ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àwọn èèyàn náà kò gba ìbáwí Jèhófà (1-13)

      • Ìparun ń bọ̀, àmọ́ kì í ṣe ìparun pátápátá (14-19)

      • Jèhófà pe àwọn èèyàn náà wá jíhìn (20-31)

Jeremáyà 5:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 22:29; Mik 7:2

Jeremáyà 5:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:1

Jeremáyà 5:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọn ò ṣàárẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 16:9
  • +2Kr 28:20-22; Jer 2:30
  • +Sek 7:11
  • +Sm 50:17; Ais 42:24, 25; Isk 3:7; Sef 3:2

Jeremáyà 5:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọ̀já.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 3:1

Jeremáyà 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 9:6; Ais 59:12; Isk 23:19

Jeremáyà 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 23:6, 7; Jer 2:11; 12:16; Sef 1:4, 5

Jeremáyà 5:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ń lé aya ọmọnìkejì rẹ̀ kiri.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 22:11

Jeremáyà 5:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:25; Jer 9:9; 44:22; Na 1:2

Jeremáyà 5:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ilẹ̀ onípele.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:44; Jer 46:28

Jeremáyà 5:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:8; Jer 3:20; Ho 5:7; 6:7

Jeremáyà 5:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Kò sí níbì kankan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16; Ais 28:15
  • +Jer 23:17

Jeremáyà 5:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:9
  • +Jer 23:29

Jeremáyà 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:15; 4:16; 25:9; Isk 7:24; Hab 1:6
  • +Di 28:49, 50

Jeremáyà 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:16

Jeremáyà 5:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:27

Jeremáyà 5:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:27; 28:48; 29:24, 25; 2Kr 7:21, 22

Jeremáyà 5:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀yin òmùgọ̀ tí kò ní ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:22
  • +Ais 59:10
  • +Ais 6:9; Isk 12:2; Mt 13:13

Jeremáyà 5:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 38:8, 11; Sm 33:7; Owe 8:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2004, ojú ìwé 8

Jeremáyà 5:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 95:10; Jer 11:8

Jeremáyà 5:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 11:14

Jeremáyà 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:23, 24; Jer 3:3

Jeremáyà 5:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 8:5; Mik 6:11, 12

Jeremáyà 5:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:23
  • +Sm 82:2

Jeremáyà 5:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Jeremáyà 5:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:14; Ida 2:14; Isk 13:6
  • +Ais 30:10; Jo 3:19

Àwọn míì

Jer. 5:1Isk 22:29; Mik 7:2
Jer. 5:2Ais 48:1
Jer. 5:32Kr 16:9
Jer. 5:32Kr 28:20-22; Jer 2:30
Jer. 5:3Sek 7:11
Jer. 5:3Sm 50:17; Ais 42:24, 25; Isk 3:7; Sef 3:2
Jer. 5:5Mik 3:1
Jer. 5:6Ẹsr 9:6; Ais 59:12; Isk 23:19
Jer. 5:7Joṣ 23:6, 7; Jer 2:11; 12:16; Sef 1:4, 5
Jer. 5:8Isk 22:11
Jer. 5:9Le 26:25; Jer 9:9; 44:22; Na 1:2
Jer. 5:10Le 26:44; Jer 46:28
Jer. 5:11Ais 48:8; Jer 3:20; Ho 5:7; 6:7
Jer. 5:122Kr 36:15, 16; Ais 28:15
Jer. 5:12Jer 23:17
Jer. 5:14Jer 1:9
Jer. 5:14Jer 23:29
Jer. 5:15Jer 1:15; 4:16; 25:9; Isk 7:24; Hab 1:6
Jer. 5:15Di 28:49, 50
Jer. 5:17Le 26:16
Jer. 5:18Jer 4:27
Jer. 5:19Di 4:27; 28:48; 29:24, 25; 2Kr 7:21, 22
Jer. 5:21Jer 4:22
Jer. 5:21Ais 59:10
Jer. 5:21Ais 6:9; Isk 12:2; Mt 13:13
Jer. 5:22Job 38:8, 11; Sm 33:7; Owe 8:29
Jer. 5:23Sm 95:10; Jer 11:8
Jer. 5:24Di 11:14
Jer. 5:25Di 28:23, 24; Jer 3:3
Jer. 5:27Emọ 8:5; Mik 6:11, 12
Jer. 5:28Ais 1:23
Jer. 5:28Sm 82:2
Jer. 5:31Jer 14:14; Ida 2:14; Isk 13:6
Jer. 5:31Ais 30:10; Jo 3:19
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 5:1-31

Jeremáyà

5 Ẹ lọ káàkiri àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù.

