ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àwọn èèyàn náà ń ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe (1-7)

      • Ǹjẹ́ ọgbọ́n lè wà láìsí ọ̀rọ̀ Jèhófà? (8-17)

      • Jeremáyà kédàárò lórí ìṣubú Júdà (18-22)

        • “Ṣé kò sí básámù ní Gílíádì ni?” (22)

Jeremáyà 8:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:19; 2Ọb 17:16; 21:1, 3; Jer 19:13; Isk 8:16; Sef 1:4, 5
  • +Jer 16:4

Jeremáyà 8:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:3

Jeremáyà 8:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:1

Jeremáyà 8:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìgbà tí àkókò bá tó.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ẹyẹ òfú.”

  • *

    Tàbí “ṣí lọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 6 2016 ojú ìwé 8-9

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2002, ojú ìwé 32

Jeremáyà 8:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

  • *

    Tàbí “àwọn akọ̀wé.”

  • *

    Tàbí “gègé.”

  • *

    Tàbí “irọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 8:1

Jeremáyà 8:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 29:14

Jeremáyà 8:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:30; Sef 1:13
  • +Ais 56:11; Isk 33:31; Mik 3:11
  • +Jer 5:31; 6:12-15; 27:9; Ida 2:14; Isk 22:28

Jeremáyà 8:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọgbẹ́.”

  • *

    Tàbí “fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:16, 17; Isk 13:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé,

    3/2017, ojú ìwé 1

Jeremáyà 8:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 3:3
  • +Jer 23:12

Jeremáyà 8:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:5
  • +Jer 9:15; 23:15; Ida 3:19

Jeremáyà 8:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:10; 14:19

Jeremáyà 8:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:19, 20; 14:17

Jeremáyà 8:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òróró ìtura.”

  • *

    Tàbí “oníṣègùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 37:25
  • +Jer 30:12, 13
  • +Jer 30:17; 33:4, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2010, ojú ìwé 21-22

    Jeremáyà, ojú ìwé 135

Àwọn míì

Jer. 8:2Di 4:19; 2Ọb 17:16; 21:1, 3; Jer 19:13; Isk 8:16; Sef 1:4, 5
Jer. 8:2Jer 16:4
Jer. 8:5Jer 5:3
Jer. 8:6Jer 5:1
Jer. 8:7Ais 1:3
Jer. 8:8Ais 8:1
Jer. 8:9Ais 29:14
Jer. 8:10Di 28:30; Sef 1:13
Jer. 8:10Ais 56:11; Isk 33:31; Mik 3:11
Jer. 8:10Jer 5:31; 6:12-15; 27:9; Ida 2:14; Isk 22:28
Jer. 8:11Jer 23:16, 17; Isk 13:10
Jer. 8:12Jer 3:3
Jer. 8:12Jer 23:12
Jer. 8:14Jer 4:5
Jer. 8:14Jer 9:15; 23:15; Ida 3:19
Jer. 8:15Jer 4:10; 14:19
Jer. 8:21Jer 4:19, 20; 14:17
Jer. 8:22Jẹ 37:25
Jer. 8:22Jer 30:12, 13
Jer. 8:22Jer 30:17; 33:4, 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 8:1-22

Jeremáyà

8 Jèhófà sọ pé: “Ní àkókò yẹn, wọ́n á kó egungun àwọn ọba Júdà àti egungun àwọn ìjòyè rẹ̀, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì pẹ̀lú egungun àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù jáde kúrò nínú sàréè wọn. 2 A ó dà wọ́n síta lábẹ́ oòrùn, òṣùpá àti lábẹ́ gbogbo ọmọ ogun ọ̀run tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n jọ́sìn, tí wọ́n tẹ̀ lé, tí wọ́n wá, tí wọ́n sì forí balẹ̀ fún.+ A ò ní kó wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní sin wọ́n. Wọn á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.”+

3 “Àwọn tó bá sì ṣẹ́ kù lára ìdílé búburú yìí á yan ikú dípò ìyè ní gbogbo ibi tí mo bá fọ́n wọn ká sí,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

4 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Tí wọ́n bá ṣubú, ṣé wọn ò ní dìde mọ́ ni?

Tí ẹnì kìíní bá sì yí pa dà, ṣé ẹnì kejì náà kò ní yí pa dà ni?

 5 Kí ló dé tí àwọn èèyàn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ò fi jáwọ́ nínú ìwà àìṣòótọ́ tí wọ́n ń hù sí mi?

