ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Sólómọ́nì fẹ́ ọmọ Fáráò (1-3)

      • Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá (4-15)

        • Sólómọ́nì béèrè ọgbọ́n (7-9)

      • Sólómọ́nì dá ẹjọ́ láàárín àwọn ìyá méjì (16-28)

1 Àwọn Ọba 3:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:3, 4; 1Ọb 7:8; 9:24; 11:1; Ne 13:25-27
  • +2Sa 5:7; 1Kr 11:7
  • +1Ọb 7:1
  • +1Ọb 8:17-19
  • +1Ọb 9:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2011, ojú ìwé 10

1 Àwọn Ọba 3:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:17
  • +Di 12:5, 6; 1Ọb 5:3; 1Kr 28:6

1 Àwọn Ọba 3:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 7:9; 10:8; 1Kr 21:26

1 Àwọn Ọba 3:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tí ó tóbi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 16:39, 40; 21:29
  • +2Kr 1:3-6

1 Àwọn Ọba 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 1:7-10

1 Àwọn Ọba 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:1, 4

1 Àwọn Ọba 3:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ kékeré.”

  • *

    Ní Héb., “mi ò mọ bí a ṣe ń jáde àti bí a ṣe ń wọlé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:1; Jer 1:6

1 Àwọn Ọba 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5, 6

1 Àwọn Ọba 3:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “tó ṣòro.” Ní Héb., “tó wúwo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 72:1; 119:34
  • +Heb 5:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2007, ojú ìwé 27

    7/15/1998, ojú ìwé 25-27

1 Àwọn Ọba 3:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 15:8

1 Àwọn Ọba 3:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọjọ́ púpọ̀.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 22:12; 29:19; 2Kr 1:11, 12; Owe 16:16

1 Àwọn Ọba 3:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 1:16; 1Jo 5:14
  • +1Ọb 4:29; Owe 2:3-5; Jem 1:5
  • +Mt 12:42

1 Àwọn Ọba 3:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìgbésí ayé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 84:11; Mt 6:33; Ef 3:20
  • +1Ọb 4:21; Onw 7:11
  • +1Ọb 10:23

1 Àwọn Ọba 3:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọjọ́ gígùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:5
  • +Sm 21:4; 91:14, 16; Owe 3:13, 16

1 Àwọn Ọba 3:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:11

1 Àwọn Ọba 3:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀rù ọba sì bà wọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:23-25; Sm 72:5
  • +1Ọb 3:9, 10

Àwọn míì

1 Ọba 3:1Di 7:3, 4; 1Ọb 7:8; 9:24; 11:1; Ne 13:25-27
1 Ọba 3:12Sa 5:7; 1Kr 11:7
1 Ọba 3:11Ọb 7:1
1 Ọba 3:11Ọb 8:17-19
1 Ọba 3:11Ọb 9:15
1 Ọba 3:22Kr 33:17
1 Ọba 3:2Di 12:5, 6; 1Ọb 5:3; 1Kr 28:6
1 Ọba 3:31Sa 7:9; 10:8; 1Kr 21:26
1 Ọba 3:41Kr 16:39, 40; 21:29
1 Ọba 3:42Kr 1:3-6
1 Ọba 3:52Kr 1:7-10
1 Ọba 3:61Ọb 2:1, 4
1 Ọba 3:71Kr 29:1; Jer 1:6
1 Ọba 3:8Ẹk 19:5, 6
1 Ọba 3:9Sm 72:1; 119:34
1 Ọba 3:9Heb 5:14
1 Ọba 3:10Owe 15:8
1 Ọba 3:111Kr 22:12; 29:19; 2Kr 1:11, 12; Owe 16:16
1 Ọba 3:12Onw 1:16; 1Jo 5:14
1 Ọba 3:121Ọb 4:29; Owe 2:3-5; Jem 1:5
1 Ọba 3:12Mt 12:42
1 Ọba 3:13Sm 84:11; Mt 6:33; Ef 3:20
1 Ọba 3:131Ọb 4:21; Onw 7:11
1 Ọba 3:131Ọb 10:23
1 Ọba 3:141Ọb 15:5
1 Ọba 3:14Sm 21:4; 91:14, 16; Owe 3:13, 16
1 Ọba 3:15Le 7:11
1 Ọba 3:281Kr 29:23-25; Sm 72:5
1 Ọba 3:281Ọb 3:9, 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 3:1-28