Ẹ wò yí ká, kí ẹ sì kíyè sí i.

Ẹ wo àwọn ojúde rẹ̀

Bóyá ẹ lè rí ẹnì kan tó ń ṣe ohun tó tọ́,+

Ẹni tó fẹ́ máa ṣòótọ́,

Màá sì dárí jì í.

 2 Bí wọ́n bá tiẹ̀ sọ pé: “Bí Jèhófà ti wà láàyè!”

Irọ́ ni wọ́n ṣì máa pa.+

 3 Jèhófà, ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn olóòótọ́ ni ojú rẹ ń wò?+

O lù wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò mọ̀ ọ́n lára.*

O pa wọ́n run, àmọ́ wọn ò gba ìbáwí.+

Wọ́n mú ojú wọn le ju àpáta lọ,+

Wọn kò sì yí pa dà.+

 4 Ṣùgbọ́n mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ó dájú pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan.

Wọ́n hùwà òmùgọ̀, torí pé wọn ò mọ ọ̀nà Jèhófà,

Wọn ò mọ òfin Ọlọ́run wọn.

 5 Màá lọ sọ́dọ̀ àwọn olókìkí èèyàn, màá sì bá wọn sọ̀rọ̀,

Torí wọ́n á ti mọ ọ̀nà Jèhófà,

Wọ́n á ti mọ òfin Ọlọ́run wọn.+

Àmọ́ gbogbo wọn ti ṣẹ́ àjàgà

Wọ́n sì ti fa ìdè* já.”

 6 Ìdí nìyẹn tí kìnnìún inú igbó fi bẹ́ mọ́ wọn,

Tí ìkookò inú aṣálẹ̀ tó tẹ́jú ń pa wọ́n jẹ,

Tí àmọ̀tẹ́kùn sì lúgọ ní àwọn ìlú wọn.

Gbogbo ẹni tó ń jáde láti inú wọn ló máa fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.

Torí pé ìṣìnà wọn pọ̀;

Ìwà àìṣòótọ́ wọn sì pọ̀.+

 7 Báwo ni mo ṣe lè dárí ohun tí o ṣe yìí jì ọ́?

Àwọn ọmọ rẹ ti fi mí sílẹ̀,

Wọ́n sì ń fi ohun tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.+

Gbogbo ohun tí wọ́n fẹ́ ni mo fún wọn,

Ṣùgbọ́n wọn ò jáwọ́ nínú àgbèrè,

Wọ́n sì ń rọ́ lọ sí ilé aṣẹ́wó.

 8 Wọ́n dà bí àwọn ẹṣin tí ara wọn ti wà lọ́nà láti gùn,

Kálukú wọn ń yán sí aya ọmọnìkejì rẹ̀.*+

 9 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.

“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?”+

10 “Ẹ wá sí pooro* oko àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì bà á jẹ́,

Ṣùgbọ́n ẹ má pa á run.+

Ẹ gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ,

Nítorí wọn kì í ṣe ti Jèhófà.

11 Nítorí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà

Ti hùwà àìṣòótọ́ sí mi gan-an,” ni Jèhófà wí.+

12 “Wọ́n ti kọ Jèhófà, wọ́n sì ń sọ pé,

‘Kò ní ṣe nǹkan kan.*+

Àjálù kankan kò ní bá wa;

A kò ní rí idà tàbí ìyàn.’+

13 Àwọn wòlíì jẹ́ àgbá òfìfo,

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sì sí lẹ́nu wọn.

Kí ó rí bẹ́ẹ̀ fún wọn!”

14 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

“Nítorí ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ,

Wò ó, màá sọ ọ̀rọ̀ mi di iná ní ẹnu rẹ,+

Àwọn èèyàn yìí yóò sì dà bí igi,

Yóò sì jó wọn run.”+

15 “Wò ó, màá mú orílẹ̀-èdè kan láti ibi tó jìnnà wá bá yín, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,”+ ni Jèhófà wí.

