ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ọ̀tá máa tó dó ti Jerúsálẹ́mù (1-9)

      • Ìbínú Jèhófà lórí Jerúsálẹ́mù (10-21)

        • Wọ́n ń sọ pé “Àlàáfíà!” nígbà tí kò sí àlàáfíà (14)

      • Ọ̀tá ya wọ ilẹ̀ náà láti àríwá (22-26)

      • Jeremáyà máa di ẹni tó ń yọ́ wúrà àti fàdákà mọ́ (27-30)

Jeremáyà 6:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:5
  • +2Kr 11:5, 6; Emọ 1:1
  • +Jer 1:14; 10:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2007, ojú ìwé 14

Jeremáyà 6:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 3:16

Jeremáyà 6:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:1
  • +Jer 4:16, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22-23

Jeremáyà 6:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ ya ara yín sí mímọ́.”

Jeremáyà 6:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:17, 19; Emọ 2:5

Jeremáyà 6:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 21:21, 22
  • +2Ọb 21:16; Isk 7:23

Jeremáyà 6:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kòtò omi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 7:11; Mik 2:2

Jeremáyà 6:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 23:18
  • +Le 26:34; Jer 9:11

Jeremáyà 6:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “pèéṣẹ́.”

Jeremáyà 6:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Wọn ò dádọ̀dọ́ etí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:10; Iṣe 7:51
  • +2Kr 36:15, 16; Jer 20:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Jeremáyà 6:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn tí wọ́n lọ́jọ́ lórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 20:9
  • +Jer 18:21
  • +Isk 9:6

Jeremáyà 6:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:30; Jer 8:10; Ida 5:11; Sef 1:13

Jeremáyà 6:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 22:12
  • +Jer 2:8; 8:10-12; 23:11; Mik 3:5, 11; Sef 3:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé,

    3/2017, ojú ìwé 1

Jeremáyà 6:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọgbẹ́.”

  • *

    Tàbí “fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:13; 23:16, 17; Isk 13:10; 1Tẹ 5:3

Jeremáyà 6:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 3:3

Jeremáyà 6:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:21
  • +Jer 18:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 10

    11/1/2005, ojú ìwé 23-25

Jeremáyà 6:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:4; Isk 3:17; Hab 2:1
  • +Ais 58:1
  • +Sek 7:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 8/2017, ojú ìwé 2

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 122-123

Jeremáyà 6:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìtọ́ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:25, 26; Da 9:12

Jeremáyà 6:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Esùsú tó ń ta sánsán.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:11; 66:3; Jer 7:21; Emọ 5:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2006, ojú ìwé 5

Jeremáyà 6:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:17; Ida 2:21

Jeremáyà 6:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:14; 25:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé,

    3/2017, ojú ìwé 2

Jeremáyà 6:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọrun.”

  • *

    Tàbí “ẹ̀ṣín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hab 1:8

Jeremáyà 6:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ìrora ìrọbí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 21:7
  • +Jer 4:31

Jeremáyà 6:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:8
  • +Ida 1:2, 16
  • +Jer 15:8

Jeremáyà 6:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Jeremáyà.

Jeremáyà 6:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:1; 48:4; Jer 5:23
  • +Jer 9:4

Jeremáyà 6:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ohun tí àwọn alágbẹ̀dẹ fi ń fẹ́ná.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 9:7; Isk 22:20
  • +Isk 24:13

Jeremáyà 6:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:19; Ida 5:22

Àwọn míì

Jer. 6:1Jer 4:5
Jer. 6:12Kr 11:5, 6; Emọ 1:1
Jer. 6:1Jer 1:14; 10:22
Jer. 6:2Ais 3:16
Jer. 6:32Ọb 25:1
Jer. 6:3Jer 4:16, 17
Jer. 6:52Kr 36:17, 19; Emọ 2:5
Jer. 6:6Isk 21:21, 22
Jer. 6:62Ọb 21:16; Isk 7:23
Jer. 6:7Isk 7:11; Mik 2:2
Jer. 6:8Isk 23:18
Jer. 6:8Le 26:34; Jer 9:11
Jer. 6:10Ais 6:10; Iṣe 7:51
Jer. 6:102Kr 36:15, 16; Jer 20:8
Jer. 6:11Jer 20:9
Jer. 6:11Jer 18:21
Jer. 6:11Isk 9:6
Jer. 6:12Di 28:30; Jer 8:10; Ida 5:11; Sef 1:13
Jer. 6:13Isk 22:12
Jer. 6:13Jer 2:8; 8:10-12; 23:11; Mik 3:5, 11; Sef 3:4
Jer. 6:14Jer 14:13; 23:16, 17; Isk 13:10; 1Tẹ 5:3
Jer. 6:15Jer 3:3
Jer. 6:16Ais 30:21
Jer. 6:16Jer 18:15
Jer. 6:17Jer 25:4; Isk 3:17; Hab 2:1
Jer. 6:17Ais 58:1
Jer. 6:17Sek 7:11
Jer. 6:19Di 4:25, 26; Da 9:12
Jer. 6:20Ais 1:11; 66:3; Jer 7:21; Emọ 5:21
Jer. 6:212Kr 36:17; Ida 2:21
Jer. 6:22Jer 1:14; 25:9
Jer. 6:23Hab 1:8
Jer. 6:24Isk 21:7
Jer. 6:24Jer 4:31
Jer. 6:26Jer 4:8
Jer. 6:26Ida 1:2, 16
Jer. 6:26Jer 15:8
Jer. 6:28Ais 30:1; 48:4; Jer 5:23
Jer. 6:28Jer 9:4
Jer. 6:29Jer 9:7; Isk 22:20
Jer. 6:29Isk 24:13
Jer. 6:30Jer 14:19; Ida 5:22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 6:1-30

