ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ìrékọjá; Àjọyọ̀ Àkàrà Aláìwú (1-8)

      • Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (9-12)

      • Àjọyọ̀ Àtíbàbà (13-17)

      • Bí wọ́n ṣe máa yan àwọn onídàájọ́ (18-20)

      • Àwọn ohun tí wọn ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn (21, 22)

Diutarónómì 16:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún B15.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:14; Le 23:5; Nọ 9:2; 28:16; 1Kọ 5:7
  • +Ẹk 34:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1692, 1796

Diutarónómì 16:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:17
  • +Ẹk 12:5, 6; 2Kr 35:7
  • +1Ọb 8:29

Diutarónómì 16:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 13:3; Le 23:6; Nọ 28:17; 1Kọ 5:8
  • +Ẹk 12:33
  • +Ẹk 12:14; 13:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 1/2021,

Diutarónómì 16:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:15; 13:7
  • +Ẹk 12:10; 34:25

Diutarónómì 16:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:3, 6; Nọ 9:2, 3; Mt 26:19, 20

Diutarónómì 16:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:8; 2Kr 35:13
  • +Jo 2:13; 11:55

Diutarónómì 16:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:16; Le 23:8

Diutarónómì 16:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:16; 34:22; Le 23:15

Diutarónómì 16:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 28:26
  • +Di 16:17; 1Kọ 16:2; 2Kọ 8:12

Diutarónómì 16:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnubodè.”

  • *

    Tàbí “aláìlóbìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:5-7

Diutarónómì 16:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:7; Di 5:15

Diutarónómì 16:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:16; Le 23:34; Nọ 29:12; Di 31:10, 11; Jo 7:2

Diutarónómì 16:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:12; Ne 8:10, 17; Onw 5:18

Diutarónómì 16:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 23:36, 40; Ne 8:18
  • +Di 7:13; 28:8; 30:16
  • +Flp 4:4; 1Tẹ 5:16

Diutarónómì 16:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:14, 15
  • +Di 16:10
  • +Di 16:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2022, ojú ìwé 24

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1998, ojú ìwé 8-9

    9/15/1995, ojú ìwé 22

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 112

Diutarónómì 16:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 8:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 46

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 196-197

Diutarónómì 16:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “nínú gbogbo ẹnubodè rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:25, 26; Di 1:16; 2Kr 19:4, 5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 16:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:2; Le 19:15
  • +Di 1:17
  • +Ẹk 23:8; 1Sa 12:3; Onw 7:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2020, ojú ìwé 1-2

Diutarónómì 16:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 6:8

Diutarónómì 16:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:13

Diutarónómì 16:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:24; Le 26:1; Di 12:3

Àwọn míì

Diu. 16:1Ẹk 12:14; Le 23:5; Nọ 9:2; 28:16; 1Kọ 5:7
Diu. 16:1Ẹk 34:18
Diu. 16:2Mt 26:17
Diu. 16:2Ẹk 12:5, 6; 2Kr 35:7
Diu. 16:21Ọb 8:29
Diu. 16:3Ẹk 13:3; Le 23:6; Nọ 28:17; 1Kọ 5:8
Diu. 16:3Ẹk 12:33
Diu. 16:3Ẹk 12:14; 13:8, 9
Diu. 16:4Ẹk 12:15; 13:7
Diu. 16:4Ẹk 12:10; 34:25
Diu. 16:6Ẹk 12:3, 6; Nọ 9:2, 3; Mt 26:19, 20
Diu. 16:7Ẹk 12:8; 2Kr 35:13
Diu. 16:7Jo 2:13; 11:55
Diu. 16:8Ẹk 12:16; Le 23:8
Diu. 16:9Ẹk 23:16; 34:22; Le 23:15
Diu. 16:10Nọ 28:26
Diu. 16:10Di 16:17; 1Kọ 16:2; 2Kọ 8:12
Diu. 16:11Di 12:5-7
Diu. 16:12Ẹk 3:7; Di 5:15
Diu. 16:13Ẹk 23:16; Le 23:34; Nọ 29:12; Di 31:10, 11; Jo 7:2
Diu. 16:14Di 12:12; Ne 8:10, 17; Onw 5:18
Diu. 16:15Le 23:36, 40; Ne 8:18
Diu. 16:15Di 7:13; 28:8; 30:16
Diu. 16:15Flp 4:4; 1Tẹ 5:16
Diu. 16:16Ẹk 23:14, 15
Diu. 16:16Di 16:10
Diu. 16:16Di 16:13
Diu. 16:172Kọ 8:12
Diu. 16:18Ẹk 18:25, 26; Di 1:16; 2Kr 19:4, 5
Diu. 16:19Ẹk 23:2; Le 19:15
Diu. 16:19Di 1:17
Diu. 16:19Ẹk 23:8; 1Sa 12:3; Onw 7:7
Diu. 16:20Mik 6:8
Diu. 16:21Ẹk 34:13
Diu. 16:22Ẹk 23:24; Le 26:1; Di 12:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 16:1-22