“Orílẹ̀-èdè tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni.

Orílẹ̀-èdè àtijọ́ ni,

Orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò gbọ́ èdè rẹ̀,

Tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò lè yé ọ.+

16 Apó wọn dà bíi sàréè tó la ẹnu sílẹ̀;

Jagunjagun ni gbogbo wọn.

17 Wọ́n á jẹ irè oko rẹ àti oúnjẹ rẹ.+

Wọ́n á pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ.

Wọ́n á jẹ àwọn agbo ẹran rẹ àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran rẹ.

Wọ́n á jẹ àjàrà rẹ àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.

Wọ́n á fi idà pa ìlú olódi rẹ tí o gbẹ́kẹ̀ lé run.”

18 “Kódà ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí, “Mi ò ní pa yín run pátápátá.+ 19 Tí wọ́n bá sì béèrè pé, ‘Kí ló dé tí Jèhófà Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo nǹkan yìí sí wa?’ kí o sọ fún wọn pé, ‘Bí ẹ ṣe fi mí sílẹ̀ láti sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ó sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ kan tí kì í ṣe tiyín.’”+

20 Ẹ kéde èyí ní ilé Jékọ́bù,

Ẹ sì polongo rẹ̀ ní Júdà pé:

21 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin òmùgọ̀ àti aláìlọ́gbọ́n:*+

Wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè ríran;+

Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ràn.+

22 ‘Ṣé ẹ kò bẹ̀rù mi ni?’ ni Jèhófà wí,

‘Ṣé kò yẹ kí ẹ̀rù bà yín níwájú mi?

Èmi ni mo fi iyanrìn pààlà òkun,

Ó jẹ́ ìlànà tó wà títí láé tí òkun kò lè ré kọjá.

Bí àwọn ìgbì rẹ̀ tiẹ̀ ń bì síwá-sẹ́yìn, wọn kò lè borí;

Bí wọ́n tiẹ̀ pariwo, síbẹ̀, wọn kò lè ré e kọjá.+

23 Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn yìí jẹ́ alágídí ọkàn, wọ́n sì ya ọlọ̀tẹ̀;

Wọ́n fi ọ̀nà mi sílẹ̀, wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ.+

24 Wọn ò sì sọ lọ́kàn wọn pé:

“Ẹ jẹ́ ká bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run wa,

Ẹni tó ń fúnni ní òjò ní àsìkò rẹ̀,

Òjò ìgbà ìkórè àti òjò ìgbà ìrúwé,

Ẹni tí kò jẹ́ kí àwọn ọ̀sẹ̀ ìkórè wa yẹ̀.”+

25 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín kò jẹ́ kí gbogbo nǹkan yìí wáyé;

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín sì ti gba ohun rere kúrò lọ́wọ́ yín.+

26 Nítorí àwọn èèyàn burúkú wà láàárín àwọn èèyàn mi.

Wọ́n ń wò bí àwọn pẹyẹpẹyẹ tó lúgọ.

Wọ́n ń dẹ pańpẹ́ ikú.

Èèyàn ni wọ́n ń mú.

27 Bí àgò tí ẹyẹ kún inú rẹ̀,

Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀tàn kún ilé wọn.+

Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi di alágbára tí wọ́n sì lọ́rọ̀.

28 Wọ́n ti sanra, ara wọn sì ń dán;

Iṣẹ́ ibi kún ọwọ́ wọn fọ́fọ́.

Wọn kò gba ẹjọ́ ọmọ aláìníbaba rò,+

Kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí;

Wọ́n ò fi òdodo dá ẹjọ́ àwọn aláìní.’”+

29 “Ǹjẹ́ kò yẹ kí n pè wọ́n wá jíhìn nítorí nǹkan wọ̀nyí?” ni Jèhófà wí.

“Ǹjẹ́ kò yẹ kí n* gbẹ̀san lára orílẹ̀-èdè tó ṣe irú èyí?

30 Ohun burúkú àti ẹ̀rù ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà:

31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́,+

Àwọn àlùfáà sì ń fi àṣẹ wọn tẹ àwọn èèyàn lórí ba.

Àwọn èèyàn mi sì fẹ́ ẹ bẹ́ẹ̀.+

Àmọ́, kí lẹ máa ṣe nígbà tí òpin bá dé?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́