ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa pa run (1-17)

        • Wòlíì pín irun rẹ̀ tó fá sí ọ̀nà mẹ́ta (1-4)

        • Ìwà Jerúsálẹ́mù burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè lọ (7-9)

        • Ìyà mẹ́ta tó máa jẹ àwọn ọlọ̀tẹ̀ (12)

Ìsíkíẹ́lì 5:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 64-65

Ìsíkíẹ́lì 5:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:21; Isk 4:8
  • +Jer 15:2
  • +Le 26:33; Isk 5:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 64-66

Ìsíkíẹ́lì 5:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 64-65

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2007, ojú ìwé 12

Ìsíkíẹ́lì 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:4

Ìsíkíẹ́lì 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:46, 47

Ìsíkíẹ́lì 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:9, 11; Jer 2:11

Ìsíkíẹ́lì 5:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:5; Isk 15:7
  • +Di 29:22, 24; 1Ọb 9:8; Ida 2:15

Ìsíkíẹ́lì 5:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 4:6; Da 9:12

Ìsíkíẹ́lì 5:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:29; Jer 19:9; Ida 4:10
  • +Le 26:33; Di 28:64

Ìsíkíẹ́lì 5:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dín yín kù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 20:3; 2Ọb 21:1, 7; 2Kr 36:14; Jer 32:34
  • +Ida 2:21; Isk 7:4

Ìsíkíẹ́lì 5:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àìsàn.”

  • *

    Ní Héb., “sínú gbogbo afẹ́fẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:12; 15:2; 21:9
  • +Le 26:33; Jer 9:16; 42:16

Ìsíkíẹ́lì 5:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:42
  • +Ẹk 20:3, 5; 34:14; Di 6:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 99-100

Ìsíkíẹ́lì 5:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:37; 1Ọb 9:7; Ne 2:17

Ìsíkíẹ́lì 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 79:4; Jer 24:9; Ida 2:15; 3:61, 62

Ìsíkíẹ́lì 5:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá búrẹ́dì.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọ̀pá tí wọ́n fi ń tọ́jú búrẹ́dì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:23
  • +Le 26:26; Isk 4:16

Ìsíkíẹ́lì 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:22; Di 32:24; Isk 14:21; 33:27
  • +Isk 21:3

Àwọn míì

Ìsík. 5:2Jer 9:21; Isk 4:8
Ìsík. 5:2Jer 15:2
Ìsík. 5:2Le 26:33; Isk 5:12
Ìsík. 5:4Jer 4:4
Ìsík. 5:6Isk 16:46, 47
Ìsík. 5:72Ọb 21:9, 11; Jer 2:11
Ìsík. 5:8Jer 21:5; Isk 15:7
Ìsík. 5:8Di 29:22, 24; 1Ọb 9:8; Ida 2:15
Ìsík. 5:9Ida 4:6; Da 9:12
Ìsík. 5:10Le 26:29; Jer 19:9; Ida 4:10
Ìsík. 5:10Le 26:33; Di 28:64
Ìsík. 5:11Le 20:3; 2Ọb 21:1, 7; 2Kr 36:14; Jer 32:34
Ìsík. 5:11Ida 2:21; Isk 7:4
Ìsík. 5:12Jer 14:12; 15:2; 21:9
Ìsík. 5:12Le 26:33; Jer 9:16; 42:16
Ìsík. 5:13Isk 16:42
Ìsík. 5:13Ẹk 20:3, 5; 34:14; Di 6:15
Ìsík. 5:14Di 28:37; 1Ọb 9:7; Ne 2:17
Ìsík. 5:15Sm 79:4; Jer 24:9; Ida 2:15; 3:61, 62
Ìsík. 5:16Di 32:23
Ìsík. 5:16Le 26:26; Isk 4:16
Ìsík. 5:17Le 26:22; Di 32:24; Isk 14:21; 33:27
Ìsík. 5:17Isk 21:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 5:1-17

Ìsíkíẹ́lì

5 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, mú idà kan tó mú kí o lè lò ó bí abẹ ìfárí. Fá orí rẹ àti irùngbọ̀n rẹ, kí o sì mú òṣùwọ̀n kí o lè wọn irun náà, kí o sì pín in. 2 O máa fi iná sun ìdá mẹ́ta irun náà nínú ìlú náà nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dó tì í bá pé.+ O máa kó ìdá mẹ́ta míì, o sì máa fi idà gé e káàkiri ìlú náà,+ kí o wá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́, èmi yóò sì mú idà kí n lè lé wọn bá.+

3 “Kí o tún mú fọ́nrán díẹ̀ nínú irun náà, kí o sì wé e mọ́ aṣọ rẹ. 4 Kí o mú díẹ̀ sí i lára rẹ̀, kí o jù ú sínú iná, kí o sì sun ún di eérú. Láti ibẹ̀ ni iná yóò ti ran gbogbo ilé Ísírẹ́lì.+

5 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èyí ni Jerúsálẹ́mù. Mo ti fi í sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ìlú sì yí i ká. 6 Àmọ́, ó ti kọ àwọn ìdájọ́ àti àṣẹ mi, ìwà rẹ̀ sì burú ju ti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìlú tó yí i ká lọ.+ Torí wọ́n ti kọ àwọn ìdájọ́ mi, wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi.’

7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí pé agídí yín pọ̀ ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká, tí ẹ kò tẹ̀ lé àwọn àṣẹ mi, tí ẹ sì kọ àwọn ìdájọ́ mi; àmọ́ ẹ tẹ̀ lé ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí yín ká,+ 8 ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò kọjú ìjà sí ọ, ìwọ ìlú,+ èmi fúnra mi yóò sì ṣèdájọ́ ní àárín rẹ lójú àwọn orílẹ̀-èdè.+ 9 Ohun tí mi ò ṣe rí ni màá ṣe fún ọ, mi ò sì tún ní ṣe irú rẹ̀ mọ́, torí gbogbo ohun ìríra tí ò ń ṣe.+

10 “‘“Ṣe ni àwọn bàbá tó wà ní àárín yín yóò jẹ àwọn ọmọ wọn,+ àwọn ọmọ yóò sì jẹ àwọn bàbá wọn, màá ṣe ìdájọ́ yín, màá sì fọ́n àwọn tó ṣẹ́ kù nínú yín káàkiri.”’*+

11 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+ 12 Àjàkálẹ̀ àrùn* tàbí ìyàn máa pa ìdá mẹ́ta lára yín. Wọ́n á sì fi idà pa ìdá mẹ́ta míì láyìíká yín.+ Màá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù káàkiri,* màá sì fa idà yọ láti fi lé wọn.+ 13 Mi ò sì ní bínú mọ́, inú mi ò ní ru sí wọn mọ́, màá ti tẹ́ ara mi lọ́rùn.+ Nígbà tí mo bá ti bínú gidigidi sí wọn tán, wọ́n á mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ti sọ pé èmi nìkan ni mo fẹ́ kí ẹ máa jọ́sìn.+

14 “‘Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro, màá sì mú kí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká àti àwọn tó ń kọjá lọ máa gàn ọ́.+ 15 Wọ́n á gàn ọ́, wọ́n á sì fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.+ Wọ́n á kọ́gbọ́n lára rẹ, ẹ̀rù á sì ba àwọn orílẹ̀-èdè tó yí ọ ká, nígbà tí mo bá fi ìbínú àti ìrunú dá ọ lẹ́jọ́ tí mo sì fìyà jẹ ọ́ gidigidi. Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.

16 “‘Màá fi ìyàn kọ lù wọ́n, ó máa pa wọ́n run bí ìgbà tí mo bá ta wọ́n ní ọfà olóró. Ọfà tí mo bá ta yóò run yín.+ Màá mú kí ìyàn náà le sí i torí pé màá dáwọ́ oúnjẹ yín dúró.*+ 17 Màá fi ìyàn kọ lù yín, màá rán àwọn ẹranko burúkú sí yín,+ wọ́n á sì pa yín lọ́mọ jẹ. Àjàkálẹ̀ àrùn máa bò yín, ìtàjẹ̀sílẹ̀ á kún ilẹ̀ yín, màá sì fi idà kọ lù yín.+ Èmi, Jèhófà, ti sọ ọ́.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́