẹnu kò mí lẹ́nu,

Torí ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi dára ju wáìnì lọ.+

 3 Bí àwọn òróró rẹ ṣe ń ta sánsán ń tuni lára.+

Orúkọ rẹ dà bí òróró tó ń ta sánsán tí wọ́n tú jáde.+

Ìdí nìyẹn tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.

 4 Mú mi dání;* jẹ́ ká sáré.

Ọba ti mú mi wọnú àwọn yàrá rẹ̀ tó wà ní inú!

Jẹ́ kí inú wa máa dùn, ká sì jọ máa yọ̀.

Jẹ́ ká yin* ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí ò ń fi hàn sí mi ju ọ̀rọ̀ wáìnì lọ.

Abájọ tí wọ́n* fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.

 5 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù, mo dúdú lóòótọ́, àmọ́ òrékelẹ́wà ni mí,

Bí àwọn àgọ́ tí wọ́n fi Kídárì ṣe,+ bí àwọn aṣọ àgọ́+ Sólómọ́nì.

 6 Ẹ má tẹjú mọ́ mi torí pé mo dúdú,

Oòrùn ló sọ mí dà bẹ́ẹ̀.

Àwọn ọmọ ìyá mi bínú sí mi;

Wọ́n ní kí n máa bójú tó àwọn ọgbà àjàrà,

Àmọ́ mi ò bójú tó ọgbà àjàrà tèmi.

 7 Ìwọ ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́* gan-an, sọ fún mi,

Ibi ìjẹko tí o ti ń da àwọn ẹran rẹ,+

Ibi tí ò ń mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ sí ní ọ̀sán.

Ṣé ó wá yẹ kí n dà bí obìnrin tó fi aṣọ bojú*

Nínú agbo ẹran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ?”

 8 “Tó ò bá mọ̀, ìwọ obìnrin tó rẹwà jù,

Gba ibi tí agbo ẹran náà gbà,

Kí o sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ewúrẹ́ rẹ máa jẹko lẹ́gbẹ̀ẹ́ àgọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn.”

 9 “Olólùfẹ́ mi, mo fi ọ́ wé abo ẹṣin* láàárín àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò.+

10 Ohun ọ̀ṣọ́* mú kí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ lẹ́wà,

Ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn rẹ sì mú kí ọrùn rẹ lẹ́wà.

11 A máa fi wúrà ṣe ohun ọ̀ṣọ́* fún ọ,

A ó sì fi fàdákà sí i lára.”

12 “Nígbà tí ọba jókòó sídìí tábìlì rẹ̀,

Lọ́fínńdà*+ mi ń ta sánsán.

13 Lójú mi, olólùfẹ́ mi dà bí àpò òjíá+ tó ń ta sánsán,

Tó ń sùn mọ́jú láàárín ọmú mi.

14 Lójú mi, olólùfẹ́ mi rí bí ìdì ewé làálì,+

Láàárín àwọn ọgbà àjàrà Ẹ́ń-gédì.”+

15 “Wò ó! O rẹwà gan-an, olólùfẹ́ mi.

Wò ó! O rẹwà gan-an. Ojú rẹ rí bíi ti àdàbà.”+

16 “Wò ó! O rẹwà púpọ̀,* olólùfẹ́ mi, o sì wù mí gan-an.+

Àárín ewéko ni ibùsùn wa.

17 Igi kédárì ni àwọn òpó ilé* wa,

Igi júnípà ni a sì fi ró ilé wa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́