Diutarónómì

16 “Máa rántí oṣù Ábíbù,* kí o sì máa ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ torí pé oṣù Ábíbù ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ mú ọ kúrò ní Íjíbítì ní òru.+ 2 Kí o fi ẹran Ìrékọjá rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ látinú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran,+ ní ibi tí Jèhófà yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+ 3 O ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó ní ìwúkàrà pẹ̀lú rẹ̀;+ ọjọ́ méje ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, ó jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, torí pé ẹ kánjú kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Máa ṣe èyí ní gbogbo ìgbà tí o bá fi wà láàyè kí o lè máa rántí ọjọ́ tí o kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 4 Kò gbọ́dọ̀ sí àpòrọ́ kíkan lọ́wọ́ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ rẹ fún ọjọ́ méje,+ bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú ẹran tí o bá fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ àkọ́kọ́ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ kù di ọjọ́ kejì.+ 5 O ò gbọ́dọ̀ fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ nínú èyí tó bá kàn wù ọ́ nínú àwọn ìlú tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ. 6 Ṣùgbọ́n ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà ni kí o ti ṣe é. Kí o fi ẹran Ìrékọjá náà rúbọ ní ìrọ̀lẹ́, gbàrà tí oòrùn bá wọ̀,+ ní déédéé àkókò tí o jáde kúrò ní Íjíbítì. 7 Kí o sè é, kí o sì jẹ ẹ́+ ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn,+ kí o wá pa dà sí àgọ́ rẹ tí ilẹ̀ bá mọ́. 8 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí o fi jẹ búrẹ́dì aláìwú, àpéjọ ọlọ́wọ̀ sì máa wà fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ọjọ́ keje. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan.+

9 “Kí o ka ọ̀sẹ̀ méje. Ìgbà tí o bá kọ́kọ́ ki dòjé bọ ọkà tó wà ní ìdúró ni kí o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọ̀sẹ̀ méje náà.+ 10 Kí o wá fi ọrẹ àtinúwá tí o mú wá ṣe Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o mú un wá bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ṣe bù kún ọ tó.+ 11 Kí o sì máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* rẹ, àjèjì, ọmọ aláìníbaba* àti opó, tí wọ́n wà láàárín rẹ, ní ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn pé kí orúkọ rẹ̀ máa wà.+ 12 Rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì,+ kí o máa pa àwọn ìlànà yìí mọ́, kí o sì máa tẹ̀ lé e.

13 “Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ nígbà tí o bá kó ọkà rẹ jọ láti ibi ìpakà, tí o sì mú òróró àti wáìnì jáde láti ibi ìfúntí rẹ. 14 Máa yọ̀ nígbà àjọyọ̀ rẹ,+ ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ, ọmọbìnrin rẹ, ẹrúkùnrin rẹ, ẹrúbìnrin rẹ, ọmọ Léfì, àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó, tí wọ́n wà nínú àwọn ìlú rẹ. 15 Ọjọ́ méje ni kí o fi ṣe àjọyọ̀+ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní ibi tí Jèhófà bá yàn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo ohun tí o bá kórè àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,+ wàá sì máa láyọ̀ nígbà gbogbo.+

16 “Kí gbogbo ọkùnrin rẹ máa fara hàn níwájú Jèhófà Ọlọ́run lẹ́ẹ̀mẹta lọ́dún ní ibi tó bá yàn: ní Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú,+ Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀+ àti Àjọyọ̀ Àtíbàbà,+ kí ẹnì kankan nínú wọn má sì wá síwájú Jèhófà lọ́wọ́ òfo. 17 Kí kálukú yín mú ẹ̀bùn wá bí Jèhófà Ọlọ́run yín bá ṣe bù kún yín tó.+

18 “Kí o yan àwọn onídàájọ́+ àti àwọn olórí fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ìlú* tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ, kí wọ́n sì máa fi òdodo ṣèdájọ́ àwọn èèyàn náà. 19 O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dájọ́,+ o ò gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú,+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, torí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń dí ọlọ́gbọ́n lójú,+ ó sì máa ń mú kí olódodo yí ọ̀rọ̀ po. 20 Máa ṣèdájọ́ òdodo, àní ìdájọ́ òdodo ni kí o máa ṣe,+ kí o lè máa wà láàyè, kí o sì lè gba ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fún ọ.

21 “O ò gbọ́dọ̀ gbin igi èyíkéyìí láti fi ṣe òpó òrìṣà*+ sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí o ṣe fún ara rẹ.

22 “O ò sì gbọ́dọ̀ ṣe ọwọ̀n òrìṣà fún ara rẹ,+ torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́