Jeremáyà

6 Ẹ wá ibi ààbò kúrò ní Jerúsálẹ́mù, ẹ̀yin ọmọ Bẹ́ńjámínì.

Ẹ fun ìwo+ ní Tékóà;+

Ẹ sì gbé àmì iná sókè lórí Bẹti-hákérémù!

Torí pé àjálù ń rọ̀ dẹ̀dẹ̀ láti àríwá, àjálù ńlá.+

 2 Ọmọbìnrin Síónì jọ arẹwà obìnrin tó gbẹgẹ́.+

 3 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti agbo ẹran wọn yóò wá.

Wọ́n á pa àgọ́ wọn yí i ká,+

Kálukú wọn á máa kó agbo ẹran wọn jẹ̀.+

 4 “Ẹ múra* láti bá a jagun!

Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká bá a jà ní ọ̀sán gangan!”

“A gbé! Nítorí ọjọ́ ti lọ,

Ilẹ̀ sì ti ń ṣú.”

 5 “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ ká bá a jà ní òru

Ká sì pa àwọn ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò run.”+

 6 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

“Gé igi lulẹ̀, kí o sì mọ òkìtì láti dó ti Jerúsálẹ́mù.+

Ìlú tí ó gbọ́dọ̀ jíhìn ni;

Ìnilára nìkan ló wà nínú rẹ̀.+

 7 Bí omi tútù ṣe máa ń wà nínú àmù,*

Bẹ́ẹ̀ ni ìwà burúkú ṣe wà nínú ìlú yìí.

Ìwà ipá àti ìparun ni ìròyìn tí à ń gbọ́ nínú rẹ̀;+

Àìsàn àti àjálù ni mò ń rí níbẹ̀ nígbà gbogbo.

 8 Gba ìkìlọ̀, ìwọ Jerúsálẹ́mù, kí n* má bàa bínú fi ọ́ sílẹ̀;+

Màá sọ ọ́ di ahoro, ilẹ̀ tí kò sí ẹni tó ń gbé ibẹ̀.”+

 9 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

“Wọ́n á fara balẹ̀ ṣa* èyí tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì bí èso àjàrà tó kẹ́yìn.

Pa dà lọ ṣà wọ́n bí ẹni tó ń ṣa èso àjàrà lórí àwọn àjàrà.”

10 “Ta ló yẹ kí n bá sọ̀rọ̀, kí n sì kìlọ̀ fún?

Ta ló máa gbọ́?

Wò ó! Etí wọn ti di,* tí wọn kò fi lè fetí sílẹ̀.+

Wò ó! Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti di ohun tí wọ́n fi ń ṣe ẹlẹ́yà;+

Inú wọn ò sì dùn sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

11 Torí náà, ìbínú Jèhófà ti kún inú mi,

Ara mi ò sì gbà á mọ́.”+

“Dà á sórí ọmọ tó wà lójú ọ̀nà,+

Sórí àwọn àwùjọ ọ̀dọ́kùnrin tó kóra jọ.

Gbogbo wọn ni ọwọ́ máa tẹ̀, láìyọ ọkùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀,

Àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú àwọn arúgbó.*+

12 Ilé wọn máa di ti àwọn ẹlòmíì,

Títí kan àwọn oko wọn àti ìyàwó wọn.+

Torí màá na ọwọ́ mi sí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà,” ni Jèhófà wí.

13 “Látorí ẹni kékeré títí dórí ẹni ńlá, kálukú wọn ń jẹ èrè tí kò tọ́;+

Látorí wòlíì títí dórí àlùfáà, kálukú wọn ń lu jìbìtì.+

14 Wọ́n sì ń wo àárẹ̀* àwọn èèyàn mi sàn láàbọ̀,* wọ́n ń sọ pé,

‘Àlàáfíà wà! Àlàáfíà wà!’

