Ẹ́sírà
7 Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, nígbà ìjọba Atasásítà+ ọba Páṣíà, Ẹ́sírà*+ pa dà. Ẹ́sírà jẹ́ ọmọ Seráyà,+ ọmọ Asaráyà, ọmọ Hilikáyà,+ 2 ọmọ Ṣálúmù, ọmọ Sádókù, ọmọ Áhítúbù, 3 ọmọ Amaráyà, ọmọ Asaráyà,+ ọmọ Méráótì, 4 ọmọ Seraháyà, ọmọ Úsáì, ọmọ Búkì, 5 ọmọ Ábíṣúà, ọmọ Fíníhásì,+ ọmọ Élíásárì,+ ọmọ Áárónì+ olórí àlùfáà. 6 Ẹ́sírà yìí dé láti Bábílónì. Ó jẹ́ adàwékọ* tó mọ Òfin Mósè+ dunjú,* èyí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Gbogbo ohun tó béèrè ni ọba fún un, nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà lára rẹ̀.
7 Àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì,+ àwọn akọrin,+ àwọn aṣọ́bodè+ àti àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ lọ sí Jerúsálẹ́mù ní ọdún keje Ọba Atasásítà. 8 Ẹ́sírà wá sí Jerúsálẹ́mù ní oṣù karùn-ún, ọdún keje ọba. 9 Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Bábílónì ní ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, ó sì dé Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ kìíní oṣù karùn-ún, nítorí ọwọ́ rere Ọlọ́run rẹ̀ wà lára rẹ̀.+ 10 Ẹ́sírà ti múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀* láti wádìí nínú Òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́+ àti láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ìlànà àti ìdájọ́ inú rẹ̀ ní Ísírẹ́lì.+
11 Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà tí Ọba Atasásítà fún Ẹ́sírà tó jẹ́ àlùfáà àti adàwékọ,* ọ̀jáfáfá nínú ẹ̀kọ́* àwọn àṣẹ Jèhófà àti àwọn ìlànà tó fún Ísírẹ́lì:
12 * “Atasásítà,+ ọba àwọn ọba, sí àlùfáà Ẹ́sírà, adàwékọ* Òfin Ọlọ́run ọ̀run: Kí àlàáfíà pípé máa jẹ́ tìrẹ. Ní báyìí, 13 mo ti pàṣẹ kan pé kí gbogbo ẹni tó wà lábẹ́ àkóso mi tó jẹ́ ara àwọn èèyàn Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà wọn àti àwọn ọmọ Léfì, tó bá fẹ́ bá ọ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí ó bá ọ lọ.+ 14 Nítorí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ méje ló rán ọ láti wádìí bóyá wọ́n ń pa Òfin Ọlọ́run rẹ, tó wà pẹ̀lú* rẹ mọ́ ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù, 15 kí o sì kó fàdákà àti wúrà tí ọba àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀ fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù 16 pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí o bá gbà* ní gbogbo ìpínlẹ̀* Bábílónì àti ẹ̀bùn tí àwọn èèyàn náà àti àwọn àlùfáà fi ṣe ọrẹ àtinúwá fún ilé Ọlọ́run wọn, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù.+ 17 Kí o tètè fi owó yìí ra àwọn akọ màlúù,+ àwọn àgbò+ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn+ pẹ̀lú àwọn ohun tí wọ́n nílò fún ọrẹ ọkà+ àti ọrẹ ohun mímu,+ kí o sì fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ ilé Ọlọ́run yín, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù.
18 “Ohun tó bá dára lójú rẹ àti lójú àwọn arákùnrin rẹ ni kí o fi ìyókù fàdákà àti wúrà náà ṣe, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run yín ṣe fẹ́. 19 Gbogbo ohun èlò tí wọ́n kó fún ọ fún iṣẹ́ ìsìn ilé Ọlọ́run rẹ ni kí o fi jíṣẹ́ níwájú Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù.+ 20 Gbogbo ohun yòókù tí o bá nílò fún ilé Ọlọ́run rẹ, kí o gbà á láti ibi ìṣúra ọba.+
21 “Èmi Ọba Atasásítà ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn tó ń tọ́jú ìṣúra ní agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò* pé ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà,+ adàwékọ* Òfin Ọlọ́run ọ̀run, bá béèrè lọ́wọ́ yín, kí ẹ fún un ní kánmọ́kánmọ́, 22 títí dórí ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ńtì* fàdákà, ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* àlìkámà* àti ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n báàtì* wáìnì+ àti ọgọ́rùn-ún (100) òṣùwọ̀n báàtì òróró+ àti ìwọ̀n iyọ̀+ tí kò níye. 23 Gbogbo ohun tí Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè ni kí a fi ìtara ṣe fún ilé Ọlọ́run ọ̀run,+ kí ìbínú Ọlọ́run má bàa wá sórí ilẹ̀ tí ọba ń ṣàkóso àti sórí àwọn ọmọ ọba.+ 24 Bákan náà, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ gba owó orí, ìṣákọ́lẹ̀*+ tàbí owó ibodè lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tó jẹ́ àlùfáà, ọmọ Léfì, olórin,+ aṣọ́nà, ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ tàbí òṣìṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run yìí.
25 “Ní tìrẹ, Ẹ́sírà, fi ọgbọ́n tí Ọlọ́run rẹ fún ọ* yan àwọn agbófinró àti àwọn onídàájọ́ tí wọ́n á máa ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn tó wà ní agbègbè Ìkọjá Odò, ìyẹn gbogbo àwọn tó mọ àwọn òfin Ọlọ́run rẹ; kí ẹ sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì mọ̀ wọ́n.+ 26 Gbogbo ẹni tí kò bá pa Òfin Ọlọ́run rẹ àti òfin ọba mọ́ ni kí wọ́n dá lẹ́jọ́ ní kánmọ́kánmọ́, ì báà jẹ́ ìdájọ́ ikú tàbí lílé kúrò láwùjọ tàbí owó ìtanràn tàbí ìfisẹ́wọ̀n.”
27 Ìyìn ni fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ẹni tó fi sí ọba lọ́kàn láti ṣe ilé Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ́ṣọ̀ọ́!+ 28 Ó ti fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí mi níwájú ọba+ àti àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ̀+ àti níwájú gbogbo àwọn ìjòyè ọba tí wọ́n jẹ́ alágbára. Torí náà, mo mọ́kàn le* nítorí ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run mi wà lára mi, mo sì kó àwọn aṣáájú ọkùnrin* jọ látinú Ísírẹ́lì kí wọ́n lè bá mi lọ.