Wọn ò jáwọ́ nínú ẹ̀tàn;

Wọn ò sì yí pa dà.+

 6 Mo fiyè sí wọn, mo sì ń fetí sílẹ̀, àmọ́ bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ kò dáa.

Kò sí ẹnì kankan tó ronú pìwà dà ìwà burúkú rẹ̀ tàbí kó sọ pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’+

Kálukú wọn ń pa dà lọ ṣe ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe, bí ẹṣin tó ń já lọ sójú ogun.

 7 Kódà ẹyẹ àkọ̀ tó ń fò lójú ọ̀run mọ àkókò rẹ̀;*

Oriri àti ẹyẹ olófèéèré àti ẹ̀gà* kì í yẹ àkókò tí wọ́n máa pa dà.*

Àmọ́ àwọn èèyàn mi ò mọ ìdájọ́ Jèhófà.”’+

 8 ‘Báwo ni ẹ ṣe lè sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ni wá, a sì ní òfin* Jèhófà”?

Nígbà tó jẹ́ pé, kìkì irọ́ ni àwọn akọ̀wé òfin* ń fi kálàmù* èké*+ wọn kọ.

 9 Ojú ti àwọn ọlọ́gbọ́n.+

Àyà wọn já, a ó sì mú wọn.

Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Jèhófà,

Ọgbọ́n wo sì ni wọ́n ní?

10 Torí náà, màá fi ìyàwó wọn fún àwọn ọkùnrin míì,

Màá fi oko wọn fún àwọn tó máa gbà á;+

Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+

Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+

11 Wọ́n sì ń wo àárẹ̀* ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi sàn láàbọ̀,* wọ́n ń sọ pé,

“Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!”

Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+

12 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?

Ojú kì í tì wọ́n!

Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+

Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.

Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,’+ ni Jèhófà wí.

13 ‘Nígbà tí mo bá kó wọn jọ, màá pa wọ́n run,’ ni Jèhófà wí.

‘Kò ní sí èso tó máa ṣẹ́ kù lórí igi àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí èso kankan lórí igi ọ̀pọ̀tọ́, àwọn ewé rẹ̀ yóò sì rọ.

Wọ́n á pàdánù àwọn ohun tí mo fún wọn.’”

14 “Kí nìdí tí a fi jókòó síbí?

Ẹ jẹ́ ká kóra jọ, ká wọnú àwọn ìlú olódi,+ ká sì ṣègbé síbẹ̀.

Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wa máa pa wá run,

Ó fún wa ní omi tó ní májèlé mu,+

Torí pé a ti ṣẹ Jèhófà.

15 À ń retí àlàáfíà, àmọ́ ohun rere kan ò dé,

À ń retí àkókò ìwòsàn, àmọ́ ìpayà là ń rí!+

16 À ń gbọ́ bí àwọn ẹṣin wọn ṣe ń fọn imú láti Dánì.

Nígbà tí àwọn akọ ẹṣin rẹ̀ bá yán,

Ìró wọn á mú gbogbo ilẹ̀ náà mì tìtì.

Wọ́n wọlé wá, wọ́n sì jẹ ilẹ̀ náà run àti gbogbo ohun tó wà lórí rẹ̀,

Ìlú náà àti àwọn tó ń gbé inú rẹ̀.”

17 “Wò ó, màá rán àwọn ejò sí àárín yín,

Àwọn ejò olóró tí kò ṣeé tù lójú,

Ó dájú pé wọ́n á bù yín ṣán,” ni Jèhófà wí.

18 Ẹ̀dùn ọkàn mi kò ṣeé wò sàn;

Ọkàn mi ń ṣàárẹ̀.

19 Igbe ìrànlọ́wọ́ wá láti ilẹ̀ tó jìnnà

Látọ̀dọ̀ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi pé:

“Ṣé kò sí Jèhófà ní Síónì ni?

Àbí ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ ni?”

“Kí ló dé tí wọ́n fi fi ère gbígbẹ́ wọn mú mi bínú,

Pẹ̀lú àwọn ọlọ́run àjèjì wọn tí kò ní láárí?”

20 “Ìkórè ti kọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí,

Ṣùgbọ́n a kò tíì rí ìgbàlà!”

21 Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nítorí àárẹ̀ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi;+

Ìbànújẹ́ sorí mi kodò.

Àyà fò mí torí ìbẹ̀rù.

22 Ṣé kò sí básámù* ní Gílíádì+ ni?

Àbí ṣé kò sí oníwòsàn* níbẹ̀ ni?+

Kí ló wá dé tí ara ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi kò fi tíì yá?+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́