Nígbà tí kò sí àlàáfíà.+

15 Ǹjẹ́ ojú tì wọ́n nítorí àwọn ohun ìríra tí wọ́n ṣe?

Ojú kì í tì wọ́n!

Àní wọn ò tiẹ̀ lójútì rárá!+

Torí náà, wọ́n á ṣubú láàárín àwọn tó ti ṣubú.

Nígbà tí mo bá fìyà jẹ wọ́n, wọ́n á kọsẹ̀,” ni Jèhófà wí.

16 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Ẹ dúró ní oríta, kí ẹ sì wò.

Ẹ béèrè àwọn ọ̀nà àtijọ́,

Ẹ béèrè ibi tí ọ̀nà tó dára wà, kí ẹ sì máa rìn ín,+

Kí ẹ* lè rí ìsinmi.”

Ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé: “A ò ní rin ọ̀nà náà.”+

17 “Mo sì yan àwọn olùṣọ́+ tí wọ́n sọ pé,

‘Ẹ fetí sí ìró ìwo!’”+

Àmọ́ wọ́n sọ pé: “A ò ní fetí sí i.”+

18 “Torí náà, ẹ gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè!

Kí o sì mọ̀, ìwọ àpéjọ,

Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn.

19 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ayé!

Màá mú àjálù bá àwọn èèyàn yìí+

Wọ́n á jèrè èrò ibi wọn,

Torí wọn kò fiyè sí ọ̀rọ̀ mi

Wọ́n sì kọ òfin* mi.”

20 “Kò já mọ́ nǹkan kan lójú mi pé ẹ̀ ń mú oje igi tùràrí wá láti Ṣébà

Àti pòròpórò olóòórùn dídùn* láti ilẹ̀ tó jìnnà.

Àwọn odindi ẹbọ sísun yín kò ní ìtẹ́wọ́gbà,

Àwọn ẹbọ yín kò sì mú inú mi dùn.”+

21 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Wò ó, màá fi àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ sí iwájú àwọn èèyàn yìí,

Wọ́n á sì mú wọn kọsẹ̀,

Àwọn bàbá àti àwọn ọmọ,

Aládùúgbò àti ọ̀rẹ́,

Gbogbo wọn yóò sì ṣègbé.”+

22 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Wò ó! Àwọn èèyàn kan ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,

Orílẹ̀-èdè ńlá kan yóò ta jí láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+

23 Wọ́n á di ọfà* àti ọ̀kọ̀* mú.

Ìkà ni wọ́n, wọn ò sì lójú àánú.

Ìró wọn dà bíi ti òkun,

Wọ́n sì gun ẹṣin.+

Wọ́n to ara wọn bí àwọn jagunjagun láti bá ọ jà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.”

24 A ti gbọ́ ìròyìn nípa rẹ̀.

Ọwọ́ wa rọ;+

Wàhálà ti bá wa,

Ìdààmú* sì bá wa bíi ti obìnrin tó ń rọbí.+

25 Má ṣe lọ sí oko,

Má sì rìn lójú ọ̀nà,

Nítorí ọ̀tá ní idà;

Ìpayà sì wà níbi gbogbo.

26 Ìwọ ọmọbìnrin àwọn èèyàn mi,

Wọ aṣọ ọ̀fọ̀,*+ kí o sì yí nínú eérú.

Ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ọmọkùnrin rẹ̀ kan ṣoṣo kú, kí o sì sunkún gidigidi,+

Torí lójijì ni apanirun máa dé bá wa.+

27 “Mo ti fi ọ́* ṣe ẹni tó ń yọ́ wúrà àti fàdákà mọ́,

Nítorí o ní láti yọ́ àwọn èèyàn mi mọ́;

Màá fiyè sí wọn, màá sì ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n ń ṣe.

28 Kò sí ẹni tó lágídí tó wọn láyé,+

Wọ́n ń rìn káàkiri bí abanijẹ́.+

Wọ́n dà bíi bàbà àti irin;

Ìwà ìbàjẹ́ kún ọwọ́ gbogbo wọn.

29 Ẹwìrì* wọn ti jóná.

Òjé ló ń jáde látinú iná wọn.

Ẹni tó ń yọ́ nǹkan mọ́ kàn ń ṣiṣẹ́ lásán ni,+

Àwọn tí kò dára kò sì yọ́ kúrò.+

30 Ó dájú pé fàdákà tí a kọ̀ ni àwọn èèyàn máa pè wọ́n,

Nítorí Jèhófà ti kọ̀ wọ́n.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́