Àwọn Ọba Kìíní

3 Sólómọ́nì bá Fáráò ọba Íjíbítì dána. Ó fẹ́* ọmọbìnrin Fáráò,+ ó sì mú un wá sí Ìlú Dáfídì+ títí ó fi kọ́ ilé rẹ̀ parí+ àti ilé Jèhófà+ pẹ̀lú ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká.+ 2 Àmọ́ àwọn èèyàn náà ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi gíga,+ nítorí títí di àkókò yẹn, wọn ò tíì kọ́ ilé fún orúkọ Jèhófà.+ 3 Ìfẹ́ Jèhófà wà lọ́kàn Sólómọ́nì bó ṣe ń rìn nínú òfin Dáfídì bàbá rẹ̀, kìkì pé ó ń rúbọ ní àwọn ibi gíga, ó sì ń mú àwọn ọrẹ rú èéfín níbẹ̀.+

4 Ọba lọ sí Gíbíónì láti rúbọ níbẹ̀, nítorí ibẹ̀ ni ibi gíga+ tí àwọn èèyàn mọ̀* jù lọ. Ẹgbẹ̀rún kan (1,000) ẹbọ sísun ni Sólómọ́nì rú lórí pẹpẹ náà.+ 5 Ní Gíbíónì, Jèhófà fara han Sólómọ́nì lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì sọ pé: “Béèrè ohun tí wàá fẹ́ kí n fún ọ.”+ 6 Ni Sólómọ́nì bá sọ pé: “O ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dáfídì bàbá mi, lọ́nà tó ga, bó ṣe rìn níwájú rẹ ní òtítọ́ àti ní òdodo pẹ̀lú ọkàn tó dúró ṣinṣin. Títí di òní yìí, ò ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ kan náà hàn sí i lọ́nà tó ga tí o fi fún un ní ọmọkùnrin kan láti jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀.+ 7 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mi, o ti fi ìránṣẹ́ rẹ jọba ní ipò Dáfídì bàbá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́* ni mí, tí mi ò sì ní ìrírí.*+ 8 Ìránṣẹ́ rẹ wà lára àwọn èèyàn rẹ tí o yàn,+ àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an débi pé wọn ò níye, wọn ò sì ṣeé kà. 9 Torí náà, fún ìránṣẹ́ rẹ ní ọkàn tó ń gbọ́ràn láti máa fi ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ,+ láti fi mọ ìyàtọ̀ láàárín rere àti búburú,+ torí ta ló lè ṣe ìdájọ́ àwọn èèyàn rẹ tó pọ̀ gan-an* yìí?”

10 Ohun tí Sólómọ́nì béèrè yìí dára lójú Jèhófà.+ 11 Ọlọ́run wá sọ fún un pé: “Nítorí o kò béèrè ẹ̀mí gígùn* fún ara rẹ tàbí ọrọ̀ tàbí ikú* àwọn ọ̀tá rẹ, àmọ́ o béèrè òye láti máa gbọ́ àwọn ẹjọ́,+ 12 màá ṣe ohun tí o béèrè.+ Màá fún ọ ní ọkàn ọgbọ́n àti òye,+ tó fi jẹ́ pé bí kò ṣe sí ẹni tó dà bí rẹ ṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹni tó máa dà bí rẹ mọ́.+ 13 Yàtọ̀ síyẹn, màá fún ọ ní ohun tí o kò béèrè,+ àti ọrọ̀ àti ògo,+ tó fi jẹ́ pé kò ní sí ọba míì tó máa dà bí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ.+ 14 Tí o bá sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí ò ń pa àwọn ìlànà àti àṣẹ mi mọ́, bí Dáfídì bàbá rẹ ṣe rìn,+ màá tún fún ọ ní ẹ̀mí gígùn.”*+

15 Nígbà tí Sólómọ́nì jí, ó rí i pé àlá ni. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó dúró níwájú àpótí májẹ̀mú Jèhófà, ó rú àwọn ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀,+ ó sì se àsè fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

16 Ní àkókò yẹn, àwọn aṣẹ́wó méjì wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀. 17 Obìnrin àkọ́kọ́ sọ pé: “Jọ̀ọ́, olúwa mi, inú ilé kan náà ni èmi àti obìnrin yìí ń gbé, ó sì wà nílé nígbà tí mo bímọ. 18 Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn tí mo bímọ, obìnrin yìí náà bímọ. Àwa méjèèjì nìkan la wà nílé; kò sí ẹlòmíì tó wà pẹ̀lú wa. 19 Ọmọ obìnrin yìí kú ní òru, torí pé ó sùn lé e. 20 Torí náà, ó dìde láàárín òru, ó sì gbé ọmọ mi lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi nígbà tí ẹrúbìnrin rẹ ń sùn lọ́wọ́, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì tẹ́ ọmọ rẹ̀ tó ti kú sí àyà mi. 21 Nígbà tí mo dìde láàárọ̀ láti tọ́jú ọmọ mi, mo rí i pé ó ti kú. Torí náà, mo yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní ní àárọ̀ yẹn, mo sì rí i pé kì í ṣe ọmọ tí mo bí.” 22 Ṣùgbọ́n obìnrin kejì sọ pé: “Rárá, ọmọ tèmi ló wà láàyè, ọmọ tìrẹ ló kú!” Síbẹ̀ obìnrin àkọ́kọ́ ń sọ pé: “Rárá o, ọmọ tèmi ló wà láàyè, ọmọ tìrẹ ló kú.” Bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn jiyàn nìyẹn níwájú ọba.

23 Níkẹyìn, ọba sọ pé: “Ẹni tibí ń sọ pé, ‘Ọmọ tó wà láàyè ni ọmọ mi, èyí tó ti kú ni ọmọ tìrẹ!’ ẹni tọ̀hún sì ń sọ pé, ‘Rárá, ọmọ tìrẹ ló kú, ọmọ tèmi ló wà láàyè!’” 24 Ọba wá sọ pé: “Ẹ bá mi mú idà kan wá.” Torí náà, wọ́n mú idà kan wá fún ọba. 25 Ni ọba bá sọ pé: “Ẹ la ààyè ọmọ náà sí méjì, kí ẹ fún obìnrin àkọ́kọ́ ní ìdajì, kí ẹ sì fún èkejì ní ìdajì.” 26 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin tó ni ààyè ọmọ náà bẹ ọba torí pé ara ọmọ ta á. Ó sọ pé: “Jọ̀wọ́, olúwa mi! Ẹ fún un ní ààyè ọmọ náà! Ẹ má pa á!” Àmọ́ obìnrin kejì ń sọ pé: “Kò ní jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni kò ní jẹ́ tìrẹ! Ẹ là á sí méjì!” 27 Ni ọba bá dáhùn pé: “Ẹ fún obìnrin àkọ́kọ́ ní ààyè ọmọ náà! Ẹ má pa á, torí òun ni ìyá rẹ̀.”

28 Nítorí náà, gbogbo Ísírẹ́lì gbọ́ ìdájọ́ tí ọba ṣe, ohun tí ọba ṣe yìí sì jọ wọ́n lójú gidigidi,*+ torí wọ́n rí i pé